ORIN 34
Máa Rìn Nínú Ìwà Títọ́
Bíi Ti Orí Ìwé
	(Sáàmù 26)
- 1. Ṣèdájọ́ mi, wo ìwà títọ́ mi. - ’Wọ ni mo gbẹ́kẹ̀ lé, mo jólóòótọ́ sí ọ. - Jọ̀ọ́, yẹ̀ mí wò, kí o sì dán mi wò. - Tún yọ́ ọkàn mi mọ́, kí n lè gba ìbùkún. - (ÈGBÈ) - Ní tèmi o, mo ti pinnu wí pé: - Màá rìn títí ayé nínú ìwà títọ́. 
- 2. Èmi kò bá ẹni ibi jókòó. - Mo kórìíra àwọn tí kò fẹ́ òtítọ́. - Jèhófà, jọ̀ọ́, má jẹ́ kí n kú pẹ̀lú - Àwọn tí ọwọ́ wọn kún fún ìwà ibi. - (ÈGBÈ) - Ní tèmi o, mo ti pinnu wí pé: - Màá rìn títí ayé nínú ìwà títọ́. 
- 3. Ó wù mí kí ń máa gbénú ilé rẹ, - Kí n máa gbé ìjọsìn mímọ́ rẹ lárugẹ. - Èmi yóò máa rìn yí pẹpẹ rẹ ká, - Kí gbogbo èèyàn lè máa gbóhùn ọpẹ́ mi. - (ÈGBÈ) - Ní tèmi o, mo ti pinnu wí pé: - Màá rìn títí ayé nínú ìwà títọ́. 
(Tún wo Sm. 25:2.)