ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 10/8 ojú ìwé 28
  • Àwọn Jagunjagun Tẹ́lẹ̀ Tí Wọ́n Di Olùwá Àlàáfíà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Jagunjagun Tẹ́lẹ̀ Tí Wọ́n Di Olùwá Àlàáfíà
  • Jí!—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀ràn Ìbànújẹ́ ní Rwanda—Ẹ̀bi Ta Ni?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ǹjẹ́ O Fara Mọ́ Ọwọ́ Tí Ẹ̀sìn Fi Ń Mú Ọ̀rọ̀ Ogun?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Ogun
    Jí!—2017
  • Kí Ló Ṣẹlẹ̀ sí Ìfẹ́ Aládùúgbò?
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 10/8 ojú ìwé 28

Àwọn Jagunjagun Tẹ́lẹ̀ Tí Wọ́n Di Olùwá Àlàáfíà

ÌWÉ ìròyìn Jí! lédè Gẹ̀ẹ́sì, tó jáde ní December 8, 2002, gbé ìtàn Toshiaki Niwa, ọmọ ilẹ̀ Japan kan tó jẹ́ awakọ̀ òfuurufú jáde. Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, ó wà lára àwọn tí wọ́n kọ́ láti fi ọkọ̀ òfuurufú jagun, èyí tó gba pé kó lọ kú pẹ̀lú àwọn ọ̀tá tó máa pa. Niwa sọ pé lóṣù August ọdún 1945, òun wà ní ibùdó àwọn ọmọ ogun ojú òfuurufú tó wà nítòsí ìlú Kyoto níbi tóun ti ń dúró de ìgbà tí wọ́n máa pàṣẹ pé kóun lọ kọ lu àwọn ọkọ̀ ojú omi ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Wọn ò pàṣẹ yẹn ṣá, nítorí pé kò ju ọjọ́ mélòó kan sígbà yẹn tí ogun náà fi parí. Lọ́dún mélòó kan lẹ́yìn náà, Niwa bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó kẹ́kọ̀ọ́ pé àwọn tí wọ́n bá fẹ́ kí inú Ọlọ́run dùn sí àwọn kì í bá wọn dá sí ogun. Wọ́n ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún àwọn èèyàn bíi tiwọn, láìka ibì yòówù kí wọ́n máa gbé tàbí ọmọ orílẹ̀-èdè yòówù tí wọn ì báà jẹ́ sí. (1 Pétérù 2:17) Báyìí, Niwa tó jẹ́ jagunjagun tẹ́lẹ̀ ti wá di ẹni tó ń wá àlááfíà tó sì ń wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tó ń mú ìrẹ́pọ̀ wá fáwọn èèyàn.

Ìtàn Niwa wọ Russell Werts tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ́kàn gan-an nítorí pé òun náà jà fún orílẹ̀-èdè rẹ̀ nínú ogun yẹn. Nínú lẹ́tà tó kọ sí Niwa, ó ní: “O sọ pé ní oṣù August, ọdún 1945 o wà nítòsí ìlú Kyoto níbi tí o ti ń dúró de ìgbà tẹ́ ẹ máa kọ lu àwa ará ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Lákòókò yẹn gan-an, èmi náà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí mò ń gbà lórí bí màá ṣe kọlu àwọn ọ̀tá lọ́nà kan náà. Ká ní ogun náà kò parí nígbà tó parí yẹn ni, bóyá àwa méjèèjì ì bá ti bógun lọ níhà kìíní àti ìhà kejì. Gẹ́gẹ́ bíi ti ìwọ àti ìdílé rẹ, èmi àti ìyàwó mi náà di Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́yìn ìgbà náà. Ó jọni lójú pé àwa tá a jọ jẹ́ ọ̀tá bíi kíkú bíi yíyè tẹ́lẹ̀, tá à ń wá bá a ṣe máa pa ara wa dànù, la ti wá di ọ̀rẹ́ báyìí, kódà a ti di arákùnrin!”

Bíi ti Toshiaki Niwa àti Russell Werts, ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá paraku tẹ́lẹ̀ ti ń gbé pọ̀ báyìí ní àlááfíà àti ìṣọ̀kan nítorí pé wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì ti fi ohun tí wọ́n kọ́ ṣèwà hù. A rí àwọn Júù àtàwọn Lárúbáwá, àwọn Áméníà, àtàwọn Turk, àwọn ará Jámánì àtàwọn ará Rọ́ṣíà, àwọn Hutu àtàwọn Tutsi láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n fi hàn pé àwọn jẹ́ Kristẹni tòótọ́. Ńṣe ló dà bí ọ̀rọ̀ Jésù tó sọ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.”—Jòhánù 13:35.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Toshiaki Niwa àti Russell Werts rèé nígbà Ogun Àgbáyé Kejì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́