ORIN 88
Mú Mi Mọ Àwọn Ọ̀nà Rẹ
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Bàbá wa ọ̀run, a ti pé jọ báyìí, - Kó o lè kọ́ wa, ká sì jọ́sìn rẹ. - Ṣe ni Ọ̀rọ̀ rẹ dà bí ìmọ́lẹ̀ tí - Ó ń tọ́ wa sọ́nà ká lè ríyè. - (ÈGBÈ) - Jọ̀ọ́, Jèhófà, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, - Jẹ́ kí n lè máa fetí sí àṣẹ rẹ. - Mú mi mọ àwọn ọ̀nà òdodo, - Kí òfin rẹ sì máa múnú mi dùn. 
- 2. Àwọn ọ̀nà ọgbọ́n rẹ kò láfiwé; - Ìdájọ́ òdodo lo máa ń ṣe. - Àwọn ẹ̀kọ́ rẹ ń tọ́ wa sọ́nà òótọ́, - Ọ̀rọ̀ tó o sọ máa wà títí láé. - (ÈGBÈ) - Jọ̀ọ́, Jèhófà, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, - Jẹ́ kí n lè máa fetí sí àṣẹ rẹ. - Mú mi mọ àwọn ọ̀nà òdodo, - Kí òfin rẹ sì máa múnú mi dùn.