-
Jèhófà Ni “Olùṣí Àwọn Àṣírí Payá”Ilé Ìṣọ́—2012 | June 15
-
-
Jèhófà Ni “Olùṣí Àwọn Àṣírí Payá”
“Lóòótọ́, Ọlọ́run yín jẹ́ Ọlọ́run àwọn ọlọ́run àti Olúwa àwọn ọba, ó sì jẹ́ Olùṣí àwọn àṣírí payá.”—DÁN. 2:47.
BÁWO LO ṢE MÁA DÁHÙN?
Kí ni Jèhófà ṣí payá fún wa nípa àwọn ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?
Kí ni àwọn mẹ́fà àkọ́kọ́ lára orí ẹranko ẹhànnà náà dúró fún?
Báwo ni ẹranko ẹhànnà náà àti ère tí Nebukadinésárì rí ṣe jọra?
1, 2. Kí ni Jèhófà ṣí payá fún wa, kí sì nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀?
ÀWỌN ìjọba wo ni yóò máa ṣàkóso ayé nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá máa fòpin sí ìṣàkóso èèyàn? A mọ ìdáhùn sí ìbéèrè yìí torí pé Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ “Olùṣí àwọn àṣírí payá” ti sọ ọ́ fún wa. Ó jẹ́ ká lè fi òye dá àwọn ìjọba wọ̀nyẹn mọ̀ nípasẹ̀ ohun tí wòlíì Dáníẹ́lì àti àpọ́sítélì Jòhánù ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀.
2 Jèhófà fi ọ̀wọ́ àwọn ẹranko kan han àwọn ọkùnrin yẹn nínú ìran. Ó tún sọ ìtúmọ̀ àlá kan tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ fún Dáníẹ́lì nípa ère arabarìbì kan tó jẹ́ ti wúrà, fàdákà, bàbà, irin àti amọ̀. Jèhófà mú kí wọ́n kọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sílẹ̀, kí wọ́n sì pá a mọ́ nínú Bíbélì fún àǹfààní wa. (Róòmù 15:4) Ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó fẹ́ kí ìrètí tá a ní túbọ̀ dá wa lójú pé, Ìjọba òun máa fọ́ gbogbo ìjọba èèyàn túútúú láìpẹ́.—Dán. 2:44.
3. Kó tó lè ṣeé ṣe fún wa láti lóye àsọtẹ́lẹ̀ dáadáa, kí ló yẹ ká kọ́kọ́ mọ̀, kí sì nìdí?
3 Lápapọ̀, àkọsílẹ̀ Dáníẹ́lì àti Jòhánù jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan kan nípa ọba mẹ́jọ, tàbí ìṣàkóso àwọn èèyàn, ó sì tún jẹ́ ká mọ bí àwọn ọba náà ṣe máa fara hàn lọ́kọ̀ọ̀kan. Àmọ́ ṣá o, ká tó lè lóye àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyẹn dáadáa, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mọ ìtumọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ pàá tó wà nínú Bíbélì. Kí nìdí? Ìdí ni pé ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ni ẹṣin ọ̀rọ̀ tó so Bíbélì pọ̀ lódindi. Lọ́nà kan, ńṣe ló dà bí okùn kan tí gbogbo àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yòókù nínú Bíbélì rọ̀ mọ́.
IRÚ ỌMỌ EJÒ NÁÀ ÀTI ẸRANKO ẸHÀNNÀ
4. Àwọn wo ló para pọ̀ di irú ọmọ obìnrin náà, kí sì ni irú ọmọ yìí máa ṣe?
4 Láìpẹ́ lẹ́yìn ìṣọ̀tẹ̀ tó wáyé ní ọgbà Édẹ́nì, Jèhófà ṣèlérí pé “obìnrin” kan máa bí “irú ọmọ” kan.a (Ka Jẹ́nẹ́sísì 3:15.) Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, irú ọmọ yìí máa pa ejò náà, Sátánì, ní orí. Nígbà tó yá, Jèhófà ṣí i payá pé irú ọmọ náà máa wá láti ìlà ìdílé Ábúráhámù, láti orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, pé ó máa jẹ́ ẹ̀yà Júdà àti pé ó máa jẹ́ àtọmọdọ́mọ Dáfídì Ọba. (Jẹ́n. 22:15-18; 49:10; Sm. 89:3, 4; Lúùkù 1:30-33) Kristi Jésù ni apá àkọ́kọ́ lára irú ọmọ náà. (Gál. 3:16) Àwọn ẹni àmì òróró tó wà nínú ìjọ Kristẹni ni apá kejì lára irú ọmọ náà. (Gál. 3:26-29) Jésù àti àwọn ẹni àmì òróró yìí ló para pọ̀ di Ìjọba Ọlọ́run, Ìjọba yìí sì ni Ọlọ́run máa lò láti fọ́ Sátánì túútúú.—Lúùkù 12:32; Róòmù 16:20.
5, 6. (a) Agbára ńlá mélòó ni Dáníẹ́lì àti Jòhánù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? (b) Kí ni àwọn orí ẹranko ẹhànnà tí ìwé Ìṣípayá sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ dúró fún?
5 Àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run sọ nínú ọgbà Édẹ́nì yẹn tún fi hàn pé Sátánì náà máa ní “irú ọmọ” tirẹ̀. Irú ọmọ Sátánì yìí máa bá irú ọmọ obìnrin náà ṣọ̀tá. Àwọn wo ló para pọ̀ di irú ọmọ ejò náà? Gbogbo àwọn tó kórìíra Ọlọ́run tí wọ́n sì ń ta ko àwọn èèyàn rẹ̀ bíi ti Sátánì ni. Ọjọ́ pẹ́ tí Sátánì ti ń ṣètò irú ọmọ rẹ̀ sí onírúurú ẹgbẹ́ òṣèlú, tàbí àwọn ìjọba. (Lúùkù 4:5, 6) Àmọ́, díẹ̀ lára àwọn ìjọba èèyàn ló tíì ní ipa tó lágbára gan-an lórí àwọn èèyàn Ọlọ́run, ì báà jẹ́ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ tàbí ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró. Kí nìdí tí kókó yìí fi ṣe pàtàkì? Ìdí ni pé ó jẹ́ ká mọ ìdí tó fi jẹ́ pé mẹ́jọ péré lára irú àwọn ìjọba alágbára bẹ́ẹ̀ ni Dáníẹ́lì àti Jòhánù rí nínú ìran.
