ORIN 109
Ní Ìfẹ́ Tó Ti Ọkàn Wá
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Jèhófà lorísun ìfẹ́. - Bí a bá ń fẹ́ni látọkàn, - A ó mú ọkàn rẹ̀ yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀; - Ìyẹn ṣeyebíye. - Bíjì bá ń jà, tílé sì ńjó, - Ìfẹ́ ará wa ń gbèrú sí i. - A kò ní fi wọ́n sílẹ̀ láé; - A nífẹ̀ẹ́ wọn dọ́kàn. - Bí a bá ń báni kẹ́dùn, - T áa fúnni lókun nígbà ‘ṣòro, - Ọ̀rẹ́ àìṣẹ̀tàn nìyẹn, - Elétí bánigbọ́rọ̀. - Bí Jésù sì ṣe nífẹ̀ẹ́ wa - Fi ànímọ́ Jèhófà hàn. - Àwa náà lè máa fìfẹ́ hàn - Lọ́nà tó dára jù lọ; - Ká nífẹ̀ẹ́ látọkàn wá. 
(Tún wo 1 Pét. 2:17; 3:8; 4:8; 1 Jòh 3:11.)