Mo Pinnu Pé Mo Gbọ́dọ̀ Bá Ohun Tí Mò Ń Lé
GẸ́GẸ́ BÍ MARTHA CHÁVEZ SERNA ṢE SỌ Ọ́
Lọ́jọ́ kan báyìí, nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlógún, mo dédé dákú bí mo ṣe ń ṣiṣẹ́ ilé lọ́wọ́ tí mi ò sì mọ nǹkan kan mọ́. Orí bẹ́ẹ̀dì ni mo ti lajú. Gbogbo nǹkan dàrú mọ́ mi lójú, bẹ́ẹ̀ lorí ń fọ́ mi lákọlákọ, ọ̀pọ̀ ìṣẹ́jú ló kọjá tí mi ò rí ohunkóhun, bẹ́ẹ̀ ni mi ò sì gbọ́ nǹkan kan. Ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí bà mí. Kí ló wa ṣe mí o?
ṢÌBÁṢÌBO bá àwọn òbí mi, wọ́n bá gbé mi lọ sọ́dọ̀ dókítà kan, dókítà yìí ló ní kí n máa lo fítámì. Dókítà obìnrin náà ní àìtètè máa sùn ló fa dídákú tí mo dá kú yẹn. Lóṣù mélòó kan sígbà yẹn, ó tún ṣe mí bíi gìrì, bẹ́ẹ̀ ló sì tún kì mí nígbà kẹta. A lọ sọ́dọ̀ dókítà mìíràn, ó sì sọ pé àrùn tó jẹ mọ́ ètò iṣan inú ọpọlọ ló ń ṣe mí, ló bá fún mi láwọn egbòogi kan tí kì í jẹ́ kéèyàn mọ ìrora lára.
Kàkà kó sàn, àsìkò yìí gan-an ni gìrì yìí wá peléke sí i. Tó bá sì ti dé sí mi báyìí, òòyì á máa kọ́ mi, máà ṣubú lulẹ̀ tí máà sì ṣera mi léṣe. Láwọn ìgbà míì, mo máa ń gé ahọ́n àti ẹnu ara mi jẹ. Bí mo bá wá ta jí, ńṣe lorí á wá máa fọ́ mi burúkú burúkú, bẹ́ẹ̀ ni èébì á sì máa gbé mi. Gbogbo ara á wá máa ro mí, ọ̀pọ̀ ìgbà ni mi ò kí ń rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ kẹ́yìn tí gìrì yẹn fi gbé mi. Kí ara mi tó lè balẹ̀ àfi kí n fi ọjọ́ kan tàbí ọjọ́ méjì gbáko sùn. Síbẹ̀, ìgbàgbọ́ mi ni pé ó máa dópin lọ́jọ́ kan, àti pé mo máa tó yí i dá.
Bó Ṣe Fẹ́rẹ̀ẹ́ Kó Bá Ohun Tí Mò Ń Lé
Mo ṣì kéré gan-an nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá ń kọ́ ìdílé wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn tọkọtaya kan báyìí tí wọ́n jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ló wá ń kọ́ wa, ìyẹn àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti máa fi wákàtí tó pọ̀ gan-an kọ́ àwọn ẹlòmíràn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lóṣooṣù. Mo ṣàkíyèsí pé iṣẹ́ ọ̀hún ń múnú wọn dùn. Nígbà témi náà sọ fún olùkọ́ mi nílé ẹ̀kọ́ àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ bíi tèmi nípa àwọn ìlérí tó wà nínú Bíbélì, inú èmi náà bẹ̀rẹ̀ sí dùn bíi tàwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe yẹn.
Kò pẹ́ sígbà yẹn tí ọ̀pọ̀ lára ìdílé mi fi di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Tẹ̀gàn ni hẹ̀, ohun tí mo máa ń gbádùn bí iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere ò wọ́pọ̀! Nígbà tí mo fi máa pé ọmọ ọdún méje, mo pinnu pé lọ́jọ́ kan èmi náà máa ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe yẹn. Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún ni mí nígbà tí mo ṣèrìbọmi, ìyẹn sì jẹ́ ìgbésẹ̀ ńlá kan tí mo gbé láti mú ìpinnu mi ṣẹ. Kí ni mo ṣèrìbọmi tán sí ni, gìrì tó ń ṣe mí tún bẹ̀rẹ̀.
Iṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú-Ọ̀nà
Láìka àìlera tó ń bá mi fínra sí, ó ṣì ń ṣe mí bíi pé, gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo lè di oníwàásù alákòókò kíkún. Ṣùgbọ́n níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ó máa ń tó bí ẹ̀ẹ̀méjì tí gìrì máa ń gbé mi ṣánlẹ̀ láàárín ọ̀sẹ̀, àwọn ará kan gbà mí nímọ̀ràn pé kí n má ṣe tún gbé ẹrù ńlá yẹn ka ara mi lórí. Ìyẹn mú kí ìrẹ̀wẹ̀sì mú mi, inú mi sì bàjẹ́. Kò pẹ́ sígbà yẹn tí tọkọtaya kan tí wọ́n ń sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Mẹ́síkò wá sí ìjọ wa. Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé ó wù mí láti ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, wọ́n fún mi ní ìṣírí tó pọ̀. Wọ́n jẹ́ kó dá mi lójú pé kò sídìí tí àìlera mi fi gbọ́dọ̀ dá mi dúró láti ṣe iṣẹ́ náà.
Nítorí náà ní September 1, ọdún 1988, mo rí lẹ́tà gbà pé kí n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé nínú ìjọ tí mo wà nílùú wa, ìyẹn San Andrés Chiautla ní Mẹ́síkò. Ọ̀pọ̀ wákàtí ni mo máa fi ń wàásù ìhìn rere lóṣooṣù. Láwọn ìgbà tí gìrì yẹn bá ti ń yọ mí lẹ́nu tí mi ò lè jáde lọ wàásù, mo máa ń kọ lẹ́tà nípa kókó kan látinú Bíbélì sáwọn èèyàn tó wà ní àgbègbè wà, bí mo ṣe máa ń ṣe é tí mo fi ń gba wọ́n nímọ̀ràn láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn.
Wọ́n Ṣàwárí Ohun Tó Ń Ṣe Mí
Ìgbà tọ́rọ̀ rí bó ṣe rí yìí làwọn òbí mi bá ní àwọn ò kọ iye tó máa ná àwọn, wọ́n gbé mi lọ sọ́dọ̀ dókítà tó mọ̀ nípa ètò ìṣàn ara. Dókítà yìí sọ pé àrùn wárápá ló ń yọ mí lẹ́nu. Ọpẹ́lọpẹ́ ìtọ́jú yẹn ló jẹ́ kí n jéèyàn fún bí ọdún mẹ́rin tó tẹ̀ lé e. Láàárín àkókò yẹn, ó ṣeé ṣe fún mi láti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Aṣáájú-Ọ̀nà, ibẹ̀ ni mo sì ti rí ìṣírí tó jẹ́ kí n túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ láti sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù tó pọ̀ sí i gbà.
Àwọn òbí mi mọ bó ṣe ń wù mí tó pé kí n lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìwàásù. Ìgbà tó dà bíi pé àìlera mi ti ń gbóògùn díẹ̀díẹ̀, wọ́n gbà pé kí n lọ sìn nílùú Zitácuaro ní Ìpínlẹ̀ Michoacán, tó fi igba kìlómítà jìnnà sílé wa. Bí mo ṣe máa ń rí àwọn aṣáájú-ọ̀nà mìíràn bá kẹ́gbẹ́ ràn mí lọ́wọ́ gan-an ni láti túbọ̀ mọyì iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún.
Lẹ́yìn ọdún méjì tí mo ti ń wàásù nílùú Zitácuaro ni wárápá yìí tún dé sí mi. Pẹ̀lú ìjákulẹ̀ àti ìbànújẹ́ ni mo fi padà sọ́dọ̀ àwọn òbí mi nílé láti lọ gba ìtọ́jú. Ọ̀dọ̀ dókítà mìíràn tí mo lọ ló jẹ́ kí n mọ̀ pé oògùn tí mò ń lò ti ba ẹ̀dọ̀ mi jẹ́. A wá bẹ̀rẹ̀ sí wá ìtọ́jú ìṣègùn míì níwọ̀n bí a ò ti ní iye owó ìtọ́jú tí oníṣègùn yẹn ní ká san. Àìlera mi wá ń burú sí i débi pé mo ní láti fi iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà sílẹ̀. Gbogbo ìgbà tí wárápá yìí bá ti gbé mi ṣánlẹ̀, ìfàsẹ́yìn ló ń jẹ́ fún mi. Ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá ti ka ìwé Sáàmù tí mo sì gbàdúrà sí Jèhófà, ara máa ń tù mí, mo sì máa ń lókun sí i.—Sáàmù 94:17-19.
