ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ̀yin Alàgbà, Ǹjẹ́ Ẹ Máa Ń Dá Àwọn Míì Lẹ́kọ̀ọ́?
    Ilé Ìṣọ́—2015 | April 15
    • Sámúẹ́lì àti Sọ́ọ̀lù jọ ń jẹun lórí ilé

      Ẹ̀yin Alàgbà, Ǹjẹ́ Ẹ Máa Ń Dá Àwọn Míì Lẹ́kọ̀ọ́?

      “Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún.” —ONÍW. 3:1.

      KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

      • Ọwọ́ wo ló yẹ ká fi mú dídá àwọn arákùnrin lẹ́kọ̀ọ́, kí sì nìdí?

      • Báwo ló ṣe máa ṣe ìjọ láǹfààní táwọn alàgbà bá ń dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́?

      • Báwo làwọn alàgbà ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Sámúẹ́lì tí wọ́n bá ń dáni lẹ́kọ̀ọ́?

      1, 2. Kí ni àwọn alábòójútó àyíká ti kíyè sí ní ọ̀pọ̀ ìjọ?

      NÍGBÀ tí alábòójútó àyíká kan fẹ́ parí ìpàdé pẹ̀lú ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ìjọ kan, inú rẹ̀ dùn gan-an bó ṣe wojú àwọn alàgbà tó ń ṣiṣẹ́ kára yìí, léyìí tó jẹ́ pé àwọn kan lára wọn tó bí i lọ́mọ. Síbẹ̀, nǹkan kan wà tó fẹ́ kí wọ́n fún láfiyèsí, torí náà ó bi wọ́n pé, “Kí lẹ ti ṣe láti dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè tẹ́wọ́ gba àfikún iṣẹ́ nínú ìjọ?” Wọ́n rántí pé nígbà ìbẹ̀wò tí alábòójútó àyíká ṣe kẹ́yìn, ó rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n túbọ̀ máa dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́. Alàgbà kan wá sọ pé, “Ká sòótọ́, ohun tá a ṣe kò tó nǹkan.” Àwọn alàgbà tó kù sì gbà pẹ̀lú rẹ̀.

      2 Tó o bá jẹ́ alàgbà nínú ìjọ, ohun tó ṣẹlẹ̀ nípàdé àwọn alàgbà yẹn lè ti ṣẹlẹ̀ lójú ìwọ náà rí. Kárí ayé, àwọn alábòójútó àyíká ti kíyè sí i pé ó yẹ kí ọ̀pọ̀ ìjọ ṣe púpọ̀ sí i láti dá àwọn ọ̀dọ́ àtàwọn àgbàlagbà ọkùnrin lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè bójú tó agbo Ọlọ́run. Lóòótọ́, èyí lè má rọrùn. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?

      3. (a) Báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe fi hàn pé ó ṣe pàtàkì ká máa dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́, kí sì nìdí tó fi yẹ kí gbogbo wa fún ìjíròrò yìí láfiyèsí? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.) (b) Kí nìdí tó fi lè ṣòro fún àwọn alàgbà kan láti dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́?

      3 Tó o bá jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn nínú ìjọ, o mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì kó o máa dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́.a O mọ̀ pé a nílò àwọn arákùnrin púpọ̀ sí i kí ìjọ lè máa lágbára nípa tẹ̀mí, kí a sì lè dá àwọn ìjọ tuntun sílẹ̀. (Ka Aísáyà 60:22.) O tún mọ̀ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá níyànjú pé kí a “kọ́ àwọn ẹlòmíràn.” (Ka 2 Tímótì 2:2.) Síbẹ̀, bíi ti àwọn alàgbà tá a sọ̀rọ̀ wọn níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, ó lè má rọrùn fún ẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn tó o bá bójú tó ìdílé rẹ, tó o ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, tó o ṣe ojúṣe rẹ nínú ìjọ, tó o sì tún bójú tó àwọn ọ̀ràn míì tó jẹ́ kánjúkánjú, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kò sí àyè láti dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ nínú ìjọ. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, jẹ́ ká jíròrò ọwọ́ tó yẹ ká fi mú dídá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́.

      ÌDÁLẸ́KỌ̀Ọ́ ṢE PÀTÀKÌ GAN-AN

      4. Kí ló ṣeé ṣe kó jẹ́ ìdí rẹ̀ tí ọ̀pọ̀ fi máa ń fi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ falẹ̀?

      4 Kí nìdí tó fi ṣòro fún àwọn alàgbà kan láti wáyè kí wọ́n lè dá àwọn ẹlòmíì lẹ́kọ̀ọ́? Àwọn kan lè ronú pé: ‘Ìdálẹ́kọ̀ọ́ ṣe pàtàkì lóòótọ́, àmọ́ àwọn ọ̀ràn míì wà nínú ìjọ tá a gbọ́dọ̀ bójú tó ní kánjúkánjú. Bó bá tiẹ̀ ṣì pẹ́ díẹ̀ kí n tó dá àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, ìyẹn ò sọ pé kí nǹkan má lọ bó ṣe yẹ nínú ìjọ.’ Òótọ́ ni pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló yẹ kẹ́ ẹ bójú tó lójú ẹsẹ̀, àmọ́ tẹ́ ẹ bá ń fi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ falẹ̀ ó lè ṣe ìpalára fún ìjọ nípa tẹ̀mí.

      5, 6. Ẹ̀kọ́ wo la lè kọ́ lára awakọ̀ àti ọwọ́ tó fi mú ṣíṣe àbójútó ọkọ̀ rẹ̀, báwo la sì ṣe lè fi èyí wé bí a ṣe ń dáni lẹ́kọ̀ọ́ nínú ìjọ?

      5 Ronú nípa àpèjúwe yìí ná: Awakọ̀ kan lè mọ̀ pé tí òun bá fẹ́ kí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ òun àti ẹ́ńjìnnì rẹ̀ máa ṣiṣẹ́ dáadáa, ó ṣe pàtàkì kí òun máa pààrọ̀ ọ́ìlì ọkọ̀ náà látìgbàdégbà. Síbẹ̀, ó lè ronú pé kí òun máa ra epo pẹtiróòlù sọ́kọ̀ náà jẹ́ kánjúkánjú ju kí òun máa pààrọ̀ ọ́ìlì lọ. Ó ṣe tán, tí pẹtiróòlù ò bá sí nínú ọkọ̀ rẹ̀, kò ní pẹ́ tí ọkọ̀ náà fi máa dáṣẹ́ dúró. Awakọ̀ náà lè máa wò ó pé, ‘tí mi ò bá ráyè pààrọ̀ ọ́ìlì náà, ìyẹn ò sọ pé kí ọkọ̀ náà má ṣiṣẹ́, ó kéré tán á ṣì ṣiṣẹ́ fúngbà díẹ̀.’ Àmọ́, ewu wo ló wà nínú ohun tí awakọ̀ yìí ń ṣe? Tó bá ń fòní dónìí, fọ̀la dọ́la tó sì kọ̀ láti ṣàyẹ̀wò ọkọ̀ rẹ̀ lásìkò, kò ní pẹ́ tí ọkọ̀ náà á fi bàjẹ́. Tó bá sì ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, ó máa ná ọ̀pọ̀ owó, ó sì tún máa gba àkókò láti tún ọkọ̀ náà ṣe kó tó lè máa rìn geerege lẹ́ẹ̀kan sí i. Ẹ̀kọ́ wo ni àpèjúwe yìí kọ́ wa?

