ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Ọba Àríwá” Ní Àkókò Òpin Yìí
    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020 | May
    • ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 19

      “Ọba Àríwá” Ní Àkókò Òpin Yìí

      “Ní àkókò òpin, ọba gúúsù máa kọ lu [ọba àríwá].”​—DÁN. 11:40.

      ORIN 150 Wá Ọlọ́run Kó O Lè Rí Ìgbàlà

      OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa

      1. Kí ni àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀?

      KÍ LÓ máa ṣẹlẹ̀ sáwa èèyàn Jèhófà láìpẹ́? Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ kò ṣàjèjì sí wa. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan pàtàkì tó máa ṣẹlẹ̀ táá sì kàn wá. Àsọtẹ́lẹ̀ kan wà nínú Bíbélì tó jẹ́ ká mọ ohun táwọn ìjọba tó lágbára jù lọ láyé máa ṣe. Inú Dáníẹ́lì orí kọkànlá (11) ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí wà. Ó sọ nípa ọba méjì tí wọ́n ń bá ara wọn jà, ìyẹn ọba àríwá àti ọba gúúsù. Apá tó pọ̀ jù lára àsọtẹ́lẹ̀ yìí ló ti nímùúṣẹ, ìyẹn sì jẹ́ kó dá wa lójú pé apá tó ṣẹ́ kù lára ẹ̀ náà máa ṣẹ láìsí tàbí ṣùgbọ́n.

      2. Bó ṣe wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:15 àti Ìfihàn 11:7; 12:​17, àwọn nǹkan wo ló yẹ ká fi sọ́kàn bá a ṣe ń ṣàyẹ̀wò àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì?

      2 Ká lè lóye àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Dáníẹ́lì orí kọkànlá (11), ó yẹ ká fi sọ́kàn pé àwọn ìjọba àtàwọn alákòóso tí wọ́n ní ohun kan pàtó tí wọ́n ṣe sí àwọn èèyàn Ọlọ́run nìkan ni àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn Ọlọ́run kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ ní ìfiwéra pẹ̀lú àwọn tó wà láyé, àwọn ni ìjọba ayé sábà máa ń dájú sọ. Kí nìdí? Ìdí ni pé ohun kan ṣoṣo tó gba Sátánì àti ayé burúkú yìí lọ́kàn ni bí wọ́n ṣe máa run àwọn tó ń sin Jèhófà tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 3:15 àti Ìfihàn 11:7; 12:17.) Ohun míì tó yẹ ká fi sọ́kàn ni pé àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ìwé Dáníẹ́lì gbọ́dọ̀ bá àwọn àsọtẹ́lẹ̀ míì tó wà nínú Bíbélì mu. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ká tó lè ní òye tó kún rẹ́rẹ́ nípa àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ìwé Dáníẹ́lì, ó ṣe pàtàkì ká wo àwọn apá míì nínú Ìwé Mímọ́.

      3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí àtèyí tó tẹ̀ lé e?

      3 Pẹ̀lú àwọn kókó yìí lọ́kàn, ẹ jẹ́ ká wá jíròrò ohun tó wà nínú Dáníẹ́lì 11:25-39. A máa rí ẹni tí ọba àríwá àti ọba gúúsù jẹ́ láàárín ọdún 1870 sí 1991, àá sì rídìí tó fi bọ́gbọ́n mu pé ká ṣàtúnṣe sí òye tá a ní tẹ́lẹ̀ nípa apá kan nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò Dáníẹ́lì 11:40–12:1, àá sì ṣàtúnṣe sí òye wa nípa ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ láàárín ọdún 1990 sí ìgbà tí ogun Amágẹ́dọ́nì máa jà. Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ àpilẹ̀kọ yìí, wàá jàǹfààní gan-an tó o bá ń wo àtẹ tá a pè ní “Àwọn Ọba Tó Ń Bára Wọn Jà Lákòókò Òpin Yìí.” Lákọ̀ọ́kọ́ ná, àwọn wo ni àsọtẹ́lẹ̀ yẹn pè ní ọba àríwá àti ọba gúúsù?

      BÍ A ṢE LÈ DÁ ỌBA ÀRÍWÁ ÀTI ỌBA GÚÚSÙ MỌ̀

      4. Àwọn kókó mẹ́ta wo ló máa jẹ́ ká lè dá ọba àríwá àti ọba gúúsù mọ̀?

      4 Níbẹ̀rẹ̀, gbólóhùn náà “ọba àríwá” àti “ọba gúúsù” tọ́ka sí àwọn ọba tó ṣàkóso láwọn ilẹ̀ tó wà lápá àríwá àti gúúsù orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Kíyè sí ohun tí áńgẹ́lì tí Ọlọ́run rán sí Dáníẹ́lì sọ, ó ní: “Mo wá láti jẹ́ kí o lóye ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn rẹ ní àkókò òpin.” (Dán. 10:14) Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ni àwọn èèyàn Ọlọ́run títí dìgbà Pẹ́ńtíkọ́sì 33 Sànmánì Kristẹni. Àmọ́ látìgbà yẹn wá, Jèhófà mú kó ṣe kedere pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tó jẹ́ olóòótọ́ ni àwọn èèyàn òun. Nítorí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi ni èyí tó pọ̀ jù lára àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì orí kọkànlá (11) kàn, kì í ṣe orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. (Ìṣe 2:1-4; Róòmù 9:6-8; Gál. 6:​15, 16) Àmọ́ látìgbàdégbà ni ìyípadà ń bá àwọn tó jẹ́ ọba àríwá àti ọba gúúsù. Bó ti wù kó rí, àwọn nǹkan kan wà tí kò yí pa dà. Àkọ́kọ́, àwọn ọba yẹn ń ṣàkóso lé àwọn èèyàn Ọlọ́run lórí tàbí kí wọ́n ṣenúnibíni sí wọn. Ìkejì, bí wọ́n ṣe ń fojú pọ́n àwọn èèyàn Ọlọ́run fi hàn pé wọ́n kórìíra Jèhófà tó jẹ́ Ọlọ́run tòótọ́. Kókó kẹta ni pé àwọn ọba méjèèjì yìí máa ń bá ara wọn jà láti mọ ẹni tó jẹ́ ọ̀gá.

      5. Ṣé ọba àríwá àti ọba gúúsù wà láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní sí ọdún 1870? Ṣàlàyé.

      5 Láwọn ọdún mélòó kan lẹ́yìn ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn afàwọ̀rajà tí wọ́n pe ara wọn ní Kristẹni rọ́ wọnú ìjọ, wọ́n sì ń fi ẹ̀kọ́ èké kọ́ni dípò ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì. Látìgbà yẹn títí di ọdún 1870, kò sí àwùjọ àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tó wà létòlétò tí wọ́n sì ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Àwọn èké Kristẹni ló gbòde kan bí ìgbà tí èpò bá gbalẹ̀, ìdí nìyẹn tó fi ṣòro láti mọ àwọn tó jẹ́ Kristẹni tòótọ́. (Mát. 13:36-43) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká mọ kókó yìí? Èyí jẹ́ ká rí i pé ohun tí Bíbélì sọ nípa ọba àríwá àti ọba gúúsù kò kan àwọn alákòóso tàbí ìjọba tó wà nípò láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní sí ọdún 1870. Kò sí àwùjọ àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tòótọ́ tí wọ́n lè gbógun tì.b Àmọ́, a lè retí pé kí ọba àríwá àti ọba gúúsù fara hàn lẹ́yìn ọdún 1870. Báwo la ṣe mọ̀?

      6. Ìgbà wo làwọn èèyàn Ọlọ́run tún bẹ̀rẹ̀ sí í wà létòlétò? Ṣàlàyé.

