ORIN 8
Jèhófà Ni Ibi Ààbò Wa
Bíi Ti Orí Ìwé
	(Sáàmù 91)
- 1. Jèhófà ni ààbò wa. - Ìwọ la gbẹ́kẹ̀ lé. - Òjìji rẹ la sá di, - A ò ní sá kúrò láé. - Torí a mọ̀ pé wàá gbèjà - Àwọn tó bá gbára lé ọ. - Jèhófà l’Olùṣọ́ wa; - Olódodo, olóòótọ́ ni. 
- 2. Jèhófà máa ń dáàbò bo - Àwọn olódodo - Àti ọlọ́kàn tútù; - Kò ní pa wọ́n tì láé. - Torí náà, kò yẹ ká bẹ̀rù - Torí ìyọnu àjálù. - Òun yóò máa dá wa nídè - Kúrò lọ́wọ́ ẹni ibi. 
- 3. Ó ń tọ́ wa, ó sì ńṣọ́ wa - Ká má kó sídẹkùn. - Ó ń fún wa lókun ká lè - Máa kojú àtakò. - Kò sí ìdí kankan fún wa - Láti bẹ̀rù ohunkóhun. - Jèhófà ni ààbò wa, - Yóò dáàbò bò wá títí láé. 
(Tún wo Sm. 97:10; 121:3, 5; Àìsá. 52:12.)