      6 Àwọn alàgbà ní ọ̀pọ̀ iṣẹ́ pàtàkì tí wọ́n gbọ́dọ̀ bójú tó ní kánjúkánjú; torí bí wọn kò bá ṣe é, ó máa pa ìjọ lára gan-an. Bí awakọ̀ inú àpèjúwe yẹn ṣe gbọ́dọ̀ máa fi epo pẹtiróòlù sínú ọkọ̀ rẹ̀, àwọn alàgbà náà gbọ́dọ̀ “máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.” (Fílí. 1:10) Àmọ́, àwọn iṣẹ́ pàtàkì tó ń fẹ́ àbójútó ní kánjúkánjú máa ń mú kí ọwọ́ àwọn alàgbà kan dí gan-an, ìyẹn ni kì í jẹ́ kí wọ́n ráyè dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́. Ńṣe nìyẹn sì dà bí ìgbà tí awakọ̀ kan kò pààrọ̀ ọ́ìlì ọkọ̀ rẹ̀. Tí àwọn alàgbà bá ń fòní dónìí fọ̀la dọ́la lórí ọ̀rọ̀ ìdálẹ́kọ̀ọ́, bó pẹ́ bó yá àwọn arákùnrin tó kúnjú ìwọ̀n kò ní pọ̀ tó láti bójú tó àwọn iṣẹ́ tó yẹ ká ṣe nínú ìjọ.

      7. Ojú wo ló yẹ ká fi wo àwọn alàgbà tó máa ń wáyè láti kọ́ àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́?

      7 A ti wá rí i báyìí pé, kò yẹ kí àwọn alàgbà máa rò pé dídá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì. Àwọn alàgbà tó bá ń ronú nípa ohun tó máa ṣe ìjọ láǹfààní lọ́jọ́ iwájú, tí wọ́n sì ń wáyè láti dá àwọn arákùnrin tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ ní ìrírí lẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ ọlọ́gbọ́n ìríjú, ìbùkún gidi ni wọ́n sì jẹ́ fún gbogbo ìjọ. (Ka 1 Pétérù 4:10.) Báwo lèyí ṣe ń ṣe ìjọ láǹfààní?

      OHUN TÓ BỌ́GBỌ́N MU

      8. (a) Ànímọ́ wo ló máa mú kí àwọn alàgbà dá àwọn ẹlòmíì lẹ́kọ̀ọ́, kí sì nìdí tó fi yẹ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀? (b) Ojúṣe tó jẹ́ kánjúkánjú wo ni àwọn alàgbà tó ń sìn níbi tí àìní pọ̀ sí ní? (Wo àpótí náà “Iṣẹ́ Tó Pọn Dandan.”)

      8 Ìrẹ̀lẹ̀ máa mú kí àwọn alàgbà tó nírìírí gan-an gbà pé bí ara ṣe ń dara àgbà ni iṣẹ́ tí àwọn lè ṣe nínú ìjọ á máa dín kù díẹ̀díẹ̀. (Míkà 6:8) Ó tún yẹ kí wọ́n gbà pé “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” lè wáyé lójijì, èyí sì lè mú kí wọ́n má lè ṣe àwọn iṣẹ́ tí wọ́n ti ń bójú tó nínú ìjọ tẹ́lẹ̀. (Oníw. 9:11, 12; Ják. 4:13, 14) Àwọn alàgbà tó nífẹ̀ẹ́ àwọn àgùntàn Jèhófà dénú, tí wọ́n sì ń ro ohun tó máa ṣe ìjọ láǹfààní lọ́jọ́ iwájú, máa ń ṣètò déédéé láti ṣàjọpín ìrírí wọn pẹ̀lú àwọn arákùnrin tó kéré sí wọn.—Ka Sáàmù 71:17, 18.

      9. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú tó mú kó ṣe pàtàkì pé ká máa dá àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nísinsìnyí?

      9 Kí nìdí tá a tún fi lè sọ pé àwọn alàgbà tó ń dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ ìbùkún fún agbo? Wọ́n ń jẹ́ kí ìjọ túbọ̀ jẹ́ alágbára kí wọ́n lè borí ìdẹwò. Lọ́nà wo? Tí àwọn alàgbà bá ń sapá láti dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́, a máa rí àwọn arákùnrin púpọ̀ sí i tí wọ́n á lè ran ìjọ lọ́wọ́ láti jẹ́ adúróṣinṣin kí wọ́n sì wà níṣọ̀kan nísinsìnyí, àti pàápàá jù lọ lákòókò tí nǹkan bá le koko nígbà ìpọ́njú ńlá. (Ìsík. 38:10-12; Míkà 5:5, 6) Nítorí náà, ẹ̀yin alàgbà wa ọ̀wọ́n, à ń rọ̀ yín pé láti àkókò yìí lọ ẹ máa dá àwọn ẹlòmíì lẹ́kọ̀ọ́ déédéé bẹ́ ẹ ṣe ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ yín.

      10. Kí ni alàgbà kan lè ṣe kó bàa lè ráyè dá àwọn ẹlòmíì lẹ́kọ̀ọ́?

      10 A mọ̀ pé àkókò tẹ́ ẹ̀ ń lò láti bójú tó àwọn iṣẹ́ pàtàkì nínú ìjọ pọ̀, ó tiẹ̀ lè dà bíi pé ó ń tán yín lókun. Nítorí náà, ó lè pọn dandan pé kí ẹ dín àkókò tí ẹ̀ ń lò fún àwọn nǹkan yẹn kù, kí ẹ lè ráyè dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́. (Oníw. 3:1) Tí ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe lẹ̀ ń pọn omi sílẹ̀ de òùngbẹ.

      Ẹ KỌ́KỌ́ JẸ́ KÍ ARA TÙ WỌ́N

      11. (a) Kí ló gbàfiyèsí nípa àwọn àbá tí àwọn alàgbà láti oríṣiríṣi orílẹ̀-èdè mú wa nípa ọ̀nà tá a lè gbà dáni lẹ́kọ̀ọ́? (b) Báwo ni Òwe 15:22 ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé ó máa ṣàfààní tá a bá gbé ohun tí àwọn alàgbà míì dábàá yẹ̀ wò?

      11 Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, a béèrè lọ́wọ́ àwọn alàgbà kan nípa ọ̀nà tí wọ́n gbé e gbà tí wọ́n fi dá ọ̀pọ̀ arákùnrin lẹ́kọ̀ọ́ débi tí òtítọ́ fi jinlẹ̀ nínú wọn.b Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ibi tí àwọn arákùnrin yìí ń gbé àti ipò wọn yàtọ̀ síra, ó gbàfiyèsí pé ìdáhùn wọn jọra gan-an ni. Kí lèyí kọ́ wa? Ó jẹ́ ká rí i pé ìdálẹ́kọ̀ọ́ tá a gbé ka Bíbélì máa ń ṣàǹfààní fún àwọn èèyàn “níbi gbogbo nínú gbogbo ìjọ,” bó sì ṣe rí náà nìyẹn nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wà láyé. (1 Kọ́r. 4:17) Nítorí náà, nínú àpilẹ̀kọ yìí àti èyí tó tẹ̀ lé e, a máa jíròrò àwọn ohun tí àwọn alàgbà náà dábàá. (Òwe 15:22) Kí àlàyé tá à ń ṣe lè rọrùn, nínú àpilẹ̀kọ méjèèjì a máa pe àwọn tó ń dáni lẹ́kọ̀ọ́ ní “olùkọ́” a sì máa pe àwọn tá à ń dá lẹ́kọ̀ọ́ ní “akẹ́kọ̀ọ́.”