6 Nígbà tí ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni (S.K.) ń parí lọ, Jésù tó ti jíǹde fi ọ̀wọ́ àwọn ìran kíkàmàmà kan han àpọ́sítélì Jòhánù. (Ìṣí. 1:1) Nínú ọ̀kan lára àwọn ìran náà, Jòhánù rí Èṣù, tí wọ́n fi dírágónì ṣàpẹẹrẹ, tó dúró ní etíkun tó fẹ̀ lọ salalu. (Ka Ìṣípayá 13:1, 2.) Jòhánù tún rí ẹranko abàmì kan tó jáde wá láti inú òkun náà, tó sì gba agbára ńlá látọ̀dọ̀ Èṣù. Lẹ́yìn náà ni áńgẹ́lì kan wá fi han Jòhánù pé orí méje tí ẹranko aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà ní, èyí tó jẹ́ ère ẹranko tí Ìṣípayá 13:1 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, dúró fún “ọba méje” tàbí àwọn ìjọba. (Ìṣí. 13:14, 15; 17:3, 9, 10) Ní àkókò tí Jòhánù ń kọ ìwé rẹ̀, márùn-ún lára àwọn ọba náà ti ṣubú, ọ̀kan ń ṣàkóso lọ́wọ́ nígbà yẹn, ọ̀kan tó kù “kò tíì dé.” Báwo la ṣe lè dá àwọn ìjọba, tàbí àwọn agbára ayé náà mọ̀? Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn orí ẹranko tí ìwé Ìṣípayá sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. A tún máa rí bí ìwé Dáníẹ́lì ṣe fi kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa ọ̀pọ̀ lára àwọn ìjọba yìí kún un, bẹ́ẹ̀ ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún kí wọ́n tó fara hàn ni Dáníẹ́lì ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa wọn.
ORÍ MÉJÌ ÀKỌ́KỌ́ DÚRÓ FÚN ÍJÍBÍTÌ ÀTI ÁSÍRÍÀ
7. Kí ni àkọ́kọ́ lára orí ẹranko náà dúró fún, kí sì nìdí?
7 Àkọ́kọ́ lára orí ẹranko náà dúró fún orílẹ̀-èdè Íjíbítì. Kí nìdí? Ìdí ni pé Íjíbítì ni agbára ayé tó kọ́kọ́ mú àwọn èèyàn Ọlọ́run ní ọ̀tá. Àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù, ẹni tí Ọlọ́run ṣèlérí pé ipasẹ̀ rẹ̀ ni irú ọmọ obìnrin náà máa gbà wá, di púpọ̀ rẹpẹtẹ ní ilẹ̀ Íjíbítì. Lẹ́yìn náà, àwọn ará Íjíbítì wá ń pọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lójú. Sátánì gbìyànjú láti pa àwọn èèyàn Ọlọ́run rẹ́ kí irú ọmọ náà tó dé. Lọ́nà wo? Ó mú kí Fáráò pa gbogbo ọmọ ọkùnrin tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bí. Jèhófà mú kí ìsapá yìí forí ṣánpọ́n, ó sì dá àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀ lóko ẹrú àwọn ará Íjíbítì. (Ẹ́kís. 1:15-20; 14:13) Ẹ̀yìn náà ló wá fìdí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kalẹ̀ sí Ilẹ̀ Ìlérí.
8. Kí ni èkejì lára orí ẹranko náà dúró fún, kí ló sì gbìyànjú láti ṣe?
8 Èkejì lára orí ẹranko náà dúró fún orílẹ̀-èdè Ásíríà. Ìjọba alágbára yìí náà gbìyànjú láti pa àwọn èèyàn Ọlọ́run rẹ́. Òótọ́ ni pé Jèhófà lo orílẹ̀-èdè Ásíríà láti fìyà jẹ ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì nítorí wọ́n di abọ̀rìṣà àti ọlọ̀tẹ̀. Àmọ́, orílẹ̀-èdè Ásíríà tún wá gbéjà ko Jerúsálẹ́mù. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni Sátánì ń wá bó ṣe máa pa ìlà ìdílé ọba tí Jésù máa gbà wá run. Ìgbéjàkò yìí kò sí lára ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn láti ṣe, ó sì dá àwọn èèyàn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sílẹ̀ lọ́nà ìyanu nípa pípa àwọn ọ̀tá náà run.—2 Ọba 19:32-35; Aísá. 10:5, 6, 12-15.
ORÍ KẸTA DÚRÓ FÚN BÁBÍLÓNÌ
9, 10. (a) Kí ni Jèhófà gba àwọn ará Bábílónì láyè láti ṣe? (b) Kí àsọtẹ́lẹ̀ tó lè ní ìmúṣẹ, kí ló ní láti ṣẹlẹ̀?
9 Ẹ̀kẹta lára orí ẹranko tí Jòhánù rí dúró fún ìjọba tí Bábílónì jẹ́ olú ìlú rẹ̀. Jèhófà fàyè gba àwọn ará Bábílónì láti pa Jerúsálẹ́mù run, kí wọ́n sì kó àwọn èèyàn rẹ̀ nígbèkùn. Àmọ́ kí Jèhófà tó jẹ́ kí àwọn èèyàn rẹ̀ kan àbùkù lọ́nà yìí, ó ti kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ti ya ọlọ̀tẹ̀ yẹn pé irú àgbákò yẹn máa dé bá wọn. (2 Ọba 20:16-18) Ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé a máa mú ìlà àwọn ọba tí wọ́n ń jókòó sórí “ìtẹ́ Jèhófà” ní Jerúsálẹ́mù kúrò. (1 Kíró. 29:23) Àmọ́, Jèhófà tún ṣèlérí pé ọ̀kan lára àwọn àtọmọdọ́mọ Dáfídì Ọba, ẹni tó ní “ẹ̀tọ́ lọ́nà òfin,” máa wá láti gba agbára ìjọba.—Ìsík. 21:25-27.
10 Àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn fi hàn pé àwọn Júù á ṣì máa jọ́sìn nínú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù nígbà tí Mèsáyà, tàbí Ẹni Àmì Òróró, tá a ṣèlérí náà bá dé. (Dán. 9:24-27) Àsọtẹ́lẹ̀ kan tí wọ́n ti sọ ṣáájú èyí, ìyẹn kí wọ́n tó kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbèkùn lọ sí ìlú Bábílónì, sọ pé ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ni wọ́n ti máa bí ẹni yìí. (Míkà 5:2) Bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn bá máa ní ìmúṣẹ, a jẹ́ pé a máa ní láti dá àwọn Júù sílẹ̀ nígbèkùn, wọ́n á pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn, wọ́n á sì tún tẹ́ńpìlì kọ́. Àmọ́, kì í ṣe àṣà àwọn ará Bábílónì láti dá àwọn tí wọ́n bá kó nígbèkùn sílẹ̀. Báwo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì á ṣe borí ìdènà yẹn? Jèhófà ṣí ìdáhùn ìbéèrè yìí payá fún àwọn wòlíì rẹ̀.—Ámósì 3:7.
11. Àwọn ọ̀nà tó yàtọ̀ wo la gbà ṣàpẹẹrẹ Ilẹ̀ Ọba Bábílónì? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
11 Wòlíì Dáníẹ́lì wà lára àwọn tí wọ́n kó nígbèkùn lọ sí ìlú Bábílónì. (Dán. 1:1-6) Jèhófà lo Dáníẹ́lì láti ṣí àwọn ìjọba tó máa jẹ tẹ̀ lé agbára ayé Bábílónì payá. Jèhófà ṣí àwọn àṣírí yìí payá nípa lílo onírúurú nǹkan láti ṣàpẹẹrẹ àwọn ìjọba náà. Bí àpẹẹrẹ, ó mú kí Nebukadinésárì Ọba Bábílónì lá àlá nípa ère arabarìbì kan tó jẹ́ ti wúrà, fàdákà, bàbà, irin àti amọ̀. (Ka Dáníẹ́lì 2:1, 19, 31-38.) Jèhófà tipasẹ̀ wòlíì Dáníẹ́lì ṣí i payá pé orí ère náà tó jẹ́ wúrà dúró fún Ilẹ̀ Ọba Bábílónì.b Igẹ̀ àti apá ère náà tó jẹ́ fàdákà ṣàpẹẹrẹ agbára ayé tó máa tẹ̀ lé Bábílónì. Agbára ayé wo ni ìyẹn máa jẹ́, kí ló sì máa ṣe sáwọn èèyàn Ọlọ́run?
