ORIN 94
A Mọyì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Jèhófà Bàbá wa, jọ̀ọ́ gba ọpẹ́ wa. - A mọrírì Ìwé Mímọ́ tó o fún wa! - Òtítọ́ ni Ọ̀rọ̀ rẹ; - Ó máa ń tọ́ wa sọ́nà. - Ó dà bí ìmọ́lẹ̀, ó ń jẹ́ ká róòótọ́. 
- 2. Òtítọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ máa ń wọni lọ́kàn. - Ó máa ń jẹ́ ká mọ irú ẹni tá a jẹ́. - Òfin rẹ ṣe kedere, - ìdájọ́ rẹ wúlò. - Àwọn ìlànà rẹ sì máa ń darí wa. 
- 3. Ọ̀rọ̀ rẹ ṣàǹfààní, ó ń wọ̀ wá lọ́kàn. - Èèyàn bíi tiwa ni àwọn wòlí ì rẹ. - Jẹ́ ká tẹ̀ lápẹẹrẹ wọn; - káwa náà nígbàgbọ́. - A dúpẹ́ Jèhófà, fún ẹ̀bùn ńlá yìí! 
(Tún wo Sm. 19:9; 119:16, 162; 2 Tím. 3:16; Jém. 5:17; 2 Pét. 1:21.)