      12. Kí ló yẹ kí olùkọ́ ṣe, kí sì nìdí?

      12 Olùkọ́ gbọ́dọ̀ mú kí ara tu akẹ́kọ̀ọ́ kí ohun tó ń kọ́ ọ bàa lè wọ̀ ọ́ lọ́kàn. Bó ṣe jẹ́ pé àgbẹ̀ máa ń kọ́kọ́ túlẹ̀ kó tó gbin irúgbìn sí oko rẹ̀, bákan náà ló ṣe yẹ kí olùkọ́ múra ọkàn akẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀ tàbí kó fún un níṣìírí kó tó kọ́ ọ lóhun tuntun. Ọ̀nà wo wá ni olùkọ́ lè gbà múra ọkàn àwọn míì sílẹ̀ kó tó dá wọn lẹ́kọ̀ọ́? Ọ̀nà tó lè gbà ṣe é ni pé kó tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wòlíì ìgbàanì kan. Kí ni wòlíì náà ṣe?

      13-15. (a) Iṣẹ́ wo ni Ọlọ́run gbé fún wòlíì Sámúẹ́lì? (b) Ọ̀nà wo ni Sámúẹ́lì gbà ṣe iṣẹ́ náà? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (d) Kí nìdí tó fi yẹ kí àwọn alàgbà lóde òní fún àkọsílẹ̀ Bíbélì yìí nípa Sámúẹ́lì láfiyèsí àrà ọ̀tọ̀?

      13 Ó ṣẹlẹ̀ pé lọ́jọ́ kan ní nǹkan tó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] ọdún sẹ́yìn, Jèhófà sọ fún wòlíì tó ti dàgbà náà, Sámúẹ́lì pé: “Ní ìwòyí ọ̀la, èmi yóò rán ọkùnrin kan láti ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì sí ọ, kí o sì fòróró yàn án ṣe aṣáájú lórí àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì.” (1 Sám. 9:15, 16) Èyí jẹ́ kí Sámúẹ́lì mọ̀ pé iṣẹ́ òun láti máa darí orílẹ̀-èdè náà ti wá sópin àti pé Jèhófà ti gbé iṣẹ́ lé òun lọ́wọ́ láti yan ẹni tó máa rọ́pò òun. Ó ṣeé ṣe kí Sámúẹ́lì máa rò ó pé, ‘Báwo ni màá ṣe mú kí ọkùnrin yìí mọ iṣẹ́ tó gbà?’ Ohun kan wá sí i lọ́kàn, ó sì mọ bí òun ṣe máa ṣe é.

      14 Lọ́jọ́ kejì nígbà tí Sámúẹ́lì rí Sọ́ọ̀lù, Jèhófà sọ fún wòlíì náà pé: “Ọkùnrin náà rèé.” Sámúẹ́lì wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tó ní lọ́kàn. Ó ní kí Sọ́ọ̀lù wá jẹun ní gbọ̀ngàn ìjẹun. Ó sì fún Sọ́ọ̀lù àti ẹmẹ̀wà rẹ̀ ní ààyè ìjókòó tó lọ́lá jù lọ àti ekìrí ẹran tó dára jù lọ, Sámúẹ́lì sì sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Jẹ ẹ́, nítorí wọ́n ti fi pa mọ́ dè ọ́ fún àkókò tí a yàn kalẹ̀.” Lẹ́yìn náà, Sámúẹ́lì àti Sọ́ọ̀lù jọ rìn lọ sílé wòlíì náà, wọ́n jọ ń sọ̀rọ̀ bí wọ́n ṣe ń lọ. Lẹ́yìn tí Sámúẹ́lì àti Sọ́ọ̀lù ti jẹun dáadáa tí wọ́n sì ti jọ rìnrìn gbẹ̀fẹ́ lọ sílé rẹ̀, ó mọ̀ pé ara ti tu Sọ́ọ̀lù ó sì fẹ́ lo àkókò náà lọ́nà rere. Torí náà, ó ní kí Sọ́ọ̀lù jẹ́ káwọn lọ sórí ilé. Bí atẹ́gùn ọwọ́ alẹ́ ṣe ń fẹ́ yẹ́ẹ́ sí wọn lára, Sámúẹ́lì “ń bá a lọ ní bíbá Sọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ ní orí ilé” títí wọ́n fi lọ sùn. Lọ́jọ́ tó tẹ̀ lé e, Sámúẹ́lì fòróró yan Sọ́ọ̀lù, ó fẹnu kò ó lẹ́nu, ó sì tún fún un ní ìtọ́ni síwájú sí i. Lẹ́yìn tó ti múra Sọ́ọ̀lù sílẹ̀ fún àwọn ohun tó máa wáyé láìpẹ́, ó ní kó máa lọ.—1 Sám. 9:17-27; 10:1.

      15 Àmọ́, ìyàtọ̀ wà nínú kí wọ́n fòróró yan ọkùnrin kan láti di olórí orílẹ̀-èdè kan àti fífún arákùnrin kan ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ kó lè di alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ. Síbẹ̀, àwọn alàgbà lóde òní lè kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì nínú ohun tí Sámúẹ́lì ṣe. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ lórí méjì nínú rẹ̀.

      OLÙKỌ́ TÓ ṢE TÁN LÁTI KỌ́NI TÓ SÌ TÚN JẸ́ Ọ̀RẸ́ TÒÓTỌ́

      16. (a) Báwo ló ṣe rí lára Sámúẹ́lì nígbà tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sọ pé àwọn fẹ́ ọba? (b) Ọwọ́ wo ni Sámúẹ́lì fi mú iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún un pé kó fòróró yan Sọ́ọ̀lù?

      16 Múra tán láti kọ́ àwọn ẹlòmíì, má ṣe lọ́ tìkọ̀. Nígbà tí Sámúẹ́lì kọ́kọ́ gbọ́ pé àwọn èèyàn Ísírẹ́lì fẹ́ kí ẹnì kan máa jọba lé wọn lórí, ó ṣe é bíi pé àwọn èèyàn òun já òun kulẹ̀, wọn ò sì fẹ́ kí òun máa darí wọn mọ́. (1 Sám. 8:4-8) Kódà, ó lọ́ tìkọ̀ láti ṣe ohun táwọn èèyàn náà fẹ́ débi pé ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jèhófà sọ fún un pé kó ṣe ohun táwọn èèyàn náà ń sọ. (1 Sám. 8:7, 9, 22) Síbẹ̀, Sámúẹ́lì ò di ọkùnrin tó máa gba ipò lọ́wọ́ rẹ̀ sínú tàbí kó kórìíra rẹ̀. Nígbà tí Jèhófà sọ fún un pé kó fòróró yan Sọ́ọ̀lù, wòlíì náà ṣe bẹ́ẹ̀, kì í ṣe pé ó kàn gbà bẹ́ẹ̀ torí pé ó di dandan, ṣùgbọ́n ìfẹ́ ló mú kó múra tán láti ṣe bẹ́ẹ̀.

      17. Báwo làwọn alàgbà lónìí ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Sámúẹ́lì, àǹfààní wo nìyẹn sì máa ń ṣe fún wọn?

