ORIN 65
Ẹ Tẹ̀ Síwájú!
- 1. Ẹ máa tẹ̀ síwájú, nínú òtítọ́. - Ká tan ìmọ́lẹ̀ òótọ́ fún gbogbo aráyé. - Jẹ́ kíṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ máa sunwọ̀n sí i; - Kó o gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run. - Gbogbo wa ló yẹ ká ṣiṣẹ́ yìí. - Rántí pé Jésù náà ṣiṣẹ́ yìí. - Máa bẹ Ọlọ́run pé kó dúró tì ọ́, - Kó o lè jẹ́ olódodo. 
- 2. Ẹ máa tẹ̀ síwájú, fìgboyà wàásù. - Ká sọ ìròyìn ayọ̀ fún gbogbo aráyé. - Ẹ jẹ́ ká máa wàásù látilé délé, - Ká fi yin Jáà, Ọba wa. - Báwọn ọ̀tá tiẹ̀ ń halẹ̀ mọ́ wa, - Má bẹ̀rù, ṣáà máa fòótọ́ kọ́ni. - Ká jẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ̀ pé láìpẹ́, - ’Jọba Ọlọ́run máa dé. 
- 3. Ẹ máa tẹ̀ síwájú, ẹ má ṣe yẹsẹ̀. - Ká sì máa sunwọ̀n sí i, - Iṣẹ́ ṣì pọ̀ láti ṣe. - Jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí rẹ, - Yóò sì máa fún ọ láyọ̀. - Nífẹ̀ẹ́ àwọn tí ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. - Kọ́ wọn kí òótọ́ lè dọ́kàn wọn. - Ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè dàgbà dénú, - Kí ‘mọ́lẹ̀ òótọ́ lè tàn. 
(Tún wo Fílí. 1:27; 3:16; Héb. 10:39.)