ORIN 157
Àlàáfíà Ayérayé!
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Ní inú ayé yìí, - Kò sí àlàáfíà, - Àmọ́, ọkàn tiwa balẹ̀. - A mọ̀ pé láìpẹ́, - Ayé tuntun máa dé - A ó sì máa fayọ̀ - kọrin pé: - (ÈGBÈ) - A fọpẹ́ fún Baba, - Àlàáfíà dé! - Ìtura dé sáyé! - Ìbẹ̀rù kò sí mọ́, - Ìbànújẹ́ tán - Àlàáfíà - ayérayé dé! 
- 2. Tíjọba Ọlọ́run - Bá gbàkóso - Kò ní sógun, kò sọ́tẹ̀ mọ́. - Gbogbo èèyàn máa - Wà ní àlàáfíà. - Kò ní síṣòro mọ́ láyé. - (ÈGBÈ) - A fọpẹ́ fún Baba, - Àlàáfíà dé! - Ìtura dé sáyé! - Ìbẹ̀rù kò sí mọ́, - Ìbànújẹ́ tán - Àlàáfíà - ayérayé dé! - (ÈGBÈ) - A fọpẹ́ fún Baba, - Àlàáfíà dé! - Ìtura dé sáyé! - Ìbẹ̀rù kò sí mọ́, - Ìbànújẹ́ tán - Ayé tuntun ti dé! - (ÈGBÈ) - A fọpẹ́ fún Baba, - Àlàáfíà dé! - Ìtura dé sáyé! - Ìbẹ̀rù kò sí mọ́, - Ìbànújẹ́ tán - Àlàáfíà - ayérayé dé! - Ó ti dé! 
(Tún wo Sm. 72:1-7; Àìsá. 2:4; Róòmù 16:20)