ORIN 139
Fojú Inú Wo Ìgbà Tí Gbogbo Nǹkan Máa Di Tuntun
- 1. Wo ara rẹ àtèmi náà - Bíi pé a wà nínú ayé tuntun. - Wo bí yóò ṣe rí lára rẹ - Pé gbogbo ayé wà lálàáfíà. - Kò sí èèyàn búburú mọ́; - Ìjọba Ọlọ́run dúró láé. - Àkókò ìtura ti dé fáráyé - A ó máa kọrin ìyìn jáde - látọkàn wá: - (ÈGBÈ) - “A dúpẹ́, Jèhófà Ọlọ́run wa. - Ìjọba Ọmọ rẹ sọ nǹkan dọ̀tun. - Ayọ̀ kún ọkàn wa, a sì ń kọrin ọpẹ́. - Kí ògo, ìyìn àtọlá jẹ́ tìrẹ láé.” 
- 2. Wo ara rẹ, wo èmi náà, - Bá ó ṣe jọ máa gbádùn láyé tuntun. - Ìbànújẹ́ kò ní sí mọ́; - Kò sóhun tó máa dẹ́rù bà wá. - Ìlérí Ọlọ́run máa ṣẹ: - Àgọ́ rẹ̀ yóò bo gbogbo ayé. - Yóò sì jí àwọn tó ń sùn nínú ikú; - Àwọn àtàwa náà yóò máa - kọrin ọpẹ́: - (ÈGBÈ) - “A dúpẹ́, Jèhófà Ọlọ́run wa. - Ìjọba Ọmọ rẹ sọ nǹkan dọ̀tun. - Ayọ̀ kún ọkàn wa, a sì ń kọrin ọpẹ́. - Kí ògo, ìyìn àtọlá jẹ́ tìrẹ láé.” 
(Tún wo Sm. 37:10, 11; Àìsá. 65:17; Jòh. 5:28; 2 Pét. 3:13.)