ORIN 130
Ẹ Máa Dárí Jini
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa; - Ó fún wa ní Ọmọ rẹ̀, - Kó lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wá, - Kó sì mú ikú kúrò. - Tí a bá ronú pìwà dà, - Yóò dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wá. - Lọ́lá ìràpadà Kristi, - Ọlọ́run yóò gbẹ́bẹ̀ wa. 
- 2. Tá a bá ńdárí jini, - Tá a fara wé Ọlọ́run, - Tá a nífẹ̀ẹ́, tá à ń gba tẹni rò, - Àwa náà máa ráàánú gbà. - Ká máa fara dà á fúnra wa, - Ká má ṣe máa bínú jù. - Ká máa bọlá fáwọn ará; - Ìyẹn ni ìfẹ́ tòótọ́. 
- 3. Àánú ṣe pàtàkì. - Ó yẹ ká jẹ́ aláàánú. - Ká má ṣe dira wa sínú, - Ká sì fẹ́ràn ara wa. - Táa bá ńfara wé Jèhófà, - Ẹni tífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ga jù, - Aó máa dárí ji ara wa - Látọkàn wá, láìṣẹ̀tàn. 
(Tún wo Mát. 6:12; Éfé. 4:32; Kól. 3:13.)