ORIN 58
À Ń Wá Àwọn Ọ̀rẹ́ Àlàáfíà
- 1. Jésù pàṣẹ pé: ‘Ẹ wàásù òótọ́.’ - Lójò lẹ́ẹ̀rùn ló máa ń wàásù - látòwúrọ̀, tílẹ̀ fi ṣú. - Ó ń pe àwọn èèyàn níbi gbogbo. - Ó nífẹ̀ẹ́ wọn, ó sì ń kọ́ wọn - lọ́rọ̀ Ọlọ́run. - Nílé délé, lójú ọ̀nà, - À ń wàásù fún gbogbo èèyàn - Pé ìṣòro aráyé máa tó dópin. - (ÈGBÈ) - Kárí ayé, - À ń wá àwọn ọ̀rẹ́ àlàáfíà. - A sì tún ń wá - Àwọn èèyàn tó fẹ́ ìgbàlà. - Gbogbo ‘pá wa - Ni a máa sà. 
- 2. Ká tẹra mọ́ ‘wàásù, àkókò ń lọ, - Ká sì fi kún ìsapá wa - kọ́pọ̀ èèyàn lè rígbàlà. - Ìfẹ́ ló ń mú ká pa dà wá wọn lọ. - Ká lè ràn wọ́n lọ́wọ́, ká sì - tún ayé wọn ṣe. - Nílùú délùú, níbi gbogbo, - Tá a bá rẹ́ni tó gbọ́rọ̀ wa, - Inú wa máa ń dùn, a sì máa ń báṣẹ́ lọ. - (ÈGBÈ) - Kárí ayé, - À ń wá àwọn ọ̀rẹ́ àlàáfíà. - A sì tún ń wá - Àwọn èèyàn tó fẹ́ ìgbàlà. - Gbogbo ‘pá wa - Ni a máa sà. 
(Tún wo Àìsá. 52:7; Mát. 28:19, 20; Lúùkù 8:1; Róòmù 10:10.)