ORIN 30
Bàbá Mi, Ọlọ́run Mi àti Ọ̀rẹ́ Mi
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Ìnira pọ̀ gan-an láyé. - Ó ń fa ẹkún àti ìrora. - Ṣùgbọ́n mo mọ̀ dájú pé, - “Asán kọ́ layé mi.” - (ÈGBÈ) - Olóòótọ́ ni Jèhófà. - Kò ní gbàgbé iṣẹ́ ìsìn mi. - Yóò sì máa wà pẹ̀lú mi, - Kò ní fi mí sílẹ̀ láéláé. - Jèhófà l’aláàbò mi, - aláàánú àti olùpèsè. - Bàbá mi ni, Ọ̀rẹ́ mi ni, - Ọlọ́run mi. 
- 2. Ìgbà ọ̀dọ́ mi ti lọ. - Ọjọ́ ogbó ti wá ńdé báyìí. - Síbẹ̀, mo nígbàgbọ́ pé - Ìrètí mi dájú. - (ÈGBÈ) - Olóòótọ́ ni Jèhófà. - Kò ní gbàgbé iṣẹ́ ìsìn mi. - Yóò sì máa wà pẹ̀lú mi, - Kò ní fi mí sílẹ̀ láéláé. - Jèhófà l’aláàbò mi, - aláàánú àti olùpèsè. - Bàbá mi ni, Ọ̀rẹ́ mi ni, - Ọlọ́run mi. 
(Tún wo Sm. 71:17, 18.)