ORÍ KẸRIN DÚRÓ FÚN MÍDÍÀ ÒUN PÁṢÍÀ
12, 13. (a) Kí ni Jèhófà jẹ́ ká mọ̀ nípa bí wọ́n ṣe máa ṣẹ́gun Bábílónì? (b) Kì nìdí tó fi bá a mu wẹ́kú bí Ìwé Mímọ́ ṣe fi ìkẹrin lára orí ẹranko ẹhànnà náà ṣàpẹẹrẹ Mídíà òun Páṣíà?
12 Ní ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún ṣáájú ìgbà ayé Dáníẹ́lì, Jèhófà tipasẹ̀ wòlíì Aísáyà ṣí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan payá nípa agbára ayé tó máa ṣẹ́gun Bábílónì. Kì í ṣe ọ̀nà tí wọ́n máa gbà ṣẹ́gun ìlú Bábílónì nìkan ni Jèhófà sọ di mímọ̀, ó tún sọ orúkọ ẹni tó máa ṣẹ́gun ìlú náà. Ẹni tó máa ṣáájú ogun náà ni Kírúsì ará Páṣíà. (Aísá. 44:28–45:2) Dáníẹ́lì rí ìran méjì míì nípa Agbára Ayé Mídíà òun Páṣíà. Nínú ọ̀kan lára àwọn ìran náà, a fi ìjọba yìí wé béárì tá a gbé sókè ní ìhà kan. Wọ́n sì sọ fún un pé kí ó “jẹ ẹran púpọ̀.” (Dán. 7:5) Nínú ìran míì tó yàtọ̀ sí èyí, Dáníẹ́lì rí àgbò kan tó ní ìwo méjì èyí tó ṣàpẹẹrẹ orílẹ̀-èdè méjì tó para pọ̀ di agbára ayé yìí.—Dán. 8:3, 20.
13 Jèhófà lo Ilẹ̀ Ọba Mídíà òun Páṣíà láti mú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ṣẹ nígbà tó gba ìjọba lọ́wọ́ Bábílónì tó sì dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn. (2 Kíró. 36:22, 23) Àmọ́, agbára ayé kan náà yìí tún fẹ́rẹ̀ẹ́ pa àwọn èèyàn Ọlọ́run rẹ́. Ìwé Ẹ́sítérì nínú Bíbélì sọ nípa ìdìtẹ̀ kan tó wáyé. Ọkùnrin kan báyìí tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Hámánì tó jẹ́ igbá kejì ọba Páṣíà ló sì dìtẹ̀ náà. Ó ṣètò pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn Júù tó ń gbé ní Ilẹ̀ Ọba Páṣíà gbígbòòrò run, ó sì dá ọjọ́ kan pàtó tí ìpẹ̀yàrun náà máa wáyé. Ọpẹ́lọpẹ́ bí Jèhófà ṣe dá sí ọ̀rọ̀ náà ló yọ àwọn èèyàn rẹ̀, tó sì tún gbà wọ́n lọ́wọ́ irú ọmọ Sátánì tó ń ṣe kèéta sí wọn. (Ẹ́sít. 1:1-3; 3:8, 9; 8:3, 9-14) Ó bá a mu wẹ́kú bí Ìwé Mímọ́ ṣe fi ìkẹrin lára orí ẹranko inú ìwé Ìṣípayá ṣàpẹẹrẹ Mídíà òun Páṣíà.
ORÍ KARÙN-ÚN DÚRÓ FÚN GÍRÍÌSÌ
14, 15. Àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ wo ni Jèhófà ṣí payá nípa Ilẹ̀ Ọba Gíríìsì ìgbàanì?
14 Ìkarùn-ún lára orí ẹranko ẹhànnà inú ìwé Ìṣípayá dúró fún ilẹ̀ Gíríìsì. Bí Dáníẹ́lì ṣe fi hàn nígbà tó ń sọ ìtumọ̀ àlá tí Nebukadinésárì lá, agbára ayé Gíríìsì yìí kan náà ni ikùn àti itan ère náà tó jẹ́ bàbà ṣàpẹẹrẹ. Dáníẹ́lì tún rí ìran méjì tó sọ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tó gbàfiyèsí nípa bí ilẹ̀ ọba náà ṣe máa rí àti nípa alákòóso rẹ̀ tó lókìkí jù lọ.
15 Nínú ìran kan, Dáníẹ́lì rí ilẹ̀ Gíríìsì tá a fi àmọ̀tẹ́kùn tó ní ìyẹ́ apá mẹ́rin ṣàpẹẹrẹ, èyí tó fi hàn pé ó máa ṣẹ́gun lọ́nà yíyára kánkán. (Dán. 7:6) Nínú ìran míì, Dáníẹ́lì ṣàpèjúwe bí òbúkọ kan tó ní ìwo ńlá kan ṣe yára kan àgbò kan tó ní ìwo méjì pa, ìyẹn Mídíà òun Páṣíà. Jèhófà sọ fún Dáníẹ́lì pé òbúkọ náà ṣàpẹẹrẹ ilẹ̀ Gíríìsì, ìwo ńlá tó wà lórí rẹ̀ sì dúró fún ọ̀kan lára àwọn ọba rẹ̀. Dáníẹ́lì sọ síwájú sí i pé ìwo ńlá tí òbúkọ náà ní máa ṣẹ́ àti pé ìwo kéékèèké mẹ́rin máa yọ dípò rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún kí ilẹ̀ Gíríìsì tó di agbára ayé ni wọ́n ti kọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí sílẹ̀, gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ náà ló ní ìmúṣẹ láìkù síbì kan. Alẹkisáńdà Ńlá, tó jẹ́ ọba tó lókìkí jù lọ nínú àwọn ọba tó jẹ ní ilẹ̀ Gíríìsì ìgbàanì, ló ṣáájú ogun tí wọ́n bá Mídíà òun Páṣíà jà. Àmọ́ kò pẹ́ tí ìwo yìí fi ṣẹ́, ọba alágbára yìí kú nígbà tí agbára rẹ̀ dé òtéńté, lẹ́ni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n [32] péré. Lẹ́yìn náà, àwọn ọ̀gágun rẹ̀ mẹ́rin pín ìjọba rẹ̀ láàárín ara wọn.—Ka Dáníẹ́lì 8:20-22.
