ORIN 98
Ọlọ́run Ló Mí sí Ìwé Mímọ́
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Ọ̀r’Ọlọ́run tàn bí ‘mọ́lẹ̀ - Láyé tó ṣókùnkùn yìí. - Tá a bá ń jẹ́ kó ṣamọ̀nà wa, - Òótọ́ rẹ̀ yóò dá wa sílẹ̀. 
- 2. Ọlọ́run mí s’Ìwé Mímọ́, - Láti darí ‘ṣísẹ̀ wa. - Ó fi ń kọ́ wa, ó ńbá wa wí. - Ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ń gbé wa ró. 
- 3. Tá a bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run - Lójoojúmọ́ ayé wa, - A ó máa túbọ̀ sún m’Ọ́lọ́run, - Ìfẹ́ tá a ní yóò máa pọ̀ sí i. 
(Tún wo Sm. 119:105; Òwe 4:13.)