ORIN 132
A Ti Di Ọ̀kan Ṣoṣo
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Èyí ni egungun tèmi. - Jèhófà ló pèsè rẹ̀ fún mi. - Mo ti wá ní ẹnì kejì; - Èmi kò dá wà mọ́. - A ti wá di ọ̀kan ṣoṣo; - Kí Jáà bù kún àwa méjèèjì. - A ti wá di ìdílé kan; - A di tọkọtaya. - A ó jọ máa sin Ọlọ́run pa pọ̀. - A ó máa fara wé e, - A ó fẹ́ra wa látọkàn. - Bá a ṣe jẹ́jẹ̀ẹ́, bẹ́ẹ̀ ni kó rí. - Kí ìtura, ayọ̀, wọlé wá. - A ó máa fògo fún Jèhófà, - A ó sì jọ bára wa kalẹ́. 
(Tún wo Jẹ́n. 29:18; Oníw. 4:9, 10; 1 Kọ́r. 13:8.)