ORIN 133
Sin Jèhófà Nígbà Ọ̀dọ́
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Jèhófà fẹ́ràn àwa ọ̀dọ́ gan-an. - Tọkàntọkàn sì la fi ń jọ́sìn rẹ̀. - Ó dájú pé ó ń fiyè síṣẹ́ wa, - Yóò sì bù kún wa jálẹ̀ ayé wa. 
- 2. Àwa ọ̀dọ́ ń bọ̀wọ̀ fún òbí wa, - A sì ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an. - Èyí ń jẹ́ kí inú wọn dùn sí wa, - A sì túbọ̀ ń sún mọ́ Jáà, Ọ̀rẹ́ wa. 
- 3. Káwa ọ̀dọ́ rántí Ọlọ́run wa. - Kí òtítọ́ máa jinlẹ̀ lọ́kàn wa. - Tá a bá fi ayé wa sin Jèhófà, - Inú rẹ̀ yóò dùn, yóò sì bù kún wa. 
(Tún wo Sm. 71:17; Ìdárò 3:27; Éfé. 6:1-3.)