      6 Látọdún 1870 lọ, àwọn èèyàn Ọlọ́run tún bẹ̀rẹ̀ sí í wà létòlétò. Ọdún yẹn ni Arákùnrin Charles T. Russell àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ dá àwùjọ tí wọ́n jọ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sílẹ̀. Arákùnrin Russell àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ló dà bí ìránṣẹ́ Jèhófà tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa “tún ọ̀nà ṣe” ká tó fìdí Ìjọba Mèsáyà múlẹ̀. (Mál. 3:1) Ó ti wá ṣeé ṣe báyìí láti dá àwọn èèyàn Ọlọ́run mọ̀! Ǹjẹ́ agbára ayé èyíkéyìí wà nígbà yẹn tó máa nípa lórí àwọn èèyàn Ọlọ́run? Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn kókó tó tẹ̀ lé e yìí yẹ̀ wò.

      TA NI ỌBA GÚÚSÙ?

      7. Ta ni ọba gúúsù láti ọdún 1870 títí dìgbà Ogun Àgbáyé Kìíní?

      7 Nígbà tó fi máa dọdún 1870, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti ń ṣàkóso àwọn ilẹ̀ tó pọ̀ jù láyé, òun ló sì ní ẹgbẹ́ ológun tó lágbára jù lọ. Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì sọ̀rọ̀ nípa ìwo kékeré kan tó ṣẹ́gun ìwo mẹ́ta míì. Ìwo kékeré yẹn ṣàpẹẹrẹ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nígbà táwọn ìwo yòókù ṣàpẹẹrẹ ilẹ̀ Faransé, orílẹ̀-èdè Sípéènì àti Netherlands. (Dán. 7:7, 8) Òun ni ọba gúúsù títí dìgbà Ogun Àgbáyé Kìíní. Láàárín àsìkò yìí kan náà, Amẹ́ríkà ni orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ jù lọ láyé, ó sì ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

      8. Ta ni ọba gúúsù láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí?

      8 Nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì jọ pawọ́ pọ̀ ja ogun náà, ìyẹn sì mú kí wọ́n lágbára gan-an. Àsìkò yẹn ni wọ́n di ohun tá a mọ̀ lónìí sí Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà. Bí Dáníẹ́lì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ọba yìí ní “ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ogun tó lágbára lọ́nà àrà ọ̀tọ̀.” (Dán. 11:25) Láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ni ọba gúúsù.c Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ta wá ni ọba àríwá?

      Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Nípa Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà

      Onírúurú ọ̀nà ni Bíbélì gbà ṣàpèjúwe Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà tó dúró fún ọba gúúsù. Lára ọ̀nà tó gbà ṣàpèjúwe ẹ̀ nìyí . . .

      • Àtẹ́lẹsẹ̀ tó jẹ́ irin àti amọ̀.

        àtẹ́lẹsẹ̀ tó jẹ́ irin àti amọ̀ (Dán. 2:​41-43)

      • Orí ẹranko kan tó ní ìwo tó pọ̀. Ìwo kékeré kan tó ní ojú àti ẹnu hù jáde láàárín àwọn ìwo náà.

        ìwo tó hù jáde lórí ẹranko tó ń bani lẹ́rù (Dán. 7:​7, 8)

      • Ẹranko kan tó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá.

        ìkeje lára orí ẹranko kan (Ìfi. 13:1)

      • Ẹranko kan tó ní ìwo méjì.

        ẹranko tó ní ìwo méjì (Ìfi. 13:​11-15)

      • Àwọn ilé ìjọba tó dúró fún Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà.

        “wòlíì èké” (Ìfi. 19:20)

      ỌBA ÀRÍWÁ TÚN FARA HÀN

      9. Ìgbà wo ni ọba àríwá tún fara hàn, báwo sì lọ̀rọ̀ tó wà nínú Dáníẹ́lì 11:25 ṣe nímùúṣẹ?

      9 Ní 1871, ìyẹn ọdún kan lẹ́yìn tí Russell àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ dá àwùjọ tí wọ́n jọ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sílẹ̀, ọba àríwá tún fara hàn. Lọ́dún yẹn, Otto von Bismarck pa àwọn ìlú mélòó kan tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn pọ̀, ó sì pè é ní orílẹ̀-èdè Jámánì. Ọba Wilhelm Kìíní tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Prussia ni olú ọba àkọ́kọ́, ó sì yan Bismarck ṣe olórí ìjọba àkọ́kọ́.d Bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, orílẹ̀-èdè Jámánì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso àwọn orílẹ̀-èdè míì ní Áfíríkà àtàwọn erékùṣù tó wà ní Òkun Pàsífíìkì, ó sì ń wá bó ṣe máa lágbára ju ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ. (Ka Dáníẹ́lì 11:25.) Ilẹ̀ Jámánì ní ẹgbẹ́ ológun tó lágbára, kódà òun ni orílẹ̀-èdè kejì táwọn ọmọ ogun ojú omi rẹ̀ pọ̀ jù lọ láyé. Àwọn ẹgbẹ́ ológun yìí ni Jámánì lò láti bá àwọn ọ̀tá rẹ̀ jà nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní.

      10. Báwo ni Dáníẹ́lì 11:25b, 26 ṣe nímùúṣẹ?

      10 Dáníẹ́lì wá sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ilẹ̀ Jámánì àtàwọn ẹgbẹ́ ológun rẹ̀. Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn jẹ́ kó ṣe kedere pé ọba àríwá kò “ní dúró.” Kí nìdí? “Torí wọ́n máa gbèrò ibi sí i. Àwọn tó ń jẹ oúnjẹ aládùn rẹ̀ máa fa ìṣubú rẹ̀.” (Dán. 11:25b, 26a) Lásìkò tí Dáníẹ́lì gbáyé, lára àwọn tó ń jẹ “oúnjẹ aládùn tí ọba ń jẹ” ni àwọn ìjòyè tó ń “bá ọba ṣiṣẹ́.” (Dán. 1:5) Àwọn wo gan-an ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? Àwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn tó wà nínú ìjọba ilẹ̀ Jámánì ni, títí kan àwọn olórí ogun àtàwọn agbaninímọ̀ràn ìjọba. Àwọn yìí ló fa ìṣubú ilẹ̀ ọba náà.e Yàtọ̀ sí pé àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sọ ohun tó máa fa ìṣubú ilẹ̀ ọba náà, ó tún sọ àbájáde ogun tó wáyé láàárín òun àti ọba gúúsù. Ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ nípa ọba àríwá ni pé: “Ní ti àwọn ọmọ ogun rẹ̀, a máa gbá wọn lọ, a sì máa pa ọ̀pọ̀ nínú wọn run.” (Dán. 11:26b) Bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe sọ ló rí, àwọn ọ̀tá gbá àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Jámánì lọ, wọ́n sì “pa ọ̀pọ̀ nínú wọn run.” Tá a bá fi wéra pẹ̀lú àwọn ogun tó ti wáyé ṣáájú ìgbà yẹn, ogun yẹn ló tíì burú jù nínú ìtàn ẹ̀dá.

      11. Kí ni ọba àríwá àti ọba gúúsù ṣe?

      11 Nígbà tí Dáníẹ́lì 11:27, 28 sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ṣáájú Ogun Àgbáyé Kìíní, ó sọ pé ọba àríwá àti ọba gúúsù “máa jókòó sídìí tábìlì kan náà, wọ́n á [sì] máa parọ́ fúnra wọn.” Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn tún sọ pé ọba àríwá tún máa kó “ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹrù” jọ. Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ nìyẹn lóòótọ́. Ilẹ̀ Jámánì àti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì jọ ṣàdéhùn pé àlàáfíà máa wà, àmọ́ ogun tí wọ́n bára wọn jà lọ́dún 1914 fi hàn pé irọ́ ni wọ́n pa fúnra wọn. Láwọn ọdún tó ṣáájú 1914, ilẹ̀ Jámánì ní ọrọ̀ tó pọ̀ gan-an, kódà òun ni orílẹ̀-èdè kejì tó lọ́rọ̀ jù lọ láyé. Lẹ́yìn náà, kí àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Dáníẹ́lì 11:29 àti apá àkọ́kọ́ nínú ẹsẹ 30 lè nímùúṣẹ, ilẹ̀ Jámánì bá ọba gúúsù jagun, àmọ́ ó fìdí rẹmi.

