ORIN 123
Máa Ṣègbọràn sí Ètò Ọlọ́run
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Báwa èèyàn Jáà ṣe ń kéde òtítọ́ - Nípa Ìjọba náà káàkiri ayé, - Ó yẹ ká ṣègbọràn sétò Ọlọ́run. - Ká wà ní ìṣọ̀kan, ká jẹ́ olóòótọ́. - (ÈGBÈ) - Tá a bá ń ṣègbọràn sétò Ọlọ́run, - Jèhófà máa láyọ̀. - Yóò dáàbò bò wá, yóò sì pa wá mọ́ - Bá a ṣe ń jẹ́ olóòótọ́ sí i. 
- 2. Ẹ̀mí mímọ́ àti ẹrú olóòótọ́; - Wọn yóò máa tọ́ wa sọ́nà ìyè tòótọ́. - Torí náà ká wá ojúure Ọlọ́run; - Ká dúró ṣinṣin, ká kéde rẹ̀ fáyé. - (ÈGBÈ) - Tá a bá ń ṣègbọràn sétò Ọlọ́run, - Jèhófà máa láyọ̀. - Yóò dáàbò bò wá, yóò sì pa wá mọ́ - Bá a ṣe ń jẹ́ olóòótọ́ sí i. 
(Tún wo Lúùkù 12:42; Héb. 13:7, 17.)