      17 Lónìí, àwọn alàgbà tó jẹ́ onírìírí máa ń fi ìfẹ́ dá àwọn ẹlòmíì lẹ́kọ̀ọ́ bíi ti Sámúẹ́lì. (1 Pét. 5:2) Irú àwọn alàgbà bẹ́ẹ̀ kì í fà sẹ́yìn láti dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ torí ìbẹ̀rù pé àwọn tí wọ́n bá dá lẹ́kọ̀ọ́ máa gba àwọn iṣẹ́ kan tí wọ́n ń bójú tó nínú ìjọ mọ́ wọn lọ́wọ́. Àwọn olùkọ́ tó lọ́kàn tó dáa máa ń gbà pé àwọn tó múra tán láti kẹ́kọ̀ọ́ kì í ṣe abánidíje, àmọ́ wọ́n jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀,” wọ́n sì jẹ́ ẹ̀bùn iyebíye fún ìjọ. (2 Kọ́r. 1:24; Héb. 13:16) Ẹ wo bí inú àwọn olùkọ́ tí kò mọ tara wọn nìkan yìí ṣe máa dùn tó nígbà tí wọ́n bá ń kíyè sí bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣe ń lo ẹ̀bùn tí wọ́n ní lọ́nà tó máa ṣe ìjọ láǹfààní!—Ìṣe 20:35.

      18, 19. Báwo ni alàgbà kan ṣe lè múra ọkàn akẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀, kí sì nìdí tí ìyẹn fi ṣe pàtàkì?

      18 Má ṣe jẹ́ olùkọ́ nìkan, di ọ̀rẹ́ wọn. Ní ọjọ́ tí Sámúẹ́lì pàdé Sọ́ọ̀lù, wòlíì náà lè mú ṣágo òróró, kó sì yára tú u sórí Sọ́ọ̀lù, lẹ́yìn náà kó ní kí ọba tuntun náà máa lọ. Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, Sọ́ọ̀lù á di ọba lóòótọ́, àmọ́ kò ní mọ iṣẹ́ tó gbà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Sámúẹ́lì fara balẹ̀ múra ọkàn Sọ́ọ̀lù sílẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Lẹ́yìn tí wọ́n jẹ oúnjẹ aládùn, tí wọ́n rìnrìn gbẹ̀fẹ́, tí wọ́n sọ̀rọ̀ dáadáa, tí wọ́n sì sùn di ọjọ́ kejì ni wòlíì náà tó gbà pé àkókò ti tó láti fi òróró yan Sọ́ọ̀lù.

      Alàgbà àti ìránṣẹ́ òjíṣẹ́ kan jọ ń sọ̀rọ̀

      Tí a bá fẹ́ kọ́ àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́, ó yẹ kí á kọ́kọ́ mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́

      (Wo ìpínrọ̀ 18 àti 19)

      19 Bákan náà lónìí, kí olùkọ́ tó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ ó yẹ kó mú kí ara tu akẹ́kọ̀ọ́ náà kó sì mú un lọ́rẹ̀ẹ́. Àwọn ìgbésẹ̀ tí alàgbà kan máa gbé kó tó lè di ọ̀rẹ́ ẹni tó fẹ́ kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ máa ń yàtọ̀ láti ibì kan sí ibòmíì, ó máa sinmi lórí ipò kálukú àti àṣà wọn. Síbẹ̀, ibi yòówù kó o máa gbé, tó o bá ń wáyè láti wà pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́ kan bó tiẹ̀ jẹ́ pé ojúṣe rẹ gẹ́gẹ́ bí alàgbà máa ń mú kí ọwọ́ rẹ dí, ohun tó ò ń sọ fún akẹ́kọ̀ọ́ náà ni pé: “Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ mí lógún gan-an ni.” (Ka Róòmù 12:10.) Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé ibi yòówù kó o máa gbé, àwọn tó múra tán láti kẹ́kọ̀ọ́ á mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn, wọ́n á sì mọyì rẹ̀ gan-an.

      20, 21. (a) Irú olùkọ́ wo ni o lè sọ pé ó kẹ́sẹ járí? (b) Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e?

      20 Ó yẹ kí ẹ̀yin alàgbà rántí pé: Yàtọ̀ sí pé olùkọ́ tó kẹ́sẹ járí máa ń fẹ́ dá ẹlòmíì lẹ́kọ̀ọ́, ó tún máa nífẹ̀ẹ́ ẹni tó ń dá lẹ́kọ̀ọ́. (Fi wé Jòhánù 5:20.) Kò ní pẹ́ rárá tí akẹ́kọ̀ọ́ náà á fi rí i pé olùkọ́ náà nífẹ̀ẹ́ òun, èyí sì máa jẹ́ kí ohun tó ń kọ́ wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an. Nítorí náà, ẹ̀yin alàgbà, bí ẹ ṣe ń dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́, ẹ má ṣe jẹ́ olùkọ́ nìkan, ẹ di ọ̀rẹ́ wọn.—Òwe 17:17; Jòh. 15:15.

      21 Lẹ́yìn tí alàgbà kan bá ti múra ọkàn akẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀, ohun tó kàn ni pé kó kọ́ ọ láwọn nǹkan tó yẹ kó mọ̀. Ọ̀nà wo ni alàgbà náà lè gbé e gbà? Èyí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.

      a Àwọn alàgbà ni a dìídì kọ àpilẹ̀kọ yìí àti èyí tó tẹ̀ lé e fún, àmọ́ gbogbo wa nínú ìjọ ló yẹ ká fún ohun tá a fẹ́ jíròrò láfiyèsí. Kí nìdí? Ó máa jẹ́ kí gbogbo àwọn ọkùnrin tó ti ṣèrìbọmi mọ̀ pé ó yẹ káwọn gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ kí wọn bàa lè ṣèrànwọ́ láti bójú tó iṣẹ́ nínú ìjọ. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí sì máa wá ṣe gbogbo èèyàn láǹfààní.

      b Àwọn alàgbà tá a fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò wá láti Amẹ́ríkà, Bangladesh, Belgium, Brazil, Faransé, French Guiana, Japan, Kòríà, Mẹ́síkò, Nàìjíríà, Nàmíbíà, Ọsirélíà, Réunion, Rọ́ṣíà àti South Africa.

      Iṣẹ́ Tó Pọn Dandan

      Alàgbà kan tó ń sìn níbi tí àìní pọ̀ sí ń dá àwọn arákùnrin lẹ́kọ̀ọ́ láti di olùṣọ́ agbo Ọlọ́run

      LÁWỌN ibì kan láyé, ọ̀pọ̀ ìjọ máa ń ní àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè míì láti sìn níbi tí àìní pọ̀ sí. Iṣẹ́ kékeré kọ́ làwọn Ẹlẹ́rìí tó yọ̀ǹda ara wọn yìí ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìkórè tẹ̀mí. Àmọ́, kí ló máa ṣẹlẹ̀ ká sọ pé àwọn tó ń ṣiṣẹ́ kára láti wàásù Ìjọba Ọlọ́run yìí kúrò ní orílẹ̀-èdè tí wọ́n lọ ṣèrànwọ́ fún? Ọ̀pọ̀ ìjọ ni kò ní ní àwọn arákùnrin tó tóótun tó pọ̀ tó láti bójú tó àwọn ojúṣe tó wà nínú ìjọ. Nítorí náà, ó pọn dandan pé kí àwọn alàgbà tó ń sìn láwọn àgbègbè tí àìní pọ̀ sí ran àwọn arákùnrin tó wà ní irú àwọn àgbègbè bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè di alábòójútó agbo Ọlọ́run.