16. Kí ni Áńtíókọ́sì Kẹrin ṣe?
16 Lẹ́yìn tí ilẹ̀ Gíríìsì ti ṣẹ́gun Páṣíà, ó ṣàkóso lórí ilẹ̀ àwọn èèyàn Ọlọ́run. Ní àkókò yìí àwọn Júù ti pa dà sí Ilẹ̀ Ìlérí, wọ́n sì ti tún tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù kọ́. Àyànfẹ́ Ọlọ́run ni wọ́n ṣì jẹ́, tẹ́ńpìlì tí wọ́n tún kọ́ náà sì ni ojúkò ìjọsìn tòótọ́. Àmọ́ ní ọ̀rúndún kejì ṣáájú Sànmánì Kristẹni (Ṣ.S.K.), ilẹ̀ Gíríìsì tó jẹ́ ìkarùn-ún lára orí ẹranko ẹhànnà náà, gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run. Áńtíókọ́sì Kẹrin tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó gba ilẹ̀ ọba Alẹkisáńdà tí wọ́n pín, gbé ojúbọ òrìṣà sórí ilẹ̀ tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù, ó sì ṣòfin pé pípa ni wọ́n máa pa ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá rí tó ń ṣe ẹ̀sìn àwọn Júù. Ẹ ò rí i pé ìkórìíra ńlá gbáà lèyí jẹ́ látọ̀dọ̀ irú ọmọ Sátánì! Àmọ́ kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí wọ́n fi gba agbára ayé lọ́wọ́ ilẹ̀ Gíríìsì. Kí ni ìkẹfà lára orí ẹranko ẹhànnà yìí dúró fún?
RÓÒMÙ TÍ ORÍ KẸFÀ DÚRÓ FÚN, ‘Ń BANI LẸ́RÙ, Ó SÌ Ń JÁNI LÁYÀ’
17. Ipa pàtàkì wo ni ìkẹfà lára orí ẹranko náà kó nínú ìmúṣẹ Jẹ́nẹ́sísì 3:15?
17 Róòmù ló ń ṣàkóso lọ́wọ́ nígbà tí Jòhánù rí ìran ẹranko ẹhànnà náà. (Ìṣí. 17:10) Róòmù tó jẹ́ ìkẹfà lára orí ẹranko yìí kó ipa pàtàkì nínú ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:15. Sátánì lo àwọn aláṣẹ ìlú Róòmù láti ṣe irú ọmọ obìnrin náà lọ́ṣẹ́ fúngbà díẹ̀, èyí tó já sí pé ó pa á “ní gìgísẹ̀.” Lọ́nà wo? Wọ́n gbẹ́jọ́ Jésù lórí àwọn ẹ̀sùn èké tí wọ́n fi kàn án pé ó dìtẹ̀ sí ìjọba, wọ́n sì dájọ́ ikú fún un. (Mát. 27:26) Àmọ́ kò pẹ́ tí ọgbẹ́ náà fi jinná torí pé Jèhófà jí Jésù dìde.
18. (a) Orílẹ̀-èdè tuntun wo ni Jèhófà yàn, kí sì nìdí? (b) Ọ̀nà wo ni irú ọmọ ejò náà ń gbà bá a nìṣó láti máa ṣe kèéta sí irú ọmọ obìnrin náà?
18 Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará Róòmù lòdì sí Jésù, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè náà ló sì kọ Jésù sílẹ̀. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi pa Ísírẹ́lì nípa tara tí wọ́n jẹ́ èèyàn rẹ̀ tì. (Mát. 23:38; Ìṣe 2:22, 23) Ó wá yan orílẹ̀-èdè tuntun ìyẹn ni “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.” (Gál. 3:26-29; 6:16) Ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ni orílẹ̀-èdè náà, àwọn Júù àti àwọn Kèfèrí ló sì wà nínú rẹ̀. (Éfé. 2:11-18) Lẹ́yìn tí Jésù ti kú tó sì ti jíǹde, irú ọmọ ejò náà ń bá a nìṣó láti máa ṣe kèéta sí irú ọmọ obìnrin náà. Ó ju ìgbà kan lọ tí Róòmù gbìyànjú láti pa ìjọ Kristẹni tó jẹ́ apá kejì lára irú ọmọ náà rẹ́.c
19. (a) Báwo ni Dáníẹ́lì ṣe ṣàpèjúwe agbára ayé kẹfà? (b) Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 14?
19 Nínú àlá tí Dáníẹ́lì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún Nebukadinésárì, ẹsẹ̀ ère náà tó jẹ́ irin ló ṣàpẹẹrẹ Róòmù. (Dán. 2:33) Dáníẹ́lì tún rí ìran míì tó ṣàpèjúwe Ilẹ̀ Ọba Róòmù lọ́nà tó ṣe wẹ́kú àti agbára ayé míì tó jáde wá látinú Róòmù. (Ka Dáníẹ́lì 7:7, 8.) Fún ọ̀pọ̀ ọdún, àwọn tó ń bá ìlú Róòmù ṣọ̀tá rí i bí ẹni “tí ń bani lẹ́rù, tí ń jáni láyà, tí ó sì lágbára lọ́nà kíkàmàmà.” Àmọ́, àsọtẹ́lẹ̀ náà fi hàn pé “ìwo mẹ́wàá” máa tinú ilẹ̀ ọba yìí jáde wá, ọ̀kan lára wọn sì máa di olókìkí. Kí ni àwọn ìwo mẹ́wàá yìí dúró fún, kí la sì máa fi dá ìwo kékeré náà mọ̀? Ọ̀nà wo ni ìwo kékeré náà gbà bá àpèjúwe ère arabarìbì tí Nebukadinésárì rí mu? A máa rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó wà ní ojú ìwé 14.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Obìnrin yìí dúró fún ètò Jèhófà tó dà bí ìyàwó, àwọn áńgẹ́lì tó wà lókè ọ̀run ló sì para pọ̀ di ètò Ọlọ́run yìí.—Aísá. 54:1; Gál. 4:26; Ìṣí. 12:1, 2.
b Orí ère tó wà nínú ìwé Dáníẹ́lì àti ẹ̀kẹta lára orí ẹranko ẹhànnà tí ìwé Ìṣípayá ṣàpèjúwe rẹ̀ ṣàpẹẹrẹ Bábílónì. Wo àtẹ ìsọfúnni tó wà lójú ìwé 12 sí 13.
c Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Róòmù pa ìlú Jerúsálẹ́mù run lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni, ìgbéjàkò yìí kò sí lára ìmúṣẹ Jẹ́nẹ́sísì 3:15. Ní àkókò yẹn, Ísírẹ́lì nípa tara kì í ṣe orílẹ̀-èdè àyànfẹ́ Ọlọ́run mọ́.
-
-
Jèhófà Ṣí Àwọn Ohun Tí Ó “Gbọ́dọ̀ Ṣẹlẹ̀ Láìpẹ́” PayáIlé Ìṣọ́—2012 | June 15
-
-
Jèhófà Ṣí Àwọn Ohun Tí Ó “Gbọ́dọ̀ Ṣẹlẹ̀ Láìpẹ́” Payá
“Ìṣípayá láti ọ̀dọ̀ Jésù Kristi, èyí tí Ọlọ́run fi fún un, láti fi han àwọn ẹrú rẹ̀, àwọn ohun tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ láìpẹ́.”—ÌṢÍ. 1:1.
BÁWO LO ṢE MÁA DÁHÙN?
Àwọn apá wo lára ère arabarìbì náà ló ṣàpẹẹrẹ Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà?
Báwo ni Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe àjọṣe tó wà láàárín Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà àti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè?
Báwo ni Dáníẹ́lì àti Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe bí ìṣàkóso àwọn èèyàn ṣe máa dópin?
