ORIN 39
Ní Orúkọ Rere Lọ́dọ̀ Ọlọ́run
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Gbogbo ayé wa ló yẹ kí á fi ṣe - Orúkọ rere, ká sì pòfin Jáà mọ́. - Tí Jèhófà bá rí bí a ṣe ń sapá tó - Láti ṣèfẹ́ rẹ̀, ó máa láyọ̀. 
- 2. Ayé yìí lè fẹ́ ká wá orúkọ ńlá; - Ká wá òkìkí àt’ojúure èèyàn. - Tá a bá dọ̀rẹ́ ayé, asán ni gbogbo rẹ̀. - A ò ní rí ojúure Jèhófà. 
- 3. A fẹ́ k’Ọ́lọ́run rántí wa sí rere; - Ká ní orúkọ rere títí ayé. - A ó gbèjà òtítọ́, a gbọ́kàn wa lé Ọ. - A ó pa orúkọ rere wa mọ́. 
(Tún wo Jẹ́n. 11:4; Òwe 22:1; Mál. 3:16; Ìfi. 20:15.)