Ǹjẹ́ O Mọ̀?
(Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí wà nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí. Ẹ ó sì rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdáhùn níbi tí a tẹ̀ ẹ́ sí lójú ìwé 24. Bí ẹ bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn ìdáhùn yìí, ẹ wo ìwé “Insight on the Scriptures,” tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.)
1. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Júúdà ti fẹ́ láti kọ̀wé sí àwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ nípa ìgbàlà tí wọ́n jọ dì mú, kí ló rí i pé ó pọ̀n dandan pé kí òun kúkú ṣe? (Júúdà 3)
2. Ojú ọ̀nà abúlé wo ni Kíléópà àtàwọn tí wọ́n jọ ń rìn lọ wà nígbà tí Jésù Kristi tó ti gbé ara èèyàn wọ̀ fi dara pọ̀ mọ́ wọn? (Lúùkù 24:13-32)
3. Bí Bíbélì ṣe sọ, kí la fi kọ Òfin Mẹ́wàá sórí àwọn wàláà òkúta méjì? (Ẹ́kísódù 31:18)
4. Ọmọ orílẹ̀-èdè wo làwọn “ọ̀pọ̀lọpọ̀ aya ilẹ̀ òkèèrè” tí Sólómọ́nì fẹ́, tí wọ́n sì “tẹ ọkàn-àyà rẹ̀ láti tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn”? (1 Àwọn Ọba 11:1, 4)
5. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu, kí làwọn arákùnrin rẹ̀ ò ṣe nínú rẹ̀? (Jòhánù 7:5)
6. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé méjì lára àwọn ọmọ Dáfídì Ọba, Ábúsálómù àti Ádóníjà dìtẹ̀ láti fipá gorí ìtẹ́ baba wọn ní àkókò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ èwo nínú wọn ló kù díẹ̀ kó gbapò mọ́ ọn lọ́wọ́? (2 Sámúẹ́lì 16:15-22; 1 Àwọn Ọba 1:9-11, 38-53)
7. Báwo ni àwọn òkúta yìnyín ìṣàpẹẹrẹ tó ń já bọ́ nígbà tí áńgẹ́lì keje tú àwokòtò ìbínú Ọlọ́run jáde ṣe wúwo tó? (Ìṣípayá 16:21)
8. Kí ni Ìwé Mímọ́ sọ pé káwọn tó wà nínú ìjọ Kristẹni ṣe nígbà tí wọ́n bá yọ ẹnì kan lẹ́gbẹ́? (1 Kọ́ríńtì 5:11)
9. Nítorí ọlọ́run èké wo làwọn obìnrin Hébérù tí wọ́n di apẹ̀yìndà ṣe ń sunkún nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí? (Ìsíkíẹ́lì 8:14)
10. Kí nìdí tí Ágúrì tó kọ ìwé Òwe orí ọgbọ̀n fi béèrè pé kí Ọlọ́run ‘má ṣe fún òun ní ipò òṣì tàbí ti ọrọ̀’? (Òwe 30:8, 9)
11. Àmì wo ni Jèhófà fún Hesekáyà kó lè dá a lójú pé òun á wò ó sàn àti pé táwọn ará Ásíríà bá gbógun ti àwọn ará Jerúsálẹ́mù òun á gbèjà wọn? (Aísáyà 38:5-8)
12. Kí ni ará Samáríà tó jẹ́ aládùúgbò rere ṣe fún ọkùnrin tí wọ́n ti fẹ́rẹ̀ẹ́ lù pa tó rí lọ́nà Jẹ́ríkò? (Lúùkù 10:34)
13. Kí ni Ọlọ́run sọ pé káwọn àlùfáà àgbà ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì máa fi wérí? (Ẹ́kísódù 28:37)
14. Kí nìdí tí Ábúráhámù fi sọ nígbà méjì pé arábìnrin òun ni Sárà? (Jẹ́nẹ́sísì 12:19; 20:2)
15. Kí lorúkọ àwọn òkè ńlá méjì tí Jèhófà ti ní kí wọ́n máa súre fáwọn tó bá pa Òfin Ọlọ́run mọ́, àti èyí tí wọn ó ti máa fi àwọn tó bá rú òfin náà ré? (Diutarónómì 11:29)
16. Ìlú wo ni Sọ́ọ̀lù, ọba tó kọ́kọ́ jẹ ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ń gbé? (1 Sámúẹ́lì 10:24-26)
17. Kí lorúkọ ọba tó ju Dáníẹ́lì sínú ihò àwọn kìnnìún? (Dáníẹ́lì 6:9, 16)
Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè
1. Láti gbà wọ́n níyànjú “láti máa ja ìjà líle fún ìgbàgbọ́”
2. Ẹ́máọ́sì
3. “Ìka Ọlọ́run”
4. ‘Ọmọ Móábù, ọmọ Ámónì, ọmọ Édómù, ọmọ Sídónì àtàwọn ọmọ Hétì’
5. “Lo ìgbàgbọ́”
6. Ábúsálómù
7. “Tálẹ́ńtì kan” (tó fẹ́rẹ̀ẹ́ wúwo tó ìdajì àpò sìmẹ́ǹtì)
8. Kí wọ́n máà bá onítọ̀hún kẹ́gbẹ́
9. Támúsì
10. Kó má bàa sẹ́ Jèhófà bó bá di pé ọwọ́ ẹ̀ tẹ gbogbo ohun tó ń fẹ́, tàbí kó jalè kó sì sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ Ọlọ́run
11. Òjìji oòrùn tọsẹ̀ padà sẹ́yìn ní ìdásẹ̀lé mẹ́wàá ara àtẹ̀gùn Áhásì
12. Ó di àwọn ọgbẹ́ rẹ̀, ó gbé e lọ sí ilé èrò kan, ó sì ṣaájò rẹ̀
13. Láwàní
14. Nítorí ẹwà Sárà, ẹ̀rù ba Ábúráhámù pé Fáráò àti Ọba Ábímélékì lè pa òun kí wọ́n bàa lè fi ìyàwó òun ṣe aya
15. (Ìre ní) Òkè Ńlá Gérísímù; (Ìfiré ní) Òkè Ńlá Ébálì
16. Gíbíà
17. Dáríúsì