ORIN 13
Kristi, Àwòkọ́ṣe Wa
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, - Ó ṣoore ńlá fún wa. - Ó fọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n r’aráyé pa dà. - Nígbà tó wá sáyé, - Àpẹẹrẹ rere ni. - Ìwà rẹ̀ gbórúkọ Ọlọ́run ga. 
- 2. Ọ̀rọ̀ Jèhófà yè; - Ó fún Jésù nímọ̀, - Ó sì fún un lóye, ó gbé ẹ̀mí rẹ̀ ró. - Bó ṣe j’ónírẹ̀lẹ̀ - Jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa. - Ó máa ń wù ú láti ṣèfẹ́ Jèhófà. 
- 3. Bíi ti Jésù Kristi, - Kígbèésí ayé wa - Máa mú ìyìn bá Jèhófà Bàbá wa. - Ká fìwà jọ Jésù - Lójoojúmọ́ ayé, - Ká lè máa rójú rere Jèhófà. 
(Tún wo Jòh. 8:29; Éfé. 5:2; Fílí. 2:5-7.)