1, 2. (a) Kí ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì àti Jòhánù máa jẹ́ ká mọ̀? (b) Kí ni orí mẹ́fà àkọ́kọ́ lára ẹranko ẹhànnà náà dúró fún?
TÁ A bá fi àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì àti ti Jòhánù wéra, ó máa jẹ́ ká mọ ìtumọ̀ ọ̀pọ̀ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé báyìí àtàwọn ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Kí la lè rí kọ́ nínú ìràn tí Jòhánù rí nípa ẹranko ẹhànnà náà, ohun tí Dáníẹ́lì sọ nípa ẹranko bíbanilẹ́rù kan tó ní ìwo mẹ́wàá àti àlàyé tí Dáníẹ́lì ṣe nípa ère arabarìbì náà tá a bá fi wọ́n wéra? Tá a bá sì ní òye tó ṣe kedere nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí, kí ni wọ́n máa sún wa láti ṣe?
2 Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ìran tí Jòhánù rí nípa ẹranko ẹhànnà náà. (Ìṣí., orí 13) Bá a ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 7, orí mẹ́fà àkọ́kọ́ lára ẹranko náà dúró fún Íjíbítì, Ásíríà, Bábílónì, Mídíà òun Páṣíà, Gíríìsì àti Róòmù. Gbogbo wọn pátá ló fi hàn pé àwọn kórìíra irú ọmọ obìnrin náà. (Jẹ́n. 3:15) Róòmù, tó dúró fún ìkẹfà lára àwọn orí náà, ló ṣàkóso fún ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn tí Jòhánù kọ ìran tó rí sílẹ̀. Àmọ́, ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ ìkeje lára àwọn orí náà máa gba ipò Róòmù. Agbára ayé wo ni èyí máa jẹ́, kí ló sì máa ṣe sí irú ọmọ obìnrin náà?
ILẸ̀ GẸ̀Ẹ́SÌ ÀTI ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ DI ALÁGBÁRA
3. Kí ni ẹranko oníwo mẹ́wàá tí ń bani lẹ́rù náà dúró fún, kí sì ni àwọn ìwo mẹ́wàá náà ṣàpẹẹrẹ?
3 A lè dá ìkeje lára orí ẹranko ẹhànnà tí ìwé Ìṣípayá orí 13 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ mọ̀ tá a bá fi ìran tí Jòhánù rí wéra pẹ̀lú ìran tí Dáníẹ́lì rí nípa ẹranko oníwo mẹ́wàá tí ń bani lẹ́rù.a (Ka Dáníẹ́lì 7:7, 8, 23, 24.) Ẹranko tí Dáníẹ́lì rí dúró fún Agbára Ayé Róòmù. (Wo àtẹ ìsọfúnni tó wà lójú ìwé 12 sí 13.) Nígbà tó di ọ̀rúndún karùn-ún Sànmánì Kristẹni, Ilẹ̀ Ọba Róòmù bẹ̀rẹ̀ sí í pín sọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Ìwo mẹ́wàá tó hù jáde ní orí ẹranko tí ń bani lẹ́rù yẹn dúró fún àwọn ìjọba tó jáde wá látinú Ilẹ̀ Ọba Róòmù.
4, 5. (a) Kí ni ìwo kékeré náà ṣe? (b) Kí ni ìkeje lára orí ẹranko ẹhànnà náà dúró fún?
4 Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa mẹ́rin lára àwọn ìwo, tàbí àwọn ìjọba tó hù jáde láti orí ẹranko rírorò náà lọ́nà àkànṣe. Ìwo mìíràn “ọ̀kan tí ó kéré,” fa mẹ́ta lára àwọn ìwo náà tu. Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ní ìmúṣẹ nígbà tí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ilẹ̀ tí Róòmù ń gbókèèrè ṣàkóso, di alágbára. Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kò lágbára kankan títí di ọ̀rúndún kẹtàdínlógún [17] Sànmánì Kristẹni. Àwọn ẹkùn ilẹ̀ mẹ́ta mìíràn tó jẹ́ abẹnugan lábẹ́ Ilẹ̀ Ọba Róòmù ìgbàanì ni, Sípéènì, Netherlands àti Faransé. Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì mú àwọn alágbára yìí kúrò lọ́kọ̀ọ̀kan, ní ti pé ó gbé wọn kúrò ní àwọn ipò ọlá tí wọ́n wà. Nígbà tó fi máa di ìdajì ọ̀rúndún kejìdínlógún [18], ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di ìjọba tó lágbára jù lọ lágbàáyé. Àmọ́, kò tíì di ìkeje lára orí ẹranko ẹhànnà náà.
5 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì di alágbára, àwọn ilẹ̀ tó ń ṣàkóso lé lórí ní Amẹ́ríkà ti Àríwá yapa kúrò lára rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì gba orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láyè láti di alágbára, síbẹ̀ àwọn ọmọ ogun ojú omi ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ló ṣì ń dáàbò bò ó. Nígbà tí ọjọ́ Olúwa fi máa bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti di ilẹ̀ ọba tó gbòòrò jù lọ nínú ìtàn, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sì ti di orílẹ̀-èdè tó láwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá tó pọ̀ jù lọ lágbàáyé.b Nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà wọnú àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Bí ìkeje lára orí ẹranko náà ṣe fara hàn nìyẹn gẹ́gẹ́ bí Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà. Kí ni orí yìí ṣe sí irú ọmọ obìnrin náà?
6. Kí ni ìkeje lára orí ẹranko náà ṣe sí àwọn èèyàn Ọlọ́run?
6 Gẹ́rẹ́ lẹ́yìn tí ọjọ́ Olúwa bẹ̀rẹ̀, ìkeje lára orí ẹranko náà gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run, ìyẹn àwọn tó ṣẹ́ kù lórí ilẹ̀ ayé lára àwọn arákùnrin Kristi. (Mát. 25:40) Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé nígbà wíwàníhìn-ín òun, àwọn àṣẹ́kù lára irú ọmọ náà á máa bá iṣẹ́ lọ lórí ilẹ̀ ayé. (Mát. 24:45-47; Gál. 3:26-29) Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà bá àwọn ẹni mímọ́ yìí jagun. (Ìṣí. 13:3, 7) Nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, ó ṣenúnibíni sí àwọn èèyàn Ọlọ́run, ó fòfin de díẹ̀ lára àwọn ìtẹ̀jáde wọn, ó sì ju àwọn aṣojú ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ sẹ́wọ̀n. Ó wá dà bíi pé ìkeje lára orí ẹranko ẹhànnà náà ti dá iṣẹ́ ìwàásù náà dúró fún àkókò kan. Jèhófà rí ìṣẹ̀lẹ̀ pípabanbarì yìí tẹ́lẹ̀, ó sì fi han Jòhánù. Ọlọ́run tún sọ fún Jòhánù pé a máa mú apá kejì lára irú ọmọ yìí sọjí kí wọ́n lè tún bẹ̀rẹ̀ ìgbòkègbodò tẹ̀mí lẹ́ẹ̀kan sí i. (Ìṣí. 11:3, 7-11) Ìtàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní fi hàn pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn wáyé lóòótọ́.
