ORIN 48
Máa Bá Jèhófà Rìn Lójoojúmọ́
Bíi Ti Orí Ìwé
	(Míkà 6:8)
- 1. Ní ojoojúmọ́ ayé wa, - A ó máa fìrẹ̀lẹ̀ b’Ọ́lọ́run rìn. - Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí - Ló fún àwọn tó fẹ́ dọ̀rẹ́ rẹ̀. - Ìfẹ́ ló mú kó fún wa ní - Àǹfààní láti bá a rìn. - Bá a ṣe yara wa sí mímọ́, - Ká má fi Jèhófà sílẹ̀. 
- 2. Lákòókò t’Èṣù ń bínú yìí, - Tí òpin sì ń yára sún mọ́lé, - À ń kojú inúnibíni - Tó lè fẹ́ mú ká juwọ́ sílẹ̀. - Àmọ́ Jáà máa ń dáàbò bò wá; - Ká má kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. - Ká fi gbogbo ọkàn wa sìn ín, - Ká jẹ́ adúróṣinṣin sí i. 
- 3. Jèhófà máa ń fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ - Àti ẹ̀mí rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́. - Ó máa ń lo ìjọ Kristẹni, - Ó sì tún máa ń gbọ́ àdúrà wa. - Bí a ṣe ń bá Jèhófà rìn, - Yóò mú ká ṣohun tó tọ́. - Yóò mú ká lè dúró ṣinṣin, - Ká sì máa fìrẹ̀lẹ̀ bá a rìn. 
(Tún wo Jẹ́n. 5:24; 6:9; 1 Ọba 2:3, 4.)