ORIN 122
Ẹ Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Ṣinṣin
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Hílàhílo ti dé bá aráyé; - Wọn kò mọ ohun tá á ṣẹlẹ̀ lọ́la. - Ó yẹ káwa fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, - Ká fòótọ́ sin Ọlọ́run. - (ÈGBÈ) - Ó yẹ ká dúró ṣinṣin, - Ká má ṣe báyé ṣọ̀rẹ́. - Kí á jẹ́ olóòótọ́, - Ká lè jogún ìyè. 
- 2. Ìdẹwò pọ̀ gan-an nínú ayé yìí. - Èrò tó tọ́ yóò mú ká borí wọn. - Tá a bá kórìíra ohun tó burú, - Yóò jẹ́ kẹ́sẹ̀ wa múlẹ̀. - (ÈGBÈ) - Ó yẹ ká dúró ṣinṣin, - Ká má ṣe báyé ṣọ̀rẹ́. - Kí á jẹ́ olóòótọ́, - Ká lè jogún ìyè. 
- 3. Ká jọ́sìn Ọlọ́run látọkàn wá; - Ká sì tẹra mọ́ iṣẹ́ Olúwa. - Ká wàásù Ìjọba náà fáráyé; - Òpin ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé tán. - (ÈGBÈ) - Ó yẹ ká dúró ṣinṣin, - Ká má ṣe báyé ṣọ̀rẹ́. - Kí á jẹ́ olóòótọ́, - Ká lè jogún ìyè. 
(Tún wo Lúùkù 21:9; 1 Pét. 4:7.)