ORIN 100
Máa Fi Ìfẹ́ Gbà Wọ́n Lálejò
Bíi Ti Orí Ìwé
	(Ìṣe 17:7)
- 1. Jèhófà máa ń fìfẹ́ tọ́jú gbogbo wa. - Ó máa ń fìfẹ́ pèsè fún gbogbo èèyàn. - Ó ń mú kí oòrùn ràn, - Ó ńmú kí òjò rọ̀; - Ó ń fún wa ní oúnjẹ tó dára. - Ó yẹ káwa náà fara wé Ọlọ́run. - Ká máa ṣàánú àwọn tó jẹ́ aláìní. - Ká máa ràn wọ́n lọ́wọ́, - Kí ara lè tù wọ́n. - Ká rí i pé a ṣeé látọkàn wá. 
- 2. Ẹ jẹ́ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Lìdíà - Tó gba àwọn ẹni mímọ́ lálejò. - Ẹ̀mí ọ̀làwọ́ wa - Àtìfẹ́ tá a ń fi hàn - Yóò fògo fún Bàbá wa ọ̀run. - Tí àwọn àlejò bá wá sọ́dọ̀ wá, - Ẹ jẹ́ ká fìfẹ́ gbà wọ́n sínú ‘lé wa. - Bàbá wa onífẹ̀ẹ́ - Rí gbogbo ‘hun tá à ń ṣe. - Ó dájú pé yóò pín wa lérè.