      ÀWỌN ỌBA MÉJÈÈJÌ BÁ ÀWỌN ÈÈYÀN ỌLỌ́RUN JÀ

      12. Kí ni ọba àríwá àti ọba gúúsù ṣe nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní?

      12 Bẹ̀rẹ̀ látọdún 1914, ńṣe ni ogun táwọn ọba méjèèjì yìí ń bára wọn jà túbọ̀ ń gbóná, wọ́n sì ń dojú àtakò kọ àwọn èèyàn Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, ìjọba ilẹ̀ Jámánì àti ti Gẹ̀ẹ́sì ṣenúnibíni sáwọn èèyàn Ọlọ́run torí pé wọn ò dá sí ọ̀rọ̀ ogun. Bákan náà, ìjọba orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ju àwọn tó ń múpò iwájú láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run sẹ́wọ̀n. Èyí ló mú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Ìfihàn 11:​7-10 ṣẹ.

      13. Kí ni ọba àríwá ṣe lẹ́yìn ọdún 1930 àti nígbà Ogun Àgbáyé Kejì?

      13 Nígbà tó yá, ìyẹn lẹ́yìn ọdún 1930, pàápàá nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, ọba àríwá fayé ni àwọn èèyàn Ọlọ́run lára gan-an. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ẹgbẹ́ òṣèlú Násì gbàjọba lórílẹ̀-èdè Jámánì, Hitler àtàwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ fòfin de iṣẹ́ táwọn èèyàn Ọlọ́run ń ṣe. Àwọn ọ̀tá yìí pa àwọn bí ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ lára àwọn èèyàn Jèhófà, wọ́n sì rán ẹgbẹẹgbẹ̀rún míì lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Dáníẹ́lì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀. Bọ́rọ̀ sì ṣe rí nìyẹn torí ọba àríwá ‘sọ ibi mímọ́ di aláìmọ́, ó sì mú ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà gbogbo kúrò’ ní ti pé ó jẹ́ kó nira fáwọn èèyàn Jèhófà láti máa yìn ín kí wọ́n sì máa kéde orúkọ rẹ̀ ní gbangba. (Dán. 11:30b, 31a) Kódà, Hitler tó jẹ́ aṣáájú ìjọba Násì lérí pé òun máa pa gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà run ráúráú nílẹ̀ Jámánì.

      ỌBA ÀRÍWÁ MÍÌ DÌDE

      14. Ta ni ọba àríwá lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì? Ṣàlàyé.

      14 Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, ìjọba Kọ́múníìsì ti Soviet Union ṣẹ́gun ilẹ̀ Jámánì, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ di ọba àríwá. Bíi ti àwọn aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀ nígbà ìjọba Násì, ìjọba Soviet Union náà fayé ni àwọn èèyàn Jèhófà lára gan-an torí pé wọ́n ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run tòótọ́ dípò kí wọ́n máa ṣègbọràn sí ìjọba èèyàn láìfi ti Ọlọ́run pè.

      15. Kí ni ọba àríwá ṣe lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kejì parí?

      15 Kété lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kejì parí, Soviet Union tó jẹ́ ọba àríwá tuntun àtàwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ dojú ìjà kọ àwọn èèyàn Ọlọ́run. Bí Ìfihàn 12:15-17 ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ọba yìí fòfin de iṣẹ́ àwọn èèyàn Jèhófà, ó sì rán ẹgbẹẹgbẹ̀rún lára wọn lọ sí ìgbèkùn. Kódà, jálẹ̀ àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí ni ọba àríwá fi ń ṣenúnibíni sáwọn èèyàn Ọlọ́run bí ìgbà tí “odò” bá ya luni, àmọ́ pàbó ni gbogbo ìsapá rẹ̀ já sí.f

      16. Báwo ni ìjọba Soviet Union ṣe mú àsọtẹ́lẹ̀ inú Dáníẹ́lì 11:​37-39 ṣẹ?

      16 Ka Dáníẹ́lì 11:37-39. Bí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe sọ, ọba àríwá kò “ka Ọlọ́run àwọn bàbá rẹ̀ sí.” Ọ̀nà wo ló gbà ṣe bẹ́ẹ̀? Ìjọba Soviet Union wá bó ṣe máa pa gbogbo ẹ̀sìn run, torí náà ó fojú àwọn ẹlẹ́sìn rí màbo, ó sì gba àwọn ohun àmúṣọrọ̀ wọn. Kó lè mú ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀ ṣẹ, lọ́dún 1918 ìjọba Soviet Union ṣòfin kan tó mú kí wọ́n máa kọ́ àwọn ọmọ ilé ìwé pé kò sí Ọlọ́run. Báwo ni ọba àríwá ṣe “yin ọlọ́run ibi ààbò lógo”? Ìjọba Soviet Union ná òbítíbitì owó láti mú kí àwọn ẹgbẹ́ ológun rẹ̀ lágbára gan-an àti láti ṣe àwọn ohun ìjà runlérùnnà kí ìjọba rẹ̀ lè túbọ̀ lágbára. Bó ṣe di pé tọ̀tún-tòsì wọn, ìyẹn ọba àríwá àti ọba gúúsù to àwọn ohun ìjà jọ pelemọ nìyẹn, kódà àwọn ohun ìjà náà lágbára débi pé wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ lè pa gbogbo ayé run!

      ÀWỌN ỌBA MÉJÈÈJÌ PAWỌ́ PỌ̀ ṢE OHUN KAN

      17. Kí ni “ohun ìríra tó ń fa ìsọdahoro”?

      17 Ohun pàtàkì kan wà tí ọba àríwá ṣe ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ọba gúúsù, ohun náà ni pé wọ́n “gbé ohun ìríra tó ń fa ìsọdahoro kalẹ̀.” (Dán. 11:31) Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ni “ohun ìríra” náà.

      18. Kí nìdí tí Bíbélì fi pe Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ní “ohun ìríra”?

      18 Bíbélì pe Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ní “ohun ìríra” nítorí pé ó ṣèlérí pé òun máa mú àlàáfíà wá sáyé, bẹ́ẹ̀ sì rèé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè mú àlàáfíà wá. Àsọtẹ́lẹ̀ yìí sọ pé ohun ìríra náà máa “fa ìsọdahoro” torí pé Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè máa dojú kọ gbogbo ìsìn èké, ó sì máa pa wọ́n run.​—Wo àtẹ tá a pè ní “Àwọn Ọba Tó Ń Bára Wọn Jà Lákòókò Òpin Yìí.”

      KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ MỌ OHUN TÁ A JÍRÒRÒ YÌÍ?

      19-20. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká mọ àwọn ohun tá a jíròrò yìí? (b) Ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

      19 Ó yẹ ká mọ àwọn ohun tá a jíròrò tán yìí torí pé láàárín ọdún 1870 sí 1991, àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì nípa ọba àríwá àti ọba gúúsù ní ìmúṣẹ. Fún ìdí yìí, ó dá wa lójú pé àwọn apá tó kù nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà máa nímùúṣẹ.

      20 Lọ́dún 1991, ìjọba Soviet Union wá sópin ó sì pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ta wá ni ọba àríwá lásìkò wa yìí? A máa rí ìdáhùn nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

      KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

      • Ohun mẹ́ta wo ló jẹ́ ká mọ “ọba àríwá” àti “ọba gúúsù”?

      • Ta ni ọba àríwá àti ọba gúúsù láàárín ọdún 1870 sí 1991?

      • Kí nìdí tó fi yẹ ká mọ àwọn ohun tá a jíròrò yìí?

