ORIN 127
Irú Èèyàn Tó Yẹ Kí N Jẹ́
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Jèhófà, kí ni mo lè fi san oore - Tó o ṣe ní ayé mi, tó o dá ẹ̀mí mi sí? - Mo fọ̀rọ̀ rẹ yẹ ọkàn mi wò bíi dígí. - Jọ̀ọ́, jẹ́ n lè mọrú ẹni tí mo jẹ́ dáadáa. - (ÀSOPỌ̀) - Mo ti pinnu pé màá fayé mi sìn ọ́. - Kì í ṣe pé wọ́n fipá mú mi láti ṣe bẹ́ẹ̀. - Tọkàntọkàn ni mo yàn láti sìn ọ́. - Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n lè máa mú inú rẹ dùn. - Ràn mí lọ́wọ́ kí n lè yẹ ara mi wò, - Kí n sì lè mọ irú ẹni tó o fẹ́ kí n jẹ́. - Ìwọ máa ń ṣìkẹ́ àwọn adúróṣinṣin. - Jẹ́ kí n wà lára àwọn tó ń mọ́kàn rẹ yọ̀. 
(Tún wo Sm. 18:25; 116:12; Òwe 11:20.)