  • Bí Àwọn Alàgbà Ṣe Ń Kọ́ Àwọn Míì Kí Wọ́n Lè Tóótun
    Ilé Ìṣọ́—2015 | April 15
    • Èlíṣà ń wo bí Èlíjà ṣe fi ẹ̀wù oyè rẹ̀ lu Odò Jọ́dánì tó sì pín sí méjì

      Bí Àwọn Alàgbà Ṣe Ń Kọ́ Àwọn Míì Kí Wọ́n Lè Tóótun

      “Àwọn nǹkan tí ìwọ sì ti gbọ́ lọ́dọ̀ mi . . . , fi lé àwọn olùṣòtítọ́ lọ́wọ́.”—2 TÍM. 2:2.

      KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

      • Àwọn ọ̀nà wo ni alàgbà kan lè gbà ran arákùnrin kan lọ́wọ́ kó lè lókun nípa tẹ̀mí?

      • Tí arákùnrin kàn kò bá fẹ́ gba àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kankan nínú ìjọ, àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo la lè fi tún èrò rẹ̀ ṣe?

      • Báwo ni àwọn tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Èlíṣà?

      1. (a) Kí làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti mọ̀ tipẹ́tipẹ́ nípa ìdálẹ́kọ̀ọ́, kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì lónìí? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

      TIPẸ́TIPẸ́ làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti mọ̀ pé ìdálẹ́kọ̀ọ́ máa ń mú kéèyàn ṣàṣeyọrí. Nígbà tí Ábúrámù, baba ńlá ìgbàanì fẹ́ lọ dá Lọ́ọ̀tì nídè, ó “pe àwọn ọkùnrin tí ó ti kọ́ jọ,” wọ́n sì ṣàṣeyọrí. (Jẹ́n. 14:14-16) Nígbà tí Dáfídì Ọba wà láyé, àwọn “tí a kọ́ ní iṣẹ́ orin kíkọ sí Jèhófà” ló ń kọrin ní ilé Ọlọ́run, wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo. (1 Kíró. 25:7) Lónìí, à ń bá Sátánì àtàwọn tó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn jagun tẹ̀mí. (Éfé. 6:11-13) Bákan náà, à ń ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe ká lè fi ìyìn fún Jèhófà. (Héb. 13:15, 16) Nítorí náà, bíi ti àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà àtijọ́, ìdálẹ́kọ̀ọ́ ṣe pàtàkì ká bàa lè ṣàṣeyọrí. Nínú ìjọ, àwọn alàgbà ni Jèhófà gbé iṣẹ́ kíkọ́ àwọn ẹlòmíì lé lọ́wọ́. (2 Tím. 2:2) Àwọn ọ̀nà wo ni àwọn alàgbà tó nírìírí ń gbà kọ́ àwọn arákùnrin kí wọ́n lè tóótun láti bójú tó agbo Ọlọ́run?

      RAN AKẸ́KỌ̀Ọ́ LỌ́WỌ́ KÓ LÈ LÓKUN NÍPA TẸ̀MÍ

      2. Kí ló yẹ kí alàgbà kan ṣe kí ó tó kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ kan, kí sì nìdí?

      2 A lè fi ẹ̀yin alàgbà wé àgbẹ̀ kan. Kí àgbẹ̀ kan tó gbin irúgbìn sóko rẹ̀, ó lè rí i pé ó yẹ kí òun fi ajílẹ̀ sí inú ilẹ̀ tó fẹ́ gbin nǹkan sí kí àwọn irè oko rẹ̀ lè so dáadáa. Bákan náà, kí o tó dá arákùnrin kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní ìrírí lẹ́kọ̀ọ́, o lè rí i pé ó máa dáa tí o bá kọ́kọ́ ṣàlàyé àwọn ẹsẹ Bíbélì kan tó máa jẹ́ kí ẹ̀kọ́ náà wọ̀ ọ́ lọ́kàn kó sì túbọ̀ fi ẹ̀kọ́ náà sílò.—1 Tím. 4:6.

      3. (a) Báwo ni a ṣe lè lo ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Máàkù 12:29, 30 tá a bá ń bá akẹ́kọ̀ọ́ kan sọ̀rọ̀? (b) Ipa wo ni àdúrà tí alàgbà kan bá gbà lè ní lórí akẹ́kọ̀ọ́?

      3 Tó o bá fẹ́ mọ bí akẹ́kọ̀ọ́ kan ṣe ń jẹ́ kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ Ìjọba náà darí èrò àti ìṣe rẹ̀ tó, o lè bíi pé, ‘Báwo ni bó o ṣe ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà ṣe ti yí ọ̀nà tó o gbà ń gbé ìgbésí ayé rẹ pa dà?’ Ìbéèrè yẹn lè jẹ́ kẹ́ ẹ bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò tó gbámúṣé nípa ìdí tí a fi ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ wa tọkàntọkàn. (Ka Máàkù 12:29, 30.) Ní ìparí ọ̀rọ̀ yín ẹ lè gbàdúrà pa pọ̀, kó o sì bẹ Jèhófà pé kó fún akẹ́kọ̀ọ́ náà ní ẹ̀mí mímọ́ tó nílò kó lè ṣàṣeyọrí lẹ́nu ìdálẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Bí arákùnrin náà ṣe ń gbọ́ tó ò ń gbàdúrà látọkàn wá nítorí rẹ̀ máa fún un níṣìírí gan-an ni.

      4. (a) Àwọn àpẹẹrẹ wo ló wà nínú Bíbélì tó máa ran akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ kó lè tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí? (b) Kí ni àwọn alàgbà máa ń fẹ ṣe tí wọ́n bá ń dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́?

      4 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà, jíròrò àwọn àkọsílẹ̀ Bíbélì kan tó máa jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ náà rí ìdí tó fi yẹ kí òun múra tán láti kẹ́kọ̀ọ́, kó ṣeé gbára lé, kó sì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. (1 Ọba 19:19-21; Neh. 7:2; 13:13; Ìṣe 18:24-26) Ó ṣe pàtàkì pé kí akẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn ìwà yẹn bó ṣe ṣe pàtàkì pé kí àgbẹ̀ fi ajílẹ̀ sílẹ̀ tó fẹ́ fi dáko. Wọ́n máa jẹ́ kó tètè tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Alàgbà kan tó ń jẹ́ Jean-Claude, láti orílẹ̀-èdè Faransé sọ pé: “Tí mo bá ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́, mo máa ń fẹ́ ran ẹni náà lọ́wọ́ kó lè di ẹni tí nǹkan tẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn. Mo máa ń rí i pé a jọ ka àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtó kan tó máa ‘la ojú’ akẹ́kọ̀ọ́ náà sí ‘àwọn ohun àgbàyanu’ tó wà nínú Bíbélì.” (Sm. 119:18) Àwọn nǹkan míì wo la lè ṣe láti ran akẹ́kọ̀ọ́ kan lọ́wọ́ kó lè lókun nípa tẹ̀mí?