AGBÁRA AYÉ GẸ̀Ẹ́SÌ ÒUN AMẸ́RÍKÀ ÀTI ẸSẸ̀ TÓ JẸ́ ÀDÀPỌ̀ IRIN ÀTI AMỌ̀
7. Ọ̀nà wo ni ìkeje lára orí ẹranko ẹhànnà náà àti ère arabarìbì náà gbà jọra?
7 Ọ̀nà wo ni ìkeje lára orí ẹranko ẹhànnà náà àti ère arabarìbì náà gbà jọra? Inú Ilẹ̀ Ọba Róòmù ni ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti jáde wa, níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé ara ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti jáde wá, a lè sọ pé, ará Ilẹ̀ Ọba Róòmù ni Amẹ́ríkà náà ti jáde wá. Ẹsẹ̀ ère náà wá ńkọ́? A ṣàpèjúwe rẹ̀ pé ó jẹ́ àdàpọ̀ irin àti amọ̀. (Ka Dáníẹ́lì 2:41-43.) Àpèjúwe yìí bọ́ sí àkókò kan náà pẹ̀lú àkókò tí ìkeje lára orí ẹranko náà, ìyẹn Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà, máa di alágbára. Bí irin tí wọ́n dà pọ̀ mọ́ amọ̀ kò ṣe lè lágbára bí ojúlówó irin, bẹ́ẹ̀ náà ni Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà kò ṣe lágbára tó agbára ayé Róòmù tó ti jáde wá. Kí ló fà á?
8, 9. (a) Báwo ni agbára ayé keje ṣe lo agbára tó le bí irin? (b) Kí ni amọ̀ tó wà ní ẹsẹ̀ ère náà dúró fún?
8 Nígbà míì, ìkeje lára orí ẹranko náà máa ń fi hàn pé òun ní agbára tó le bí irin. Bí àpẹẹrẹ, ó fi hàn pé òun jẹ́ alágbára nígbà tó borí nínú Ogun Àgbáyé Kìíní. Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, ó tún hàn gbangba pé ìkeje lára orí ẹranko náà ní agbára tó le bí irin.c Lẹ́yìn ogun yẹn, àwọn ìgbà míì wà tí ìkeje lára orí ẹranko náà ti lo agbára rẹ̀ tó le bí irin. Àmọ́, àtìgbà tó ti di agbára ayé ni irin náà ti dà pọ̀ mọ́ amọ̀.
9 Ọjọ́ pẹ́ tí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ti ń wá ọ̀nà láti lóye ohun tí ẹsẹ̀ ère náà dúró fún. Ìwé Dáníẹ́lì 2:41 ṣàpèjúwe ẹsẹ̀ tó jẹ́ àdàpọ̀ irin àti amọ̀ náà pé ó jẹ́ “ìjọba” kan ṣoṣo. Torí náà, amọ̀ náà dúró fún àwọn èèyàn tó wà lábẹ́ ìṣàkóso Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà, àwọn èèyàn yìí ni kò jẹ́ kó le bí irin gẹ́gẹ́ bí Ilẹ̀ Ọba Róòmù. Bíbélì sọ pé amọ̀ náà jẹ́ “ọmọ aráyé,” tàbí àwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ gbáàtúù. (Dán. 2:43) Lábẹ́ ìṣàkóso Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà, àwọn èèyàn máa ń dìde láti jà fún ẹ̀tọ́ wọn nípasẹ̀ ìpolongo ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ àti àwọn tó ń jà fún òmìnira. Àwọn ará ìlú tí wọ́n jẹ́ gbáàtúù kò jẹ́ kí Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà lè lo agbára tó le bí irin. Bákan náà, àwọn èròǹgbà tó ta ko ti ìjọba àti èsì ìbò tó sún mọ́ ti àwọn tí ìjọba bọ́ sí lọ́wọ́ kì í jẹ́ kí àwọn aṣáájú tó gbajúmọ̀ pàápàá lè lo àṣẹ tí wọ́n ní láti ṣe àwọn ohun tí ìjọba wọn fẹ́ gbé ṣe. Dáníẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ìjọba náà yóò ní agbára lápá kan, yóò sì jẹ́ èyí tí ó gbẹgẹ́ lápá kan.”—Dán. 2:42; 2 Tím. 3:1-3.
10, 11. (a) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí “ẹsẹ̀” ère náà lọ́jọ́ iwájú? (b) Ibo la lè parí èrò sí nípa iye ọmọ ìka ẹsẹ̀ ère náà?
10 Àjọṣe tímọ́tímọ́ ṣì wà láàárín ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà títí di àkókò wa yìí, wọ́n sábà máa ń ṣe nǹkan pa pọ̀ tí ọ̀ràn kan bá ṣẹlẹ̀ nínú ayé. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ère arabarìbì náà àti ẹranko ẹhànnà náà fi hàn pé, kò sí agbára ayé míì tó máa rọ́pò Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà. Bó tílẹ̀ jẹ́ pé Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà tó kẹ́yìn yìí kò lágbára bíi Róòmù tí àwọn ẹsẹ̀ ère náà tó jẹ́ irin ṣàpẹẹrẹ, síbẹ̀ kò ní fúnra rẹ̀ kógbá wọlé.
11 Ǹjẹ́ iye ọmọ ìka ẹsẹ̀ ère náà ní ìtumọ̀ pàtàkì kankan? Gbé èyí yẹ̀ wò: Nínú àwọn ìran míì, Dáníẹ́lì sọ àwọn iye kan pàtó, bí àpẹẹrẹ, ó sọ iye àwọn ìwo tó wà ní orí onírúurú àwọn ẹranko tó rí. Àwọn iye yìí ní ìtumọ̀ pàtàkì. Àmọ́ ṣá o, nígbà tí Dáníẹ́lì ń ṣàpèjúwe ère náà, kò sọ iye ọmọ ìka ẹsẹ̀ rẹ̀. Torí náà, iye ọmọ ìka ẹsẹ̀ ère náà kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì bí iye àwọn apá, ọwọ́, ọmọ ìka ọwọ́ àti ẹsẹ̀ tí ère náà ní kò ti ṣe pàtàkì. Àmọ́ Dáníẹ́lì dìídì sọ pé ẹsẹ̀ ère náà jẹ́ àdàpọ̀ irin àti amọ̀. Nínú àpèjúwe tó ṣe, a lè parí èrò sí pé Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà ni yóò máa ṣàkóso ayé nígbà tí “òkúta” tó dúró fún Ìjọba Ọlọ́run bá kọlu ẹsẹ̀ ère náà.—Dán. 2:45.
AGBÁRA AYÉ GẸ̀Ẹ́SÌ ÒUN AMẸ́RÍKÀ ÀTI ẸRANKO ẸHÀNNÀ ONÍWO MÉJÌ
12, 13. Kí ni ẹranko ẹhànnà oníwo méjì náà dúró fún, kí ló sì ṣe?
12 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àdàpọ̀ irin àti amọ̀ ni Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà, síbẹ̀ ìran tí Jésù fi han Jòhánù jẹ́ ká rí i pé agbára ayé yìí á máa bá a nìṣó láti máa kó ipa pàtàkì láwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Lọ́nà wo? Jòhánù rí ìran ẹranko ẹhànnà oníwo méjì kan tó ń sọ̀rọ̀ bíi dírágónì. Kí ni ẹranko abàmì yìí ṣàpẹẹrẹ? Ìwo méjì ló ní, torí náà orílẹ̀-èdè méjì tó para pọ̀ di agbára ayé kan ṣoṣo ni. Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà náà ni ẹranko tí Jòhánù rí yìí, àmọ́ ó ń ṣe ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀.—Ka Ìṣípayá 13:11-15.
