Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Èèyàn Ló Máa Lọ Síbẹ̀ Ṣé Ìwọ Náà Á Lọ?
◼ Lọ síbo? Ibi Àpéjọ Àgbègbè “Ìdáǹdè Kù sí Dẹ̀dẹ̀!” ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni! Ètò ti wà nílẹ̀ pé kí ọgọ́rọ̀ọ̀rún àpéjọ ọlọ́jọ́-mẹ́ta yìí wáyé jákèjádò ayé. Ó sì ti bẹ̀rẹ̀ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ́sẹ̀ tó gbẹ́yìn nínú oṣù May, yóò sì máa bá a nìṣó láwọn oṣù tó tẹ̀ lé e. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn lọ́nà mọ́kànlá tó pésẹ̀ síbi ẹgbẹ̀rún mẹ́tà dín mọ́kàndínlógún [2,981] irú àpéjọ àgbègbè kan bẹ́ẹ̀ tó wáyé láìpẹ́ yìí!
Lọ́pọ̀ ibi tí àpéjọ náà á ti wáyé, orin la ó fi máa bẹ̀rẹ̀ ní agogo mẹ́sàn-án