ORIN 137
Àwọn Obìnrin Olóòótọ́, Àwọn Arábìnrin Wa
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. A ní àwọn obìnrin tó jólóòótọ́. - Lára wọn ni Sérà, Ẹ́sítà, Rúùtù. - Màríà kò gbẹ́yìn; wọ́n fọkàn sin Jáà. - Adúróṣinṣin làwọn obìnrin yìí. - Ọ̀pọ̀ ló wà tá ò morúkọ wọn, - Àmọ́ ìgbàgbọ́ wọn jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa. 
- 2. Àwọn ànímọ́ tó dáa táráyé ń fẹ́— - Ìṣòtítọ́, ìgboyà, inú rere, - Làwọn obìnrin dáadáa wọ̀nyí gbé yọ. - Wọ́n jẹ́ àwòkọ́ṣe tó dára fún wa. - Lónìí náà, àwọn arábìnrin wa - Jẹ́ adúróṣinṣin, a sì mọyì wọn gan-an. 
- 3. Gbogbo ẹ̀yin arábìnrin wa ọ̀wọ́n, - Tẹ́ ẹ ń fìdùnnú ṣiṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. - Onírẹ̀lẹ̀ ni yín, ẹ máa ń tẹrí ba. - Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ yín, ẹ má ṣe bẹ̀rù. - Jèhófà kò ní fi yín sílẹ̀ láé; - Ẹ fọkàn yín balẹ̀, èrè yín ti dé tán! 
(Tún wo Fílí. 4:3; 1 Tím. 2:9, 10; 1 Pét. 3:4, 5.)