ORIN 2
Jèhófà Ni Orúkọ Rẹ
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Ọlọ́run òtítọ́, - Jèhófà lorúkọ rẹ. - Ìwọ nìkan lo ṣẹ̀dá - Gbogbo ohun tó wà. - Àǹfààní ńlá la ní - Pé a jẹ́ ènìyàn rẹ. - Nínú gbogbo aráyé, - À ń jẹ́ kógo rẹ tàn. - (ÈGBÈ) - Jèhófà, Jèhófà, - Kò s’Ọ́lọ́run mìíràn - Tó dà bíi rẹ lábẹ́ ilẹ̀, - Lọ́run tàbí láyé. - Ọlọ́run Olódùmarè; - Gbogbo ayé yóò gbọ́. - Jèhófà, Jèhófà, - Ìwọ nìkan ṣoṣo la ní. 
- 2. Alèwí, Alèṣe; - O mú kí a lè máa ṣe - Ohunkóhun tí o fẹ́, - Ká sì ṣe é bó o ṣe fẹ́ẹ. - Ẹlẹ́rìí Jèhófà - Ni orúkọ tó o fún wa. - Ọlá ńlá ló sì jẹ́ pé - Aráyé ń pè wá bẹ́ẹ̀. - (ÈGBÈ) - Jèhófà, Jèhófà, - Kò s’Ọ́lọ́run mìíràn - Tó dà bí rẹ lábẹ́ ilẹ̀, - Lọ́run tàbí láyé. - Ọlọ́run Olódùmarè; - Gbogbo ayé yóò gbọ́. - Jèhófà, Jèhófà, - Ìwọ nìkan ṣoṣo la ní. 
(Tún wo 2 Kíró. 6:14; Sm. 72:19; Àìsá. 42:8.)