ORIN 82
“Ẹ Jẹ́ Kí Ìmọ́lẹ̀ Yín Máa Tàn”
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Àṣẹ Jésù ni pé - Kí ‘mọ́lẹ̀ wa tàn. - Kí ìmọ́lẹ̀ wa hàn - Gbangba sáráyé. - Ìwé Mímọ́ ńkọ́ wa - Ní ìwà rere - Tá a gbọ́dọ̀ máa mú dàgbà - Nínú ayé wa. 
- 2. Bá a ṣe ń wàásù fáwọn - Èèyàn tá à ń pàdé, - Ẹ̀kọ́ ọ̀r’Ọlọ́run - Máa ràn wọ́n lọ́wọ́. - Kí wọ́n lè ṣàtúnṣe - Nínú ayé wọn; - Kí wọ́n lè yàn fúnra wọn - Láti wá sin Jáà. 
- 3. Ìwà rere tá à ń hù - Ń tàn bí ìmọ́lẹ̀. - Ọ̀rọ̀ ẹnu wa náà - Sì tún ń gbéni ró. - Bí a tiẹ̀ ń gbé nínú - Ayé Sátánì, - Ìmọ́lẹ̀ wa tó ń tàn yòò - Ń fògo f’Ọ́lọ́run. 
(Tún wo Sm. 119:130; Mát. 5:14, 15, 45; Kól. 4:6.)