ORIN 131
‘Ohun Tí Ọlọ́run So Pọ̀’
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Jáà fìfẹ́ so wọ́n pọ̀; - Ọkàn wọn kún fáyọ̀. - Àwọn èèyàn jẹ́rìí sí i, - Bí wọ́n ṣe ń jẹ́jẹ̀ẹ́ wọn. - (ÈGBÈ 1) - Ọkọ jẹ́jẹ̀ẹ́ fáya pé: - ‘Màá fẹ́ ọ látọkàn.’ - ‘Ohun t’Ọlọ́run so pọ̀, - Kéèyàn má ṣe yà wọ́n.’ 
- 2. Wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì - Kí wọ́n lè ṣèfẹ́ Jáà. - Wọ́n ńbẹ̀bẹ̀ fún ‘rànwọ́ rẹ̀ - Láti mẹ́jẹ̀ẹ́ wọn ṣẹ. - (ÈGBÈ 2) - Aya jẹ́jẹ̀ẹ́ fọ́kọ pé: - Màá fẹ́ ọ látọkàn.’ - ‘Ohun t’Ọlọ́run so pọ̀, - Kéèyàn má ṣe yà wọ́n.’ 
(Tún wo Jẹ́n. 2:24; Oníw. 4:12; Éfé. 5:22-33.)