      ORIN 128 Bí A Ṣe Lè Fara Dà Á Dópin

      a Ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì nípa “ọba àríwá” àti “ọba gúúsù” ṣì ń nímùúṣẹ. Kí ló mú kó dá wa lójú? Kí sì nìdí tó fi yẹ ká lóye kúlẹ̀kúlẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí?

      b Pẹ̀lú àlàyé yìí, kò bá a mu láti pe Aurelian tó jẹ́ Olú Ọba Róòmù (270-275 S.K.) ní “ọba àríwá” bẹ́ẹ̀ sì ni kò bá a mu láti pe Ọbabìnrin Zenobia (267-272 S.K.) ní “ọba gúúsù.” Àtúnṣe lèyí jẹ́ sí àlàyé tá a ṣe ní orí 13 àti 14 nínú ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì!

      c Wo àpótí náà “Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Nípa Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà.”

      d Lọ́dún 1890, Olú Ọba Wilhelm Kejì lé Bismarck kúrò lórí oyè.

      e Ọ̀pọ̀ nǹkan tí wọ́n ṣe ló jẹ́ kí ilẹ̀ ọba náà tètè ṣubú. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n pa dà lẹ́yìn olú ọba náà, wọ́n tú àṣírí bí àwọn ṣe fẹ́ ja ogun yẹn fáwọn ọ̀tá, wọ́n sì fipá mú olú ọba náà láti fipò rẹ̀ sílẹ̀.

      f Bó ṣe wà nínú Dáníẹ́lì 11:​34, àwọn Kristẹni tó wà láwọn ilẹ̀ tí ọba àríwá ń ṣàkóso rí ìtura fúngbà díẹ̀. Èyí ṣẹlẹ̀ nígbà tí ìjọba Soviet Union wá sópin tó sì pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ lọ́dún 1991.

  • Ta Ni “Ọba Àríwá” Lónìí?
    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020 | May
    • ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 20

      Ta Ni “Ọba Àríwá” Lónìí?

      “Ó máa . . . pa run, kò sì ní sẹ́ni tó máa ràn án lọ́wọ́.”​—DÁN. 11:45.

      ORIN 95 Ìmọ́lẹ̀ Náà Ń Mọ́lẹ̀ Sí I

      OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa

      1-2. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

      ÀWỌN nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lónìí ti túbọ̀ jẹ́ kó ṣe kedere pé apá tó kẹ́yìn lára àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ayé burúkú yìí là ń gbé. Láìpẹ́, Jèhófà àti Jésù Kristi máa pa gbogbo ìṣàkóso tó ń ta ko Ìjọba Ọlọ́run run. Àmọ́ kíyẹn tó ṣẹlẹ̀, ọba àríwá àti ọba gúúsù á ṣì máa bára wọn jà, bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n á máa bá àwọn èèyàn Ọlọ́run jà.

      2 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Dáníẹ́lì 11:40–12:1. A máa sọ ẹni tó jẹ́ ọba àríwá lónìí, àá sì jíròrò ìdí tó fi yẹ kí ọkàn wa balẹ̀ ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa dá wa nídè láìka ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ sí.

      ỌBA ÀRÍWÁ TUNTUN

      3-4. Ta ni ọba àríwá lónìí? Ṣàlàyé.

      3 Lẹ́yìn tí ìjọba Soviet Union wá sópin tó sì pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ lọ́dún 1991, àwọn èèyàn Ọlọ́run tó wà ní ilẹ̀ yẹn rí ‘ìrànlọ́wọ́ díẹ̀’ gbà ní ti pé wọ́n lómìnira. (Dán. 11:34) Èyí mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti wàásù fàlàlà, ká tó ṣẹ́jú pẹ́ àwọn akéde tó wà lábẹ́ ilẹ̀ Soviet Union àtijọ́ ti tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ di ọba àríwá. Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ká tó lè sọ pé ẹnì kan ni ọba àríwá tàbí ọba gúúsù, ó gbọ́dọ̀ ṣe àwọn nǹkan mẹ́ta yìí: (1) ó máa ṣàkóso àwọn èèyàn Ọlọ́run tàbí kó ṣenúnibíni sí wọn, (2) ó máa ṣe ohun tó fi hàn pé ó kórìíra Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀ àti (3) ó máa bá ọba kejì jà.

      4 Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ìdí tá a fi gbà pé orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ ni ọba àríwá. (1) Wọ́n ń fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa, wọ́n sì ń ṣenúnibíni sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà lábẹ́ àkóso wọn. (2) Ohun tí wọ́n ń ṣe fi hàn pé wọ́n kórìíra Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀. (3) Wọ́n ń bá Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà tó jẹ́ ọba gúúsù jà. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo ohun tí orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ ṣe tó fi hàn pé àwọn ni ọba àríwá lóòótọ́.

      ỌBA ÀRÍWÁ ÀTI ỌBA GÚÚSÙ Á MÁA KỌ LU ARA WỌN

      5. Àsìkò wo ni Dáníẹ́lì 11:​40-43 sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, kí ló sì ṣẹlẹ̀ lásìkò yẹn?

      5 Ka Dáníẹ́lì 11:​40-43. Apá yìí nínú àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì sọ̀rọ̀ nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Ó jẹ́ ká mọ bí ọba àríwá àti ọba gúúsù ṣe máa bára wọn jà. Bí Dáníẹ́lì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, ọba gúúsù ‘máa kọ lu’ ọba àríwá tàbí kó “fi ìwo kàn án.”​—Dán. 11:40; àlàyé ìsàlẹ̀.

      6. Kí ló fi hàn pé àwọn ọba méjèèjì náà ti ń kọ lu ara wọn?

      6 Ọba àríwá àti ọba gúúsù ṣì ń bára wọn jà kí wọ́n lè mọ ìjọba tó lágbára jù láyé. Bí àpẹẹrẹ wo ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, ìjọba Soviet Union àtàwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso èyí tó pọ̀ jù lára ilẹ̀ Yúróòpù. Ohun tó ṣe náà mú kí ọba gúúsù dá ẹgbẹ́ apawọ́pọ̀jagun tó lágbára sílẹ̀, ìyẹn àjọ NATO. Ohun míì ni pé ọba àríwá àti ọba gúúsù ń ná òbítíbitì owó kí wọ́n lè kó ohun ìjà jọ kí wọ́n sì ní ẹgbẹ́ ológún tó lágbára jù lọ. Ọba àríwá bá ọ̀tá rẹ̀ yìí jà nínú àwọn ogun tí tọ̀tún tòsì wọn ti pọ̀n sẹ́yìn àwọn orílẹ̀-èdè ní Áfíríkà, Éṣíà àti Látìn Amẹ́ríkà. Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ńṣe ni orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ túbọ̀ ń lo agbára wọn lọ́pọ̀ ibi láyé. Bákan náà, wọ́n ń fi àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé fimú fínlẹ̀ kí wọ́n lè jí ìsọfúnni ara wọn. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ọba yìí ń fi kọ̀ǹpútà gbéjà ko ara wọn kí wọ́n lè ba ètò ìṣòwò àti ìṣèlú ara wọn jẹ́. Láfikún sí èyí, Dáníẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé ọba àríwá ò ní ṣíwọ́ àtimáa gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run, ohun tó sì ń ṣe nìyẹn.​—Dán. 11:41.

      ỌBA ÀRÍWÁ WỌ “ILẸ̀ ÌṢELỌ́ṢỌ̀Ọ́”

      7. Kí ni “ilẹ̀ Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́”?

      7 Dáníẹ́lì 11:41 sọ pé ọba àríwá máa wọ “ilẹ̀ Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́.” Ilẹ̀ wo nibí yìí ń sọ? Lásìkò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ilẹ̀ Ísírẹ́lì ni “ibi tó rẹwà jù ní gbogbo ilẹ̀.” (Ìsík. 20:6) Àmọ́ ohun tó jẹ́ kí ilẹ̀ náà ṣàrà ọ̀tọ̀ ni pé ibẹ̀ ni àwọn èèyàn ti máa ń ṣe ìjọsìn tòótọ́. Látìgbà Pẹ́ńtíkọ́sì 33 Sànmánì Kristẹni, “ilẹ̀ Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́” náà kì í ṣe orílẹ̀-èdè kan pàtó. Ìyẹn sì bọ́gbọ́n mu torí pé ibi gbogbo láyé làwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà wà. Lónìí, “ilẹ̀ Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́” náà ni Párádísè tẹ̀mí táwọn èèyàn Ọlọ́run wà. Lára ohun tí wọ́n máa ń ṣe nínú Párádísè tẹ̀mí yìí ni pé wọ́n ń jọ́sìn Jèhófà láwọn ìpàdé wọn, wọ́n sì ń wàásù nípa Jèhófà fáwọn èèyàn.

