ORIN 16
Ẹ Yin Jáà Nítorí Ọmọ Rẹ̀ Tó Fòróró Yàn
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Jèhófà ti yan Ọmọ rẹ̀ - Láti ṣàkóso ayé, - Kí ìfẹ́ Rẹ̀ lè ṣẹ ní ayé; - Ọba olódodo ló jẹ́. - (ÈGBÈ) - Ẹ yin Jèhófà fún Ọmọ rẹ̀, - ẹ̀yin tó ń tẹ̀ lé àṣẹ rẹ̀; - Gbogbo olódodo, ẹ yin Jésù, - Ọba tí Ọlọ́run yàn. - Ẹ yin Jèhófà fún Ọmọ rẹ̀, - tó ń jọba nísàálú ọ̀run. - Ó ń gbórúkọ mímọ́ Ọlọ́run ga - Pẹ̀lú agbára ńlá rẹ̀. 
- 2. Àwọn arákùnrin Kristi - T’Ọ́lọ́run sọ d’àtúnbí, - Wọ́n máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù - Láti sọ ayé di tuntun. - (ÈGBÈ) - Ẹ yin Jèhófà fún Ọmọ rẹ̀, - ẹ̀yin tó ń tẹ̀ lé àṣẹ rẹ̀; - Gbogbo olódodo, ẹ yin Jésù, - Ọba tí Ọlọ́run yàn. - Ẹ yin Jèhófà fún Ọmọ rẹ̀, - tó ń jọba nísàálú ọ̀run. - Ó ń gbórúkọ mímọ́ Ọlọ́run ga - Pẹ̀lú agbára ńlá rẹ̀. 
(Tún wo Òwe 29:4; Àìsá. 66:7, 8; Jòh. 10:4; Ìfi. 5:9, 10.)