      DÁBÀÁ ÀWỌN ÀFOJÚSÙN KÓ O SÌ SỌ ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ

      5. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká jíròrò àwọn àfojúsùn tẹ̀mí pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́ kan? (b) Kí nìdí tó fi yẹ káwọn alàgbà dá àwọn tó ṣì kéré lẹ́kọ̀ọ́? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

      5 O lè bi akẹ́kọ̀ọ́ kan pé, ‘Àwọn nǹkan wo lo fi ṣe àfojúsùn rẹ nípa tẹ̀mí?’ Bí kò bá tíì ní àfojúsùn kan pàtó, ràn án lọ́wọ́ kó lè yan ọ̀kan tí agbára rẹ̀ ká tí ọwọ́ rẹ̀ sì lè tẹ̀. Sọ ohun kan pàtó tó o fi ṣe àfojúsùn rẹ nígbà kan rí, kó o sì fi ọ̀yàyà sọ bí inú rẹ ṣe dùn tó nígbà tí ọwọ́ rẹ tẹ̀ ẹ́. Lóòótọ́, ó lè dà bíi pé àbá yìí kò ṣòro rárá, síbẹ̀ ó gbéṣẹ́ gan-an ni. Alàgbà kan tó tún jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nílẹ̀ Áfíríkà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Victor, sọ pé: “Nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́, alàgbà kan bi mí láwọn ìbéèrè mélòó kan tó ń múni ronú jinlẹ̀ nípa àwọn nǹkan tí mo fi ṣe àfojúsùn mi. Àwọn ìbéèrè yẹn ló jẹ́ kí n bẹ̀rẹ̀ sí í ronú gan-an nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi.” Àwọn alàgbà tó nírìírí tún sọ pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká bẹ̀rẹ̀ sí í dá àwọn arákùnrin lẹ́kọ̀ọ́ nígbà tí wọ́n ṣì wà lọ́dọ̀ọ́, pàápàá tí wọ́n bá ti ń lé lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá. Ìyẹn gba pé ká máa fún wọn níṣẹ́ tó bá ọjọ́ orí wọn mu. Tí a bá tètè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ọmọ lẹ́kọ̀ọ́, nígbà tí wọ́n bá fi máa pé ọmọ ogún ọdún, àwọn àfojúsùn tẹ̀mí ni wọ́n á máa lépa dípò àwọn nǹkan ayé tó sábà máa ń pín ọkàn àwọn ọ̀dọ́ níyà.—Ka Sáàmù 71:5, 17.a

      Ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, alàgbà kan ń ṣàlàyé ìdí tó fi ṣe pàtàkì ká ṣe àwọn iṣẹ́ kan fún arákùnrin ọ̀dọ́ kan

      Ṣàlàyé ìdí tí iṣẹ́ náà fi ṣe pàtàkì, kó o sì gbóríyìn fún bó ṣe ń sapá láti ṣe iṣẹ́ náà (Wo ìpínrọ̀ 5 sí 8)

      6. Kí ni ohun pàtàkì kan tí Jésù máa ń ṣe tó bá ń dáni lẹ́kọ̀ọ́?

      6 Ohun míì tó o lè ṣe kó lè wu akẹ́kọ̀ọ́ kan láti ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn ni pé kó o ṣàlàyé ohun tó yẹ kó ṣe àti ìdí tó fi yẹ kó ṣe é. Tó o bá ń sọ ìdí tó fi yẹ kí akẹ́kọ̀ọ́ ṣe àwọn nǹkan kan, ńṣe lò ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, Olùkọ́ Ńlá náà. Bí àpẹẹrẹ, kí Jésù tó gbé iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn lé àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lọ́wọ́, ó sọ ìdí tó fi yẹ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé: “Gbogbo ọlá àṣẹ ni a ti fi fún mi ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.” Ó wá fi kún un pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mát. 28:18, 19) Báwo lo ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tó o bá ń dáni lẹ́kọ̀ọ́?

      7, 8. (a) Báwo làwọn alàgbà ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tí wọ́n bá ń kọ́ àwọn ẹlòmíì? (b) Báwo ló ṣe ṣe pàtàkì tó pé ká máa gbóríyìn fún akẹ́kọ̀ọ́? (d) Àwọn àbá wo ló lè ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ tí wọ́n bá ń kọ́ àwọn ẹlòmíì? (Wo àpótí náà “Bá A Ṣe Lè Dá Àwọn Míì Lẹ́kọ̀ọ́.”)

      7 Ṣàlàyé ìdí tí ohun tó o ní kí akẹ́kọ̀ọ́ kan ṣe fi bá Ìwé Mímọ́ mu. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe lò ń kọ́ ọ láti máa ronú lórí àwọn ìlànà Bíbélì nínú ohun gbogbo tó bá ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ká sọ pé o ní kí arákùnrin kan máa rí i pé kò sí ohunkóhun tó lè ṣèpalára fáwọn èèyàn lẹ́nu ọ̀nà Gbọ̀ngàn Ìjọba, kí ibẹ̀ sì máa wà ní mímọ́ tónítóní. O lè ka Títù 2:10, kó o wá ṣàlàyé fún un pé bó ṣe ń bójú tó ẹnu ọ̀nà Gbọ̀ngàn Ìjọba ń “ṣe ẹ̀kọ́ Olùgbàlà wa, Ọlọ́run, lọ́ṣọ̀ọ́.” Bákan náà, sọ pé kí akẹ́kọ̀ọ́ náà ronú nípa àwọn àgbàlagbà tó wà nínú ìjọ àti bí wọ́n ṣe máa jàǹfààní tó bá ń ṣe ojúṣe rẹ̀. Tá a bá ní irú ìjíròrò yìí pẹ̀lú ẹni tá à ń dá lẹ́kọ̀ọ́, á jẹ́ kó máa ronú nípa àǹfààní tí iṣẹ́ rẹ̀ máa ṣe ìjọ dípò kó máa ronú nípa ìtọ́ni tá a fun. Inú rẹ̀ máa dùn bó ṣe ń rí i pé àwọn ará ń jàǹfààní nínú iṣẹ́ tó ń bójú tó.

      8 Síwájú sí i, rí i pé ò ń gbóríyìn fún akẹ́kọ̀ọ́ náà bó ṣe ń sapá láti fi àwọn nǹkan tó ń kọ́ sílò. Báwo nìyẹn ti ṣe pàtàkì tó? Omi máa ń mú kí irúgbìn dàgbà. Lọ́nà kan náà, tí a bá ń gbóríyìn fún akẹ́kọ̀ọ́ ó máa jẹ́ kó dàgbà nípa tẹ̀mí.—Fi wé Mátíù 3:17.

      ÌPÈNÍJÀ MÍÌ

      9. (a) Ìṣòro wo ni àwọn alàgbà kan tó ń gbé láwọn orílẹ̀-èdè tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù máa ń kojú tí wọ́n bá fẹ́ dáni lẹ́kọ̀ọ́? (b) Kí nìdí tí àwọn ọ̀dọ́kùnrin kan ò ṣe fi ìjọsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́ ní ìgbésí ayé wọn?

      9 Àwọn alàgbà tó wà ní àwọn orílẹ̀-èdè tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù lè kojú ìpèníjà míì: Ìyẹn bí wọ́n ṣe máa ṣèrànwọ́ fún àwọn arákùnrin tó ti lé lọ́mọ ogún ọdún tàbí ọgbọ̀n ọdún tí wọ́n sì ti ṣèrìbọmi kí wọ́n lè gba àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ. A béèrè lọ́wọ́ àwọn alàgbà onírìírí tó wá láti ilẹ̀ tí ó tó ogún [20] ní Yúróòpù àti Amẹ́ríkà ohun tí wọ́n rò pé ó fàá tí àwọn ọ̀dọ́ kan kì í fẹ́ gba àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ. Púpọ̀ nínú wọn ló sọ pé: Nígbà tí àwọn ọ̀dọ́ kan ń dàgbà, kò sẹ́ni tó fún wọn níṣìírí láti fi àwọn nǹkan tẹ̀mí ṣe àfojúsùn wọn. Kódà, nígbà táwọn ọ̀dọ́ kan fẹ́ fi ohun tẹ̀mí ṣe àfojúsùn wọn, ńṣe làwọn òbí wọn rọ̀ wọ́n láti kàwé dáadáa kí wọ́n lè ríṣẹ́ gidi ṣe! Irú àwọn ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ kò fi ìjọsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́ ní ìgbésí ayé wọn.—Mát. 10:24.