      8. Báwo ni ọba àríwá ṣe wọ “ilẹ̀ Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́”?

      8 Láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, ọ̀pọ̀ ìgbà ni ọba àríwá ti wọ “ilẹ̀ Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́.” Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ìjọba Násì lórílẹ̀-èdè Jámánì jẹ́ ọba àríwá, pàápàá nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, ọba yìí wọ “ilẹ̀ Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́” ní ti pé ó ṣenúnibíni sáwọn èèyàn Ọlọ́run, ó sì pa ọ̀pọ̀ lára wọn. Bákan náà, lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì nígbà tí ìjọba Soviet Union di ọba àríwá, ọba náà wọ “ilẹ̀ Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́” ní ti pé òun náà ṣenúnibíni sáwọn èèyàn Ọlọ́run, ó sì kó ọ̀pọ̀ lára wọn lọ sí ìgbèkùn.

      9. Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, báwo ni orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ ṣe wọ “ilẹ̀ Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́”?

      9 Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ ti wọ “ilẹ̀ Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́.” Kí ló fi hàn bẹ́ẹ̀? Lọ́dún 2017, ọba àríwá tuntun yìí fòfin de iṣẹ́ àwọn èèyàn Jèhófà, ó sì ju àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa kan sẹ́wọ̀n. Ó tún fòfin de àwọn ìtẹ̀jáde wa títí kan Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Ohun míì tó tún ṣe ni pé, ó gbẹ́sẹ̀ lé ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà títí kan àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àtàwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ wa. Pẹ̀lú àwọn nǹkan tó ṣe yìí, lọ́dún 2018 Ìgbìmọ̀ Olùdarí jẹ́ kó ṣe kedere pé orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ ni ọba àríwá. Àmọ́ láìka gbogbo bó ṣe ń fojú pọ́n àwọn èèyàn Jèhófà tó sì ń ṣenúnibíni sí wọn, àwọn èèyàn Jèhófà kò bá ìjọba jà, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn ò wá bí wọ́n ṣe máa dojú ìjọba dé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Bíbélì sọ ni wọ́n ń ṣe pé kí wọ́n máa gbàdúrà fún “gbogbo àwọn tó wà ní ipò gíga,” ní pàtàkì táwọn ìjọba bá fẹ́ pinnu bóyá kí wọ́n fún wa lómìnira láti jọ́sìn.​—1 Tím. 2:​1, 2.

      ṢÉ ỌBA ÀRÍWÁ MÁA ṢẸ́GUN ỌBA GÚÚSÙ?

      10. Ṣé ọba àríwá máa ṣẹ́gun ọba gúúsù? Ṣàlàyé.

      10 Ohun tí ọba àríwá máa ṣe ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Dáníẹ́lì 11:​40-45 dìídì sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé ọba àríwá máa borí ọba gúúsù ni? Rárá o. Ọba gúúsù ṣì máa wà “láàyè” nígbà tí Jèhófà àti Jésù máa pa gbogbo ìjọba ayé yìí run nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì. (Ìfi. 19:20) Kí ló mú kíyẹn dá wa lójú? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì àti Ìfihàn sọ.

      Òkúta kan ń já ṣòòròṣò bọ̀ látara òkè kan, ó sì kọlu àtẹ́lẹsẹ̀ ère gìrìwò kan tó jẹ́ ti wúrà, fàdákà, bàbà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

      Nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, Ìjọba Ọlọ́run tí Bíbélì fi wé òkúta máa run ìjọba èèyàn tí Bíbélì fi wé ère gìrìwò (Wo àpilẹ̀kọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ 20, ìpínrọ̀ 11)

      11. Kí lohun tó wà nínú Dáníẹ́lì 2:​43-45 jẹ́ ká mọ̀? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)

      11 Ka Dáníẹ́lì 2:​43-45. Wòlíì Dáníẹ́lì sọ̀rọ̀ nípa onírúurú ìjọba tó mú kí nǹkan nira fáwọn èèyàn Ọlọ́run. Ó fi ère gìrìwò kan tó jẹ́ ti wúrà, fàdákà, bàbà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ṣàpèjúwe àwọn ìjọba náà. Ó fi èyí tó gbẹ̀yìn nínú àwọn ìjọba náà wé àtẹ́lẹsẹ̀ ère náà, èyí tó jẹ́ apá kan irin àti apá kan amọ̀. Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ni àtẹ́lẹsẹ̀ ère náà. Àsọtẹ́lẹ̀ yìí jẹ́ ká rí i pé Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà á ṣì máa ṣàkóso nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run máa kọ lu gbogbo ìjọba ayé yìí tó sì máa pa wọ́n run.

      12. Kí ni ìkeje lára orí ẹranko náà ṣàpẹẹrẹ, kí sì nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu?

      12 Àpọ́sítélì Jòhánù náà sọ̀rọ̀ nípa onírúurú ìjọba tó mú kí nǹkan nira fáwọn èèyàn Ọlọ́run. Jòhánù fi àwọn ìjọba yìí wé ẹranko kan tó ní orí méje. Ìkeje lára orí ẹranko náà ṣàpẹẹrẹ Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà. Èyí bọ́gbọ́n mu torí pé ẹranko náà kò ní ju orí méje lọ. Torí náà, ìkeje lára orí ẹranko náà á ṣì máa ṣàkóso nígbà tí Kristi àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ máa pa ẹranko náà run ráúráú.b​—Ìfi. 13:​1, 2; 17:​13, 14.

      KÍ NI ỌBA ÀRÍWÁ MÁA ṢE LÁÌPẸ́?

      13-14. Ta ni “Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù,” kí ló sì máa mú kó gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run?

      13 Wòlíì Ìsíkíẹ́lì sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀ nígbà tó bá kù díẹ̀ kí ọba àríwá àti ọba gúúsù pa run. Ó jọ pé ìṣẹ̀lẹ̀ kan náà ni Ìsíkíẹ́lì 38:​10-23; Dáníẹ́lì 2:​43-45; 11:44–12:1 àti Ìfihàn 16:​13-16, 21 ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn nǹkan tá a máa jíròrò tẹ̀ lé e yìí ló ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀.

      14 Lásìkò díẹ̀ lẹ́yìn tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀, “àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé” máa kóra jọ, wọ́n á sì fìmọ̀ ṣọ̀kan láti ṣe ohun kan. (Ìfi. 16:​13, 14; 19:19) Ìkórajọ àwọn orílẹ̀-èdè yẹn ni Bíbélì pè ní “Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù.” (Ìsík. 38:2) Wọ́n máa fi gbogbo agbára wọn gbéjà ko àwa èèyàn Ọlọ́run láti pa wá rẹ́ ráúráú. Kí ló máa mú kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀? Nígbà tí Jòhánù ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lásìkò yẹn, ó sọ pé àwọn òkúta yìnyín ńlá máa já bọ́ lu àwọn ọ̀tá Ọlọ́run. Ó ṣeé ṣe kí òkúta yìnyín ìṣàpẹẹrẹ yìí dúró fún àwọn gbankọgbì ọ̀rọ̀ ìdájọ́ táwa èèyàn Jèhófà máa kéde. Ìkéde yìí lè múnú bí Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù, kíyẹn sì mú kó gbéjà ko àwa èèyàn Ọlọ́run pẹ̀lú èrò àtipa wá run pátápátá.​—Ìfi. 16:21.

      15-16. (a) Ìṣẹ̀lẹ̀ wo ló ṣeé ṣe kí Dáníẹ́lì 11:​44, 45 máa tọ́ka sí? (b) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí ọba àríwá àti ìyókù Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù?

      15 Ó jọ pé àwọn gbankọgbì ọ̀rọ̀ ìdájọ́ táwa èèyàn Jèhófà máa kéde àti báwọn ọ̀tá ṣe máa gbéjà ko àwa èèyàn Ọlọ́run ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Dáníẹ́lì 11:​44, 45 ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. (Kà á.) Nínú àsọtẹ́lẹ̀ yìí, Dáníẹ́lì sọ pé “ìròyìn láti ìlà oòrùn àti àríwá” máa yọ ọba àríwá lẹ́nu, ìyẹn sì máa mú kó lọ pẹ̀lú “ìbínú tó le gan-an.” Ohun tó wà lọ́kàn ọba àríwá ni bó ṣe máa “pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ run.” Ó ṣeé ṣe kí “ọ̀pọ̀lọpọ̀” yìí tọ́ka sí àwa èèyàn Jèhófà.c Torí náà, ó jọ pé ohun tí Dáníẹ́lì ń sọ ni bí àwọn ọ̀tá ṣe máa fi gbogbo agbára wọn gbéjà ko àwa èèyàn Ọlọ́run láti pa wá rẹ́ ráúráú.

