ORIN 108
Ìfẹ́ Ọlọ́run Tí Kì Í Yẹ̀
- 1. Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́. - Ẹ̀rí fi hàn pó nífẹ̀ẹ́ wa. - Ó fi Ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo - Ṣe ìràpadà fáráyé - Ká lè níyè àìnípẹ̀kun, - Ká sì láyọ̀ títí ayé. - (ÈGBÈ) - Gbogbo ẹ̀yin tóùngbẹ ń gbẹ, - Ẹ wá mumi ‘yè lọ́fẹ̀ẹ́. - Kẹ́ ẹ mu ún, kọ́kàn yín balẹ̀; - Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ yín. 
- 2. Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́. - Gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ jẹ́rìí sí i. - Ó gbé Ọmọ rẹ̀ gorí ‘tẹ́. - Ó ti sọ ọ́ di ọba lọ́run. - Ìfẹ́ Ọlọ́run ti wá ṣẹ, - ’Jọba náà ti fìdí múlẹ̀! - (ÈGBÈ) - Gbogbo ẹ̀yin tóùngbẹ ń gbẹ, - Ẹ wá mumi ‘yè lọ́fẹ̀ẹ́. - Kẹ́ ẹ mu ún, kọ́kàn yín balẹ̀; - Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ yín. 
- 3. Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́. - Kẹ́mìí rẹ̀ mú ká fìfẹ́ hàn, - Ká sì kọ́ ọlọ́kàn tútù - Kí wọ́n lè pa òfin Jáà mọ́. - Ká máa fi ìgboyà wàásù, - Ká sì níbẹ̀rù Ọlọ́run. - (ÈGBÈ) - Gbogbo ẹ̀yin tóùngbẹ ń gbẹ, - Ẹ wá mumi ‘yè lọ́fẹ̀ẹ́. - Kẹ́ ẹ mu ún, kọ́kàn yín balẹ̀; - Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ yín.