ORIN 33
Ju Ẹrù Rẹ Sọ́dọ̀ Jèhófà
Bíi Ti Orí Ìwé
	(Sáàmù 55)
- 1. “Gbọ́ àdúrà mi,” Jèhófà. - Má fojú pa mọ́ fún mi. - Wo bínú mi ṣe bà jẹ́ tó; - Jọ̀ọ́, fi mí lọ́kàn balẹ̀. - (ÈGBÈ) - Ju gbogbo ẹrù ‘nira rẹ - Sí Jèhófà, kó o sì gbẹ́kẹ̀ lé e. - Ààbò rẹ̀ máa wà lórí rẹ - Torí pé olóòótọ́ ni. 
- 2. Tí mo bá lè fò bí ẹyẹ, - Màá fò ré kọjá ewu. - Kémi lè bọ́ lọ́wọ́ ọ̀tá - Tí ó ń lépa ẹ̀mí mi. - (ÈGBÈ) - Ju gbogbo ẹrù ‘nira rẹ - Sí Jèhófà, kó o sì gbẹ́kẹ̀ lé e. - Ààbò rẹ̀ máa wà lórí rẹ - Torí pé olóòótọ́ ni. 
- 3. Ọlọ́run máa ń tù wá nínú, - Ó ń fi wá lọ́kàn balẹ̀. - Yóò máa bá wa gbé ẹrù wa - Torí ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. - (ÈGBÈ) - Ju gbogbo ẹrù ‘nira rẹ - Sí Jèhófà, kó o sì gbẹ́kẹ̀ lé e. - Ààbò rẹ̀ máa wà lórí rẹ - Torí pé olóòótọ́ ni.