      16 Nígbà tí ọba àríwá àtàwọn ìjọba ayé yòókù bá gbéjà ko àwa èèyàn Ọlọ́run, inú máa bí Ọlọ́run Olódùmarè, ìyẹn ló sì máa yọrí sí ogun Amágẹ́dọ́nì. (Ìfi. 16:​14, 16) Lásìkò yẹn, Jèhófà máa pa ọba àríwá run, kò sì “sẹ́ni tó máa ràn án lọ́wọ́.” Ohun kan náà ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn ìjọba tó para pọ̀ jẹ́ Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù.​—Dán. 11:45.

      Jésù tó wà lórí ẹṣin funfun kan fẹ́ ta ọfà. Àwọn áńgẹ́lì gun ẹṣin funfun tẹ̀ lé e, wọ́n sì mú idà lọ́wọ́.

      Nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, Jésù Kristi àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ máa pa ayé èṣù yìí run, á sì dá àwa èèyàn Ọlọ́run nídè (Wo ìpínrọ̀ 17)

      17. Ta ni Máíkẹ́lì “ọmọ aládé ńlá” tí Dáníẹ́lì 12:1 sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, kí sì lohun tó ṣe?

      17 Ẹsẹ tó tẹ̀ lé e nínú àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ bí ọba àríwá àtàwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ ṣe máa pa run àti bí Jèhófà ṣe máa dá àwa èèyàn rẹ̀ nídè. (Ka Dáníẹ́lì 12:1.) Kí ni ẹsẹ yìí túmọ̀ sí? Máíkẹ́lì ni orúkọ míì tí Jésù Kristi Ọba wa ń jẹ́. Àtọdún 1914 tí Ọlọ́run ti fìdí Ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ lọ́run ni Máíkẹ́lì ti ń “dúró nítorí” àwa èèyàn Jèhófà. Láìpẹ́, ó “máa dìde” tàbí lédè míì á gbèjà àwa èèyàn Jèhófà, á sì pa àwọn ọ̀tá run nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì. Ogun yẹn ló máa kẹ́yìn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Dáníẹ́lì sọ pé ó máa wáyé ní “àkókò wàhálà” tó burú jù nínú ìtàn ẹ̀dá. Bákan náà, àsọtẹ́lẹ̀ Jòhánù tó wà nínú ìwé Ìfihàn pe àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ṣáájú ogun Amágẹ́dọ́nì ní “ìpọ́njú ńlá.”​—Ìfi. 6:2; 7:14.

      ṢÉ O MÁA WÀ LÁRA ÀWỌN “TÍ ORÚKỌ WỌN WÀ NÍNÚ ÌWÉ”?

      18. Kí nìdí tá ò fi bẹ̀rù ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?

      18 Ọkàn wa balẹ̀, a ò sì bẹ̀rù ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú torí pé àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì àti ti Jòhánù jẹ́ kó dá wa lójú pé àwọn tó bá sin Jèhófà àti Jésù máa là á já nígbà ìpọ́njú ńlá. Dáníẹ́lì sọ pé orúkọ àwọn tó máa là á já máa “wà nínú ìwé.” (Dán. 12:1) Kí la lè ṣe kí orúkọ wa lè wà nínú ìwé náà? A gbọ́dọ̀ fi hàn láìsí tàbí ṣùgbọ́n pé a nígbàgbọ́ nínú Jésù tó jẹ́ Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run. (Jòh. 1:29) A gbọ́dọ̀ ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà ká sì ṣèrìbọmi. (1 Pét. 3:21) Bákan náà, ó ṣe pàtàkì ká máa kọ́ àwọn míì nípa Jèhófà ká lè fi hàn pé à ń ti Ìjọba rẹ̀ lẹ́yìn.

      19. Kí ló yẹ ká ṣe nísinsìnyí, kí sì nìdí?

      19 Ìsinsìnyí ló yẹ ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ká sì fọkàn tán ètò rẹ̀ pátápátá. Ìsinsìnyí ló yẹ ká ti Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá là á já nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá pa ọba àríwá àti ọba gúúsù run.

      KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

      • Ta ni “ọba àríwá” lónìí?

      • Báwo ni ọba àríwá ṣe wọ “ilẹ̀ Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́”?

      • Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí ọba àríwá àti ọba gúúsù?

      ORIN 149 Orin Ìṣẹ́gun

      a Ta ni “ọba àríwá” lónìí, báwo ló sì ṣe máa pa run? Tá a bá mọ ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí, ìgbàgbọ́ wa máa túbọ̀ lágbára, èyí á sì jẹ́ ká múra sílẹ̀ de àwọn àdánwò tá a máa tó kojú.

      b Tó o bá fẹ́ àlàyé sí i lórí Dáníẹ́lì 2:​36-45 àti Ìfihàn 13:​1, 2, wo Ilé Ìṣọ́ June 15, 2012, ojú ìwé 7 sí 19.

      c Tó o bá fẹ́ àlàyé sí i, wo Ilé Ìṣọ́ May 15, 2015, ojú ìwé 29 sí 30.

  • Àwọn Ọba Tó Ń Bára Wọn Jà Lákòókò Òpin Yìí
    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020 | May
    • Àwọn Ọba Tó Ń Bára Wọn Jà Lákòókò Òpin Yìí

      Àwọn kan lára àsọtẹ́lẹ̀ tá a tọ́ka sí nínú àtẹ yìí ní ìmúṣẹ lásìkò kan náà. Gbogbo wọn ló jẹ́rìí sí i pé “àkókò òpin” là ń gbé yìí.​—Dán. 12:4.

      Àtẹ yìí jẹ́ ká mọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ọba àríwá àti ọba gúúsù, ó sì jẹ́ ká mọ ọba méjèèjì náà látọdún 1870 títí di báyìí.
      • Àkọ́kọ́ nínú àtẹ mẹ́rin yìí jẹ́ ká mọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣẹ lásìkò kan náà láwọn ọjọ́ ìkẹyìn, ìyẹn láti nǹkan bí ọdún 1870 sí 1918. Ó jẹ́ ká mọ̀ pé ọjọ́ ìkẹyìn bẹ̀rẹ̀ látọdún 1914. Àsọtẹ́lẹ̀ 1: Ẹranko olórí méje ti bẹ̀rẹ̀ sí i ṣàkóso tipẹ́tipẹ́ ṣááju ọdún 1870 tí àtẹ yìí bẹ̀rẹ̀. Nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, wọ́n dá ọgbẹ́ sí ìkeje lára orí ẹranko náà. Láti 1917 lọ ọgbẹ́ náà jinná, ara ẹranko náà sì yá. Àsọtẹ́lẹ̀ 2: A mọ ẹni tí ọba àríwá jẹ́ lọ́dún 1871, a sì mọ ẹni tí ọba gúúsù jẹ́ lọ́dún 1870. Jámánì di ọba àríwá lọ́dún 1871. Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni ọba gúúsù níbẹ̀rẹ̀, àmọ́ nígbà tí Amẹ́ríkà dara pọ̀ mọ́ ọn lọ́dún 1917, ó di Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà. Àsọtẹ́lẹ̀ 3: Bẹ̀rẹ̀ látọdún 1870 Russell àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ la mọ̀ sí ‘ìránṣẹ́’ náà. Bẹ̀rẹ̀ látọdún 1881, ìwé ìròyìn Zion’s Watch Tower rọ àwọn tó ń ka ìwé ìròyìn náà pé kí wọ́n máa wàásù ìhìn rere. Àsọtẹ́lẹ̀ 4: Láti 1914 lọ ìkórè bẹ̀rẹ̀. Wọ́n ya èpò kúrò lára àlìkámà. Àsọtẹ́lẹ̀ 5: Láti 1917 lọ, àtẹ́lẹsẹ̀ tó jẹ́ irin àti amọ̀ fara hàn. Àwọn nǹkan mí ì tó fara hàn: Àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ láyé látọdún 1914 sí 1918, wọ́n ja Ogun Àgbáyé I. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó kan àwọn èèyàn Jèhófà: Látọdún 1914 sí 1918, wọ́n fi àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó wà ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Jámánì sẹ́wọ̀n. Lọ́dún 1918, wọ́n fi àwọn tó ń múpò iwájú ní oríléeṣẹ́ wa tó wà ní Amẹ́ríkà sẹ́wọ̀n.
        Àsọtẹ́lẹ̀ 1.

        Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Ìfi. 11:7; 12:13, 17; 13:1-8, 12

        Àsọtẹ́lẹ̀ Ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ọdún ni “ẹranko” náà fi ṣàkóso àwọn èèyàn. Ní àkókò òpin, wọ́n dá ọgbẹ́ sí ìkeje lára orí ẹranko náà. Nígbà tó yá, ọgbẹ́ náà jinná “gbogbo ayé” sì tẹ̀ lé ẹranko náà. Sátánì wá lo ẹranko náà láti “bá àwọn tó ṣẹ́ kù” lára ẹni àmì òróró jagun.

        Ìmúṣẹ Lẹ́yìn Ìkún Omi, àwọn ìjọba tó jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso àwọn èèyàn. Ní ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́ta (3,000) lẹ́yìn náà, Ilẹ̀ Ọba Gẹ̀ẹ́sì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìjọba yẹn fara pa gan-an nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní. Ó kọ́fẹ pa dà nígbà tí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tì í lẹ́yìn. Pàápàá jù lọ ní àkókò òpin yìí, Sátánì ń lo àwọn ìjọba ayé láti ṣenúnibíni sáwọn èèyàn Ọlọ́run.

      • Àsọtẹ́lẹ̀ 2.

        Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Dán. 11:25-45

        Àsọtẹ́lẹ̀ Ọba àríwá àti ọba gúúsù máa bára wọn jà lákòókò òpin.

        Ìmúṣẹ Ilẹ̀ Jámánì bá ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà jagun. Lọ́dún 1945, Soviet Union àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ di ọba àríwá. Lọ́dún 1991, ìjọba Soviet Union wá sópin ó sì pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ. Nígbà tó yá Rọ́ṣíà àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ di ọba àríwá.

      • Àsọtẹ́lẹ̀ 3.

        Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Àìsá. 61:1; Mál. 3:1; Lúùkù 4:18

        Àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà máa rán “ìránṣẹ́” rẹ̀ láti “tún ọ̀nà ṣe” kí Ìjọba Mèsáyà tó fìdí múlẹ̀. Ìránṣẹ́ yìí máa “kéde ìhìn rere fún àwọn oníwà pẹ̀lẹ́.”

        Ìmúṣẹ Bẹ̀rẹ̀ látọdún 1870, Arákùnrin C. T. Russell àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ṣèwádìí jinlẹ̀ nínú Bíbélì kí wọ́n lè ṣàlàyé ohun tí Bíbélì fi kọ́ni gan-an. Lọ́dún 1881, wọ́n rí i pé ó ṣe pàtàkì káwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa wàásù. Torí náà, wọ́n gbé àwọn àpilẹ̀kọ bí “À Ń Wá Ẹgbẹ̀rún Oníwàásù” àti “A Fòróró Yàn Wọ́n Láti Wàásù” jáde.

      • Àsọtẹ́lẹ̀ 4.

        Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Mát. 13:24-30, 36-43

        Àsọtẹ́lẹ̀ Ọ̀tá kan máa gbin èpò sí àárín àlìkámà, wọ́n máa jẹ́ kí àwọn méjèèjì jọ dàgbà débi pé èpò máa bo àlìkámà mọ́lẹ̀, wọ́n á sì wà bẹ́ẹ̀ títí dìgbà ìkórè. Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n á ya èpò sọ́tọ̀ kúrò lára àlìkámà.

        Ìmúṣẹ Àtọdún 1870 ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn Kristẹni tòótọ́ àtàwọn èké Kristẹni ti túbọ̀ ṣe kedere. Lákòókò òpin yìí, Jèhófà ti kó àwọn Kristẹni tòótọ́ jọ sínú ìjọ rẹ̀, ó sì ti yà wọ́n sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn èké Kristẹni.

      • Àsọtẹ́lẹ̀ 5.

        Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Dán. 2:31-33, 41-43

        Àsọtẹ́lẹ̀ Ère gìrìwò kan tó jẹ́ ti wúrà, fàdákà, bàbà àti irin ní àtẹ́lẹsẹ̀ irin àti amọ̀.

        Ìmúṣẹ Amọ̀ náà ṣàpẹẹrẹ àwọn gbáàtúù tó wà lábẹ́ àkóso Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà. Àwọn èèyàn yìí ń ta ko ìjọba, ìyẹn sì mú kó ṣòro fún ìjọba láti lo agbára wọn tó dà bí irin.

      • Èkejì nínú àtẹ mẹ́rin yìí jẹ́ ká mọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣẹ lásìkò kan náà láwọn ọjọ́ ìkẹyìn, ìyẹn láti nǹkan bí ọdún 1919 sí 1945. Jámánì ni ọba àríwá títí di ọdún 1945 nígbà tí Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà sì jẹ́ ọba gúúsù. Àsọtẹ́lẹ̀ 6: Lọ́dún 1919, wọ́n kó àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró jọ sínú ìjọ tá a mú pa dà bọ̀ sípò. Látọdún 1919 lọ, wọ́n túbọ̀ ń fìtara ṣe iṣẹ́ ìwàásù, wọn ò sì dáwọ́ dúró. Àsọtẹ́lẹ̀ 7: Lọ́dún 1920, wọ́n dá Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀, ó sì wà títí dìgbà Ogun Àgbáyé II. Àwọn nǹkan mí ì tó fara hàn: Àsọtẹ́lẹ̀ 1, ìṣàkóso ẹranko olórí méje náà ń bá a lọ. Àsọtẹ́lẹ̀ 5, àtẹ́lẹsẹ̀ tó jẹ́ irin àti amọ̀ ṣì wà nípò. Àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ láyé látọdún 1939 sí 1945, wọ́n ja Ogun Àgbáyé II. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó kan àwọn èèyàn Jèhófà: Látọdún 1933 sí 1945, wọ́n ju àwọn Ẹlẹ́rìí tó lé ní 11,000 sẹ́wọ̀n lórílẹ̀-èdè Jámánì. Látọdún 1939 sí 1945, wọ́n ju àwọn Ẹlẹ́rìí tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 1,600 sẹ́wọ̀n nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Látọdún 1940 sí 1944, àwọn jàǹdùkú gbéjà ko àwọn Ẹlẹ́rìí níye ìgbà tó ju 2,500 lọ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.
        Àsọtẹ́lẹ̀ 6.

        Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Mát. 13:30; 24:14, 45; 28:19, 20

        Àsọtẹ́lẹ̀ Wọ́n máa kó “àlìkámà” jọ sínú “ilé ìkẹ́rùsí,” Jésù máa yan “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” pé kó máa bójú tó àwọn “ará ilé” rẹ̀. Wọ́n sì máa wàásù “ìhìn rere Ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé.”

        Ìmúṣẹ Lọ́dún 1919, Jésù yan ẹrú olóòótọ́ pé kó máa bójú tó àwọn èèyàn Ọlọ́run. Àtìgbà yẹn làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù. Lónìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù ní ilẹ̀ tó ju ọgọ́rùn-ún méjì (200) lọ, a sì ń tẹ àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì jáde ní èdè tó ju ẹgbẹ̀rún kan (1,000) lọ.

      • Àsọtẹ́lẹ̀ 7.

        Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Dán. 12:11; Ìfi. 13:11, 14, 15

        Àsọtẹ́lẹ̀ Ẹranko kan tó “ní ìwo méjì” máa sọ fún àwọn tó ń gbé ayé pé kí wọ́n ṣe “ère ẹranko” kan, á sì fún ère “ẹranko náà ní èémí.”