      10, 11. (a) Báwo ni alàgbà kan ṣe lè rọra tún èrò arákùnrin kan ṣe tó bá jọ pé kò fẹ́ gba àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kankan nínú ìjọ? (b) Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ni alàgbà náà lè jíròrò pẹ̀lú arákùnrin náà, kí sì nìdí? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

      10 Tó bá jọ pé arákùnrin kan kò fẹ́ gba àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kankan nínú ìjọ, ó máa gba ọ̀pọ̀ ìsapá àti sùúrù kẹ́ ẹ tó lè tún èrò rẹ̀ ṣe, àmọ́ kì í ṣe ohun tí kò ṣeé ṣe. Bí àgbẹ̀ ṣe máa ń rọra lọ́ okùn iṣu mọ́ igi kí iṣu náà lè ta dáadáa, bẹ́ẹ̀ lo ṣe lè fara balẹ̀ ran àwọn arákùnrin kan lọ́wọ́ kí wọ́n lè gbà láti ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ. Báwo lo ṣe lè ṣe é?

      11 Wá àyè láti di ọ̀rẹ́ arákùnrin tó ò ń dá lẹ́kọ̀ọ́ náà. Jẹ́ kó mọ̀ pé a nílò rẹ̀ nínú ìjọ. Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, ẹ jọ jókòó sọ̀rọ̀, kí ẹ ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan pàtó, kó o sì ràn án lọ́wọ́ láti ronú nípa ìyàsímímọ́ rẹ̀ sí Jèhófà. (Oníw. 5:4; Aísá. 6:8; Mát. 6:24, 33; Lúùkù 9:57-62; 1 Kọ́r. 15:58; 2 Kọ́r. 5:15; 13:5) O lè bi í pé, ‘Ìlérí wo lo ṣe fún Jèhófà nígbà tó o ya ara rẹ sí mímọ́ fún un?’ Kó o lè dé ọkàn rẹ̀, o lè bi í pé, ‘Báwo lo ṣe rò pé ó rí lára Jèhófà nígbà tó o ṣe ìrìbọmi?’ (Òwe 27:11) ‘Báwo ló ṣe rí lára Sátánì?’ (1 Pét. 5:8) Má ṣe fojú kéré ipa tí àwọn ẹsẹ Bíbélì tó o fara balẹ̀ yàn tó o sì kà fún arákùnrin náà lè ní lórí rẹ̀.—Ka Hébérù 4:12.b

      Ẹ̀YIN AKẸ́KỌ̀Ọ́, Ẹ JẸ́ OLÓÒÓTỌ́

      12, 13. (a) Irú ìwà wo ni Èlíṣà hù nígbà tó ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Èlíjà? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe bù kún Èlíṣà nítorí ìṣòtítọ́ rẹ̀?

      12 Ẹ̀yin ọ̀dọ́, a nílò yín nínú ìjọ! Nítorí náà, àwọn ìwà wo ló máa jẹ́ kẹ́ ẹ lè ṣàṣeyọrí? Láti wá ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn, ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ẹnì kan nígbà àtijọ́ tí òun náà jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́.

      13 Ní nǹkan tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọdún sẹ́yìn, wòlíì Èlíjà ní kí Èlíṣà tó jẹ́ ọ̀dọ́ di ìránṣẹ́ òun. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Èlíṣà gbà láti di ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì fi ìṣòtítọ́ sin bàbá àgbàlagbà yìí nípa bíbá a ṣe àwọn iṣẹ́ tí kò jọjú. (2 Ọba 3:11) Lẹ́yìn tí Èlíṣà ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ fún nǹkan bí ọdún mẹ́fà, ó gbọ́ pé iṣẹ́ Èlíjà ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì máa tó dópin. Èlíjà wá sọ fún alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀ tó ti dá lẹ́kọ̀ọ́ dáadáa yìí pé kó má tẹ̀ lé òun mọ́. Àmọ́, ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Èlíṣà sọ fún Èlíjà pé: “Èmi kí yóò fi ọ́ sílẹ̀.” Ó ṣe tán láti dúró ti ọ̀gá rẹ̀ tó bá ṣì ṣeé ṣe. Nítorí Èlíṣà jẹ́ olóòótọ́ tó sì dúró ti ọ̀gá rẹ̀ gbágbáágbá Jèhófà bù kún un, ó jẹ́ kó rí ìgbà tí Èlíjà lọ lọ́nà ìyanu.—2 Ọba 2:1-12.

      14. (a) Báwo ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lónìí ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Èlíṣà? (b) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ olóòótọ́?

      14 Báwo lo ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Èlíṣà lónìí? Jẹ́ kó máa yá ẹ lára láti gba iṣẹ́ tí wọ́n bá fún ẹ, títí kan àwọn iṣẹ́ tí kò jọjú. Mú olùkọ́ rẹ lọ́rẹ̀ẹ́, kó o sì jẹ́ kó mọ̀ pé o mọyì bó ṣe ń sapá láti kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́. Ńṣe ni ìwà rere tó o bá hù máa dà bí ìgbà tó ò ń sọ fún un pé: “Èmi kí yóò fi ọ́ sílẹ̀.” Ju gbogbo rẹ̀ lọ, máa fi ìṣòtítọ́ bójú tó iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá fún ẹ. Kí nìdí tí ìyẹn fi ṣe pàtàkì? Ìdí ni pé, lẹ́yìn tí àwọn alàgbà bá a rí i pé o jẹ́ olóòótọ́ tó o sì ṣeé fọkàn tán ni ọkàn wọn á tó balẹ̀ pé Jèhófà fẹ́ kí wọ́n fún ẹ ní àfikún iṣẹ́ nínú ìjọ.—Sm. 101:6; ka 2 Tímótì 2:2.

      FI Ọ̀WỌ̀ TÓ YẸ HÀN

      15, 16. (a) Àwọn ọ̀nà wo ni Èlíṣà gbà bọ̀wọ̀ fún olùkọ́ rẹ̀? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Kí ni Èlíṣà ṣe tó fi ọkàn àwọn wòlíì tó kù balẹ̀?

      15 Ohun tí Bíbélì sọ nípa Èlíṣà tó gbaṣẹ́ lọ́wọ́ Èlíjà tún jẹ́ ká rí bó ṣe yẹ kí àwọn arákùnrin lónìí máa bọ̀wọ̀ fún àwọn alàgbà tó nírìírí. Lẹ́yìn tí Èlíjà àti Èlíṣà lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn wòlíì kan nílùú Jẹ́ríkò, àwọn méjèèjì rìn lọ sí Odò Jọ́dánì. Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, “Èlíjà mú ẹ̀wù oyè rẹ̀, ó sì ká a, ó sì lu omi náà, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó pín.” Lẹ́yìn tí wọ́n ti rìn la àárín odò tó ti gbẹ náà kọjá, àwọn méjèèjì “ń sọ̀rọ̀ bí wọ́n ti ń rìn.” Ó ṣe kedere pé, Èlíṣà kò ronú pé òun ti mọ gbogbo nǹkan tán. Títí Èlíjà fi lọ, Èlíṣà fetí sí gbogbo ohun tí olùkọ́ rẹ̀ ń sọ. Lẹ́yìn náà, ìjì ẹlẹ́fùúùfù gbé Èlíjà lọ. Nígbà tí Èlíṣà pa dà dé Odò Jọ́dánì, ó fi ẹ̀wù Èlíjà lu odò náà, ó sì kígbe pé: “Jèhófà Ọlọ́run Èlíjà dà?” Lẹ́ẹ̀kan sí i, odò náà pín sí méjì.—2 Ọba 2:8-14.