Ọwọ́ Mi Tẹ Ohun Tí Mò Ń Wá
Láwọn àkókò tí wárápá yìí ti wọ̀ mí lára tán, ó máa ń gbé mi ṣánlẹ̀ lẹ́ẹ̀mejì lójúmọ́. Ṣùgbọ́n nígbà tó yá, àyípadà dé bá mi. Àsìkò yìí ni oníṣègùn kan bẹ̀rẹ̀ sí fún mi ní oògùn kan tó ń wo àrùn wárápá, bó ṣe di pé mi ò gbúròó ẹ̀ mọ́ fún àkókò gígùn nìyẹn o. Nígbà tó sì di September 1, ọdún 1995, mo bá tún gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà padà. Ara mi balẹ̀ dáadáa, nítorí náà lẹ́yìn ọdún méjì gbáko tí àìsàn yẹn ò tún sọ mí wò mọ́ kódà kó tiẹ̀ jẹ́ ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo péré, ni mo bá tọwọ́ bọ̀wé pé mo fẹ́ di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Ìyẹn ni pé mo fẹ́ máa lo àkókò tó túbọ̀ pọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìwàásù kí n sì lọ sìn níbi tí Jèhófà bá ti nílò mi. Mi ò lè sọ bínú mi ṣe dùn tó lọ́jọ́ tí mo gba lẹ́tà pé kí n máa báṣẹ́ lọ! Bọ́wọ́ mi ṣe tẹ ohun tí mo ti ń lé láti pínníṣín nìyẹn o.
Ní April 1, ọdún 2001 ni mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ibùdó kan tó wà láwọn àgbègbè olókè ní ìpínlẹ̀ Hidalgo. Ní báyìí, ìlú kékeré kan ni mo ti ń sìn ní Ìpínlẹ̀ Guanajuato. Ó gba pé kí n máa lo oògùn mi bó ṣe yẹ, kí n sì rí i pé mò ń fún ara ní ìsinmi tó pọ̀ tó. Mo máa ń ṣọ́ra gan-an tó bá ti dọ̀rọ̀ oúnjẹ, pàápàá àwọn oúnjẹ tó bá ní ọ̀rá tàbí èròjà kaféènì tó máa ń mú kójú dá àti oúnjẹ inú agolo. Mo sì tún máa ń ṣọ́ra fún ohunkóhun tó lè kó mi lọ́kàn sókè, bí ìbínú tàbí àwọn àníyàn kan tí kò yẹ. Àǹfààní díẹ̀ kọ́ ni mo sì ti rí nípa ṣíṣọ́ ara mi lọ́nà yìí. Ní gbogbo ìgbà tí mo fi ń sìn bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, ẹ̀ẹ̀kan péré ni wárápá yẹn kì mí.
Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé mi ò tíì lọ́kọ tí mi ò sì ní bùkátà kankan tí mò ń gbé, mo fẹ́ láti máa sìn nìṣó bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Pé ‘Jèhófà kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ wà àti ìfẹ́ tá a fi hàn fún orúkọ rẹ̀’ máa ń tù mí nínú. Ìfẹ́ Ọlọ́run wa mà pọ̀ o, ẹni tí kì í ní ká ṣe ohun tágbára wa ò ká! Fífi ìyẹn sọ́kàn ti ràn mi lọ́wọ́ láti ní òye tó tọ́ pé bó bá wá di pé àìlera yìí pàpà mú kí n fi iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà sílẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i, ó dá mi lójú pé Jèhófà ṣì máa fìfẹ́ gba ìwọ̀nba tí mo bá ń ṣe tọkàntọkàn nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀.—Hébérù 6:10; Kólósè 3:23.
Kò síyè méjì pé sísọ tí mo máa ń sọ ohun tí mo gbà gbọ́ fáwọn ẹlòmíràn máa ń jẹ́ kí n lókun sí i. Ó tún máa ń mú kí àwọn ìbùkún tí Ọlọ́run ń mú bọ̀ lọ́jọ́ iwájú wà lóókan àyà mi digbí. Ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí ni pé kò ní sí àìsàn nínú ayé tuntun àti “igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ [á] ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:3, 4; Aísáyà 33:24; 2 Pétérù 3:13.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Èmi rèé; mo to ọmọ ọdún méje, àti bí ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (nísàlẹ̀), kò pẹ́ tí mo ṣèrìbọmi
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Ìgbà témi àtọ̀rẹ́ mi ń wàásù