ORIN 80
‘Tọ́ Ọ Wò, Kó O sì Rí I Pé Ẹni Rere Ni Jèhófà’
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Ayọ̀ tá a ní kò láfiwé; - A láǹfààní láti wàásù. - Tọkàntọkàn ni ká fi ṣiṣẹ́ náà - Ká lè ráwọn ẹni yíyẹ. - (ÈGBÈ) - Tọ́ ọ wò, kó o sì rí adùn rẹ̀ pé - Jèhófà jẹ́ni rere. - Bá a ṣe ń fọkàn sin Ọlọ́run wa, - Ó ń bù kún ìsapá wa. 
- 2. A mọyì àwọn ará wa - Tó jẹ́ alákòókò kíkún. - Ọ̀pọ̀ ìbùkún ń dúró de àwọn - Tó fara síṣẹ́ Jèhófà. - (ÈGBÈ) - Tọ́ ọ wò, kó o sì rí adùn rẹ̀ pé - Jèhófà jẹ́ni rere. - Bá a ṣe ń fọkàn sin Ọlọ́run wa, - Ó ń bù kún ìsapá wa. 
(Tún wo Máàkù 14:8; Lúùkù 21:2; 1 Tím. 1:12; 6:6.)