      16 Ǹjẹ́ o kíyè sí i pé iṣẹ́ ìyanu àkọ́kọ́ tí Èlíṣà ṣe kò yàtọ̀ rárá sí iṣẹ́ ìyanu tí Èlíjà ṣe gbẹ̀yìn? Kí nìdí tí ìyẹn fi ṣe pàtàkì? Ó jọ pé Èlíṣà kò ronú pé ní báyìí tí òun ti wà nípò àṣẹ, ó yẹ kí òun yí àwọn nǹkan kan pa dà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, bó ṣe ń bá a nìṣó láti ṣe iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ bí Èlíjà ṣe máa ń ṣe é fi hàn pé ó bọ̀wọ̀ fún olùkọ́ rẹ̀, ìyẹn sì jẹ́ kí ọkàn àwọn wòlíì yòókù balẹ̀. (2 Ọba 2:15) Ọgọ́ta [60] ọdún ni Èlíṣà fi ṣe iṣẹ́ wòlíì, Jèhófà sì lò ó láti ṣe iṣẹ́ ìyanu tó pọ̀ gan-an ju ti Èlíjà lọ. Ẹ̀kọ́ wo ni ìtàn yìí kọ́ ẹ̀yin akẹ́kọ̀ọ́ lónìí?

      17. (a) Ọ̀nà wo ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lè gbà fìwà jọ Èlíṣà lónìí? (b) Bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ọ̀nà wo ni Jèhófà lè gbà lo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ olóòótọ́?

      17 Má ṣe ronú pé gbàrà tí wọ́n bá ti fún ẹ láwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan nínú ìjọ lo gbọ́dọ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí í yí nǹkan pa dà, kó o wá máa ṣe nǹkan lọ́nà tó yàtọ̀ pátápátá sí bí wọ́n ṣe ń ṣe é tẹ́lẹ̀. Ìwọ kọ́ lo máa pinnu ìgbà tó yẹ kí nǹkan yí pa dà. Ohun tí ìjọ nílò àti ìtọ́ni tá a bá rí gbà látọ̀dọ̀ ètò Jèhófà ló máa jẹ́ ká mọ ìgbà tó yẹ kí ìyípadà wáyé. Ohun tí Èlíṣà ṣe fi àwọn wòlíì tó kù lọ́kàn balẹ̀, ó ń bá a nìṣó láti ṣe nǹkan bí Èlíjà ṣe máa ń ṣe é tó fi hàn pé ó bọ̀wọ̀ fún Èlíjà tó gbaṣẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Ìwọ náà lè fìwà jọ Èlíṣà tó o bá jẹ́ kí ọkàn àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ onígbàgbọ́ balẹ̀, tó o sì ń bọ̀wọ̀ fún àwọn alàgbà onírìírí nípa ṣíṣe nǹkan lọ́nà tí wọ́n gbà ń ṣe é tí kò sì ta ko ìlànà Bíbélì. (Ka 1 Kọ́ríńtì 4:17.) Àmọ́, bí o ṣe ń ní ìrírí sí i, ó dájú pé ìwọ̀ náà á wà lára àwọn tó ń ran ìjọ lọ́wọ́ láti ṣe àwọn àyípadà táá jẹ́ kí wọ́n lè máa bá ètò Jèhófà tó ń tẹ̀ síwájú rìn. Kódà, bíi ti Èlíṣà, Jèhófà ṣì lè lo ẹ̀yin akẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ olóòótọ́ láti ṣe àwọn iṣẹ́ tó pọ̀ ju èyí tí àwọn olùkọ́ yín ṣe lọ.—Jòh. 14:12.

      18. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì gan-an pé kí a dá àwọn arákùnrin tó wà nínú ìjọ lẹ́kọ̀ọ́ lónìí?

      18 A retí pé àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí àti èyí tó ṣáájú rẹ̀ máa mú kí àwọn alàgbà máa wáyè láti dá àwọn ẹlòmíì lẹ́kọ̀ọ́. Ǹjẹ́ kí àwọn arákùnrin tó tóótun múra tán láti gba irú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ kí wọ́n sì fi ọgbọ́n lò ó bí wọ́n ṣe ń bójú tó àwọn àgùntàn Jèhófà. Tí wọ́n bá ṣè bẹ́ẹ̀, ó máa fún gbogbo ìjọ kárí ayé lókun, á sì ran ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lọ́wọ́ láti jẹ́ olóòótọ́ lákòókò táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì máa wáyé lọ́jọ́ iwájú.

      a Bí ọ̀dọ́kùnrin kan bá fi hàn pé òun dàgbà nípa tẹ̀mí, tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, tó sì dójú ìlà ohun tí Ìwé Mímọ́ béèrè, àwọn alàgbà lè dámọ̀ràn rẹ̀ láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kódà bí kò bá tíì pé ọmọ ogún ọdún.—1 Tím. 3:8-10, 12; wo Ilé Ìṣọ́nà July 1, 1989, ojú ìwé 29.

      b Nínú ìjíròrò rẹ o lè lo àwọn kókó tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ April 15, 2012, ojú ìwé 14 sí 16, ìpínrọ̀ 8 sí 13 àti ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’ orí 16, ìpínrọ̀ 1 sí 3.

      Bá A Ṣe Lè Dá Àwọn Míì Lẹ́kọ̀ọ́

      ÀWỌN alàgbà tó ti ṣàṣeyọrí nínú dídá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ dá àwọn àbá tó tẹ̀ lé e yìí:

      1. Máa fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe.

      2. Gba akẹ́kọ̀ọ́ náà níyànjú pé kó ka Bíbélì látìbẹ̀rẹ̀ dópin láàárín ọdún kan kó lè túbọ̀ ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà.

        Alàgbà kan ń dá ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan lẹ́kọ̀ọ́ lórí bó ṣe lè wàásù láwọn ibi tí èrò pọ̀ sí
      3. Ẹ jọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. (Wo àwòrán tó wà níwájú ìwé ìròyìn yìí.)

      4. Kọ́ ọ bó ṣe máa darí ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá lọ́nà rere.

        1. Alàgbà kan ń sọ àsọyé Bíbélì; 2. Alàgbà kan ń ran ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan lọ́wọ́; 3. Ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan ń sọ àsọyé Bíbélì
      5. Tó o bá ń sọ àsọyé Bíbélì, fún un ní ẹ̀dà ìwé àsọyé rẹ kó máa fojú bá a lọ, kó lè máa rí bó o ṣe gbé e kalẹ̀.

      6. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, o lè sọ pé kí òun àti ìdílé rẹ̀ wà níbi ìjọsìn ìdílé yín.

      7. Sọ pé kí òun àti ìdílé rẹ̀ bá ìwọ àti ìdílé rẹ lọ wàásù ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tá ò pín fún ìjọ èyíkéyìí tàbí ìpínlẹ̀ ìwàásù tí wọn kì í sábà wàásù níbẹ̀ déédéé.c

      c Àwọn alàgbà láti ilẹ̀ Áfíríkà, Amẹ́ríkà, Éṣíà, Ọsirélíà àti Yúróòpù ti lo àwọn àbá yìí, wọ́n sì ṣàṣeyọrí.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́