13 Ẹranko ẹhànnà yìí ń gbé yíyá ère ẹranko ẹhànnà tí Jòhánù kọ́kọ́ rí lárugẹ. Jòhánù kọ̀wé pé, ère ẹranko ẹhànnà náà ti wà tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí, síbẹ̀ ó máa tó gòkè wá. Ohun tó ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́ sí àjọ kan tí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ń gbé lárugẹ nìyẹn, ète tí wọ́n fi dá àjọ yìí sílẹ̀ ni láti mú kí ìjọba ayé wà ní ìṣọ̀kan, kó sì máa ṣojú fún wọn.d Ẹ̀yìn Ogun Àgbáyé Kìíní ni wọ́n dá àjọ yìí sílẹ̀, orúkọ rẹ̀ nígbà yẹn ni Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Àmọ́ àjọ yìí kógbá sílé nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀. Nígbà ogun yẹn, àwọn èèyàn Ọlọ́run kéde pé ní ìbámu pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ìwé Ìṣípayá, ère ẹranko ẹhànnà náà máa pa dà gòkè wá. Ó sì jáde wá lóòótọ́, gẹ́gẹ́ bí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè.—Ìṣí. 17:8.
14. Ọ̀nà wo ni ère ẹranko ẹhànnà náà gbà jẹ́ “ọba kẹjọ”?
14 Jòhánù pe ère ẹranko náà ní “ọba kẹjọ.” Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Ìwé Ìṣípayá kò ṣàfihàn rẹ̀ pé ó jẹ́ ìkẹjọ lára orí ẹranko ẹhànnà tí Jòhánù kọ́kọ́ rí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ère ẹranko yẹn. Àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nínú àjọ yẹn ló fún un ní agbára, ní pàtàkì jù lọ Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà, tó jẹ́ ògúnnágbòǹgbò alátìlẹyìn rẹ̀. (Ìṣí. 17:10, 11) Àmọ́ ó gba àṣẹ gẹ́gẹ́ bí ọba kó lè ṣe iṣẹ́ pàtàkì kan tó máa kan gbogbo ayé.
ÈRE ẸRANKO ẸHÀNNÀ NÁÀ PA AṢẸ́WÓ NÁÀ RUN
15, 16. Kí ni aṣẹ́wó náà ṣàpẹẹrẹ, kí ló sì ti ṣẹlẹ̀ sí ìtìlẹyìn tó ń rí látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn?
15 Jòhánù sọ pé òun rí aṣẹ́wó ìṣàpẹẹrẹ kan tó jókòó lórí ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò kan, ìyẹn ère ẹranko ẹhànnà náà. Ó ní orúkọ náà “Bábílónì Ńlá.” (Ìṣí. 17:1-6) Ó bá a mu gan-an pé aṣẹ́wó yìí dúró fún gbogbo ẹ̀sìn èké, èyí tí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì jẹ́ òléwájú nínú wọn. Àwọn ètò ẹ̀sìn ti ṣètìlẹ́yìn fún ère ẹranko ẹhànnà náà, wọ́n sì ti gbìyànjú láti nípa lórí rẹ̀.
16 Àmọ́ ṣá o, ní ọjọ́ Olúwa, Bábílónì Ńlá ti fojú ara rẹ̀ rí àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ tí ìwé Ìṣípayá fi wé omi, tí wọ́n ń gbẹ táútáú. (Ìṣí. 16:12; 17:15) Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ère ẹranko náà kọ́kọ́ fara hàn, àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, tó jẹ́ apá pàtàkì nínú Bábílónì Ńlá, ló pọ̀ jù lọ ní ilẹ̀ Yúróòpù àti Amẹ́ríkà. Lóde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn kò ka àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì àtàwọn aṣáájú ẹ̀sìn sí mọ́, wọn kò sì tì wọ́n lẹ́yìn mọ́. Kódà ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ìsìn ń dá kún rògbòdìyàn tàbí pé ìsìn gan-an ló ń dá a sílẹ̀. Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n tí wọ́n jẹ́ abẹnugan àtàwọn ajìjàgbara nílẹ̀ Yúróòpù àti Amẹ́ríkà ń wá bí wọ́n ṣe máa fi òpin sí ipa tí ẹ̀sìn ń ní lórí àwọn èèyàn.
17. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí ìsìn èké láìpẹ́, kí sì nìdí?
17 Àmọ́, kì í ṣe pé ńṣe ni ẹ̀sìn èké máa bẹ̀rẹ̀ sí í pòórá díẹ̀díẹ̀ o. Aṣẹ́wó yìí á ṣì máa ní ipa tó lágbára lórí àwọn ọba, á máa gbìyànjú láti mú kí wọ́n máa ṣe ohun tí òun fẹ́, títí tí Ọlọ́run yóò fi fi ohun kan sọ́kàn àwọn tó wà nípò àṣẹ. (Ka Ìṣípayá 17:16, 17.) Láìpẹ́, Jèhófà máa mú kí àwọn olóṣèlú inú ayé Sátánì, tí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ń ṣojú fún, dojú ìjà kọ ẹ̀sìn èké. Wọn kò ní jẹ́ kó nípa lórí àwọn mọ́, wọ́n á sì ba àwọn ohun àmúṣọrọ̀ rẹ̀ jẹ́. Ní nǹkan bí ogún tàbí ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn, irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ lè jọ ohun tí kò lè wáyé. Àmọ́ lóde òní, aṣẹ́wó náà ti ń mì bí ẹni tó fẹ́ já bọ́ lẹ́yìn ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà. Àmọ́, ìyẹn kò fi hàn pé ńṣe ló máa rọra já bọ́ lórí rẹ̀ o. Kàkà bẹ́ẹ̀, òjijì ló máa já bọ́, tó sì máa pa run.—Ìṣí. 18:7, 8, 15-19.
ÀWỌN ẸRANKO NÁÀ PA RUN
18. (a) Kí ni ẹranko ẹhànnà náà máa ṣe, kí ló sì máa jẹ́ àbájáde rẹ̀? (b) Àwọn ìjọba wo ni Dáníẹ́lì 2:44 sọ pé Ìjọba Ọlọ́run máa pa run? (Wo àpótí tó wà ní ojú ìwé 17.)
18 Lẹ́yìn tí ẹ̀sìn èké bá ti pa run, Sátánì á mú kí ẹranko ẹhànnà náà, ìyẹn ètò ìṣèlú Sátánì ti ilẹ̀ ayé, kọjú ìjà sí Ìjọba Ọlọ́run. Níwọ̀n bí kò ti ní ṣeé ṣe fún àwọn ọba ilẹ̀ ayé láti dé ọ̀run, wọ́n á wá kọjú ìbínú wọn sí àwọn tó ń ti Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé. Èyí ló máa yọrí sí ogun Ọlọ́run. (Ìṣí. 16:13-16; 17:12-14) Dáníẹ́lì ṣàpèjúwe apá kan lára ogun àjàkẹ́yìn yìí. (Ka Dáníẹ́lì 2:44.) Ẹranko ẹhànnà tí Ìṣípayá 13:1 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ère rẹ̀ àti ẹranko ẹhànnà oníwo méjì náà, máa ṣègbé.