        Ìmúṣẹ Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ló dá Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀, àwọn orílẹ̀-èdè míì sì dara pọ̀ mọ́ Ìmùlẹ̀ yìí. Nígbà tó yá, ọba àríwá náà dara pọ̀ mọ́ ọn, ìyẹn láti ọdún 1926 sí 1933. Ṣe làwọn èèyàn ń gbógo tó yẹ Ìjọba Ọlọ́run fún Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, ohun kan náà ni wọ́n sì ṣe fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tí wọ́n dá sílẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀.

      • Ẹ̀kẹta nínú àtẹ mẹ́rin yìí jẹ́ ká mọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣẹ lásìkò kan náà láwọn ọjọ́ ìkẹyìn, ìyẹn láti ọdún 1945 sí 1991. Soviet Union àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ ni ọba àríwá títí di ọdún 1991, nígbà tó yá Rọ́ṣíà àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ di ọba àríwá. Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ṣì ni ọba gúúsù. Àsọtẹ́lẹ̀ 8: Eruku bọ́ǹbù jẹ́ ká rí ọṣẹ́ tí Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ṣe. Àsọtẹ́lẹ̀ 9: Wọ́n dá Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀ lọ́dún 1945, ó sì rọ́pò Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Àwọn nǹkan mí ì tó fara hàn: Àsọtẹ́lẹ̀ 1, ìṣàkóso ẹranko olórí méje náà ń bá a lọ. Àsọtẹ́lẹ̀ 5, àtẹ́lẹsẹ̀ tó jẹ́ irin àti amọ̀ ṣì wà nípò. Àsọtẹ́lẹ̀ 6, lọ́dún 1945 àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run ju 156,000 lọ. Lọ́dún 1991, àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run ju 4,278,000 lọ. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó kan àwọn èèyàn Jèhófà: Látọdún 1945 sí 1951, ìjọba Soviet Union kó ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí lọ sígbèkùn ní Siberia.
        Àsọtẹ́lẹ̀ 8.

        Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Dán. 8:23, 24

        Àsọtẹ́lẹ̀ Ọba kan tí ojú rẹ̀ le máa “mú ìparun wá lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀.”

        Ìmúṣẹ Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ti pa àìlóǹkà èèyàn, ó sì ti pa ọ̀pọ̀ ilẹ̀ run. Bí àpẹẹrẹ nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fa ìparun tí kò láfiwé nígbà tó ju bọ́ǹbù méjì sí ilẹ̀ àwọn tó jẹ́ ọ̀tá òun àti ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

      • Àsọtẹ́lẹ̀ 9.

        Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Dán. 11:31; Ìfi. 17:3, 7-11

        Àsọtẹ́lẹ̀ Ẹranko “aláwọ̀ rírẹ̀dòdò” kan tó ní ìwo mẹ́wàá máa jáde látinú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, òun sì ni ọba kẹjọ. Ìwé Dáníẹ́lì pe ọba yìí ní “ohun ìríra tó ń fa ìsọdahoro.”

        Ìmúṣẹ Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè kò lágbára mọ́. Lẹ́yìn tí ogun náà parí, ‘wọ́n gbé’ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè kalẹ̀. Ṣe làwọn èèyàn ń gbógo tó yẹ Ìjọba Ọlọ́run fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè bíi ti Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tó wà ṣáájú rẹ̀. Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè máa gbéjà ko ẹ̀sìn.

      • Ẹ̀kẹrin nínú àtẹ mẹ́rin yìí jẹ́ ká mọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣẹ lásìkò kan náà láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí títí dìgbà ogun Amágẹ́dọ́nì. Rọ́ṣíà àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ ni ọba àríwá. Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ṣì ni ọba gúúsù. Àsọtẹ́lẹ̀ 10: Àwọn alákòóso kéde ‘àlàáfíà àti ààbò.’ Lẹ́yìn náà, ìpọ́njú ńlá bẹ̀rẹ̀ . Àsọtẹ́lẹ̀ 11: Àwọn orílẹ̀-èdè pa gbogbo ẹ̀sìn èké run. Àsọtẹ́lẹ̀ 12: Àwọn ìjọba gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run. Jèhófà kó àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ẹni àmì òróró lọ sọ́run. Àsọtẹ́lẹ̀ 13: Amágẹ́dọ́nì. Ẹni tó jókòó sórí ẹṣin funfun parí ìṣẹ́gun rẹ̀. Jèhófà pa ẹranko olórí méje náà run; òkúta kan kọ lu àtẹ́lẹsẹ̀ irin àti àmọ́ ère gìrìwò náà, ó sì rún eré náà wómúwómú. Àwọn nǹkan mí ì tó fara hàn: Àsọtẹ́lẹ̀ 1, ìṣàkóso ẹranko olórí méje náà ń bá a lọ títí dìgbà ogun Amágẹ́dọ́nì. Àsọtẹ́lẹ̀ 5, àtẹ́lẹsẹ̀ tó jẹ́ irin àti amọ̀ ṣì wà nípò títí dìgbà ogun Amágẹ́dọ́nì. Àsọtẹ́lẹ̀ 6, lónìí àwọn akéde ju 8,580,000 lọ. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó kan àwọn èèyàn Jèhófà: Lọ́dún 2017, àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Rọ́ṣíà ju àwọn Ẹlẹ́rìí sẹ́wọ̀n, wọ́n sì gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ilé ètò Ọlọ́run.
        Àsọtẹ́lẹ̀ 10 àti 11.

        Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ 1 Tẹs. 5:3; Ìfi. 17:16

        Àsọtẹ́lẹ̀ Àwọn orílẹ̀-èdè máa kéde “àlàáfíà àti ààbò,” bẹ́ẹ̀ sì ni “ìwo mẹ́wàá” àti “ẹranko náà” máa gbéjà ko “aṣẹ́wó náà,” wọ́n sì máa pa á run. Lẹ́yìn ìyẹn, Jèhófà máa pa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè run yán-án-yán.

        Ìmúṣẹ Àwọn orílẹ̀-èdè máa sọ pé àwọn ti jẹ́ kí àlàáfíà àti ààbò wà láyé. Lẹ́yìn náà, àwọn orílẹ̀-èdè tó ń ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè lẹ́yìn máa pa gbogbo ẹ̀sìn èké run. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló máa bẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú ńlá. Ìpọ́njú ńlá yìí máa dópin nígbà tí Jésù bá pa èyí tó ṣẹ́ kù lára ayé Sátánì run nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì.

      • Àsọtẹ́lẹ̀ 12.

        Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Ìsík. 38:​11, 14-17; Mát. 24:31

        Àsọtẹ́lẹ̀ Gọ́ọ̀gù máa wọ ilẹ̀ àwọn èèyàn Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà, àwọn áńgẹ́lì máa kó “àwọn àyànfẹ́” jọ.

        Ìmúṣẹ Ọba àríwá àtàwọn ìjọba ayé yòókù máa gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run. Ní àkókò díẹ̀ lẹ́yìn tí ìgbéjàkò yẹn bá bẹ̀rẹ̀, Jèhófà máa kó àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ẹni àmì òróró lọ sọ́run.

      • Àsọtẹ́lẹ̀ 13.

        Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Ìsík. 38:18-23; Dán. 2:34, 35, 44, 45; Ìfi. 6:2; 16:14, 16; 17:14; 19:20

        Àsọtẹ́lẹ̀ ‘Ẹni tó jókòó sórí ẹṣin funfun’ máa “parí ìṣẹ́gun rẹ̀” nígbà tó bá pa Gọ́ọ̀gù àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ run. Wọ́n máa ju “ẹranko náà” sínú “adágún iná tó ń jó,” òkúta kan sì máa rún ère gìrìwò náà wómúwómú.

        Ìmúṣẹ Jésù tó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run máa wá gba àwọn èèyàn Ọlọ́run sílẹ̀. Òun àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tí wọ́n á jọ ṣàkóso pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun ọ̀run máa pa gbogbo orílẹ̀-èdè tó gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run run, ìyẹn ló sì máa fòpin sí ìṣàkóso Sátánì.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́