ORIN 101
À Ń Ṣiṣẹ́ Níṣọ̀kan
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Ọlọ́run ti yà wá sọ́tọ̀ - Nínú ayé burúkú yìí. - Ó fi wá sínú ètò rẹ̀ - Ká lè wà lálàáfíà. - À ń ṣiṣẹ́ níṣọ̀kan; - Ó dára, ó dùn! - Jèhófà ti yan Ọmọ rẹ̀ - Láti darí iṣẹ́ tá à ń ṣe. - A gbọ́dọ̀ jẹ́ onígbọràn. - Ká ṣiṣẹ́ nírẹ̀ẹ́pọ̀. 
- 2. À ń gbàdúrà s’Ọ́lọ́run pé - Kíṣọ̀kan gbilẹ̀ láàárín wa. - Yóò mú kífẹ̀ẹ́ wa gbòòrò sí i, - Ká sì túbọ̀ láyọ̀. - Àlàáfíà wa ń pọ̀ sí i, - Ó ń mára tù wá. - Jèhófà yóò máa bù kún wa - Bá a ṣe ń fi ìfẹ́ tòótọ́ hàn. - Yóò mú ká máa wà níṣọ̀kan. - A ó máa sìn ín títí láé. 
(Tún wo Míkà 2:12; Sef. 3:9; 1 Kọ́r. 1:10.)