19. Kí ló yẹ kó dá wa lójú, kí ló sì yẹ ká máa ṣe báyìí?
19 Àkókò tí ìkeje lára orí ẹranko ẹhànnà náà ń ṣàkóso la wà yìí. Kò sí orí míì tó máa yọ lára ẹranko yìí mọ́ kó tó pa run. Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ló máa wà lójú ọpọ́n nígbà tí ẹ̀sìn èké bá pa run. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì àti ti Jòhánù ti ní ìmúṣẹ gẹ́lẹ́ bí Jèhófà ṣe fẹ́ kó rí. Ó dá wa lójú pé kò ní pẹ́ mọ́ tí ìparun ẹ̀sìn èké àti ogun Amágẹ́dọ́nì fi máa dé. Ọlọ́run ti ṣí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ yìí payá fún wa kí wọ́n tó wáyé. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ a máa fiyè sí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó jẹ́ ìkìlọ̀ yìí? (2 Pét. 1:19) Àkókò nìyí fún wa láti dúró síhà ọ̀dọ̀ Jèhófà ká sì máa ti Ìjọba rẹ̀ lẹ́yìn.—Ìṣí. 14:6, 7.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nínú Bíbélì, nọ́ńbà náà ẹẹ́wàá sábà máa ń ṣàpẹẹrẹ àpapọ̀ ohun tó pé pérépéré. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ yìí, ẹẹ́wàá dúró fún gbogbo ìjọba tó jáde wá látinú Ilẹ̀ Ọba Róòmù lápapọ̀.
b Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn orílẹ̀-èdè méjì tó para pọ̀ di agbára ayé náà ti wà láti ọ̀rúndún kejìdínlógún [18], àmọ́ ìran tí Jòhánù rí fi hàn pé àwọn méjèèjì máa di agbára ayé kan ṣoṣo ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ Olúwa. Ní tòótọ́, “ọjọ́ Olúwa” ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé Ìṣípayá ní ìmúṣẹ. (Ìṣí. 1:10) Ìgbà Ogun Àgbáyé Kìíní ni ìkeje lára orí ẹranko ẹhànnà náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí agbára ayé kan ṣoṣo.
c Dáníẹ́lì rí ìparun tó burú jáì tí ọba yìí máa fà nígbà ogun náà, ó kọ̀wé pé: “Yóò sì fa ìparun ní ọ̀nà àgbàyanu [lọ́nà tí ń bani lẹ́rù].” (Dán. 8:24) Bí àpẹẹrẹ, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fa ìparun tó lágbára gan-an nígbà tó ju àdó olóró méjì sí orílẹ̀-èdè kan tó jẹ́ ọ̀tá Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà.
d Wo ìwé Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀! ojú ìwé 240, 241 àti 253.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]
ÀWỌN WO LÓ PARA PỌ̀ DI ÀWỌN “ÌJỌBA WỌ̀NYÍ”?
Àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Dáníẹ́lì 2:44 sọ pé Ìjọba Ọlọ́run “yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn.” Àwọn ìjọba tí onírúurú apá tí ère náà pín sí ṣàpẹẹrẹ nìkan ni àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ń tọ́ka sí.
Gbogbo àwọn ìjọba èèyàn yòókù ńkọ́? Àsọtẹ́lẹ̀ míì tó fara jọ èyí nínú ìwé Ìṣípayá jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà túbọ̀ ṣe kedere. Ó fi hàn pé “àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá” máa kóra jọ pọ̀ lòdì sí Jèhófà ní “ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.” (Ìṣí. 16:14; 19:19-21) Èyí fi hàn pé àwọn ìjọba tí ère náà ṣàpẹẹrẹ àti gbogbo àwọn ìjọba èèyàn yòókù ló máa pa run nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì.
-
-
A Ṣí Àwọn Ọba Mẹ́jọ PayáIlé Ìṣọ́—2012 | June 15
-
-
A Ṣí Àwọn Ọba Mẹ́jọ Payá
Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Dáníẹ́lì àti ìwé Ìṣípayá jẹ́ ká mọ ohun tí àwọn ọba mẹ́jọ tàbí ìṣàkóso àwọn èèyàn jẹ́, wọ́n sì tún sọ bí wọ́n ṣe máa fara hàn ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. A máa mọ ohun tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn túmọ̀ sí, tá a bá lóye àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ pàá nínú Bíbélì.
Ọjọ́ pẹ́ tí Sátánì ti ń ṣètò irú ọmọ rẹ̀ sí onírúurú ẹgbẹ́ òṣèlú tàbí àwọn ìjọba. (Lúùkù 4:5, 6) Àmọ́, díẹ̀ lára àwọn ìjọba èèyàn ló tíì ní ipa tó lágbára gan-an lórí àwọn èèyàn Ọlọ́run, ì báà jẹ́ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tàbí ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró. A ṣàpèjúwe mẹ́jọ péré lára irú àwọn ìjọba alágbára bẹ́ẹ̀ nínú àwọn ìran tí Dáníẹ́lì àti Jòhánù rí.
[Àtẹ Ìsọfúnnni/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12, 13]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
ÀWỌN ÀSỌTẸ́LẸ̀ ÀWỌN ÀSỌTẸ́LẸ̀
INÚ ÌWÉ DÁNÍẸ́LÌ INÚ ÌWÉ ÌṢÍPAYÁ
1. Íjíbítì
2. Ásíríà
3. Bábílónì
4. Mídíà òun Páṣíà
5. Gíríìsì
6. Róòmù
7. Gẹ̀ẹ́sì àti
Amẹ́ríkàa
8. Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè àti
Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdèb
ÀWỌN ÈÈYÀN ỌLỌ́RUN
Ọdún 2000 Ṣ.S.K.
Ábúráhámù
1500
Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì
1000
Dáníẹ́lì 500
Ṣ.S.K./S.K.
Jòhánù
Ísírẹ́lì Ọlọ́run 500
1000
1500
2000 S.K.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn ọba méjèèjì ló wà ní àkókò òpin. Wo ojú ìwé 19.
b Àwọn ọba méjèèjì ló wà ní àkókò òpin. Wo ojú ìwé 19.
[Àwòrán]
Ère arabarìbì (Dán. 2:31-45)
Àwọn ẹranko mẹ́rin tí wọ́n jáde wá látinú òkun (Dán. 7:3-8, 17, 25)
Àgbò àti òbúkọ (Dán., orí 8)
Ẹranko ẹhànnà olórí méje (Ìṣí. 13:1-10, 16-18)
Ẹranko oníwo méjì náà ṣagbátẹrù yíyá ère ẹranko ẹhànnà náà (Ìṣí. 13:11-15)
[Àwọn Credit Line]
Ibi tí a ti mú àwọn àwòrán: Íjíbítì àti Róòmù: A ya fọ́tò yìí nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Ibi Àkójọ Ohun Ìṣẹ̀ǹbáyé Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì; Mídíà òun Páṣíà: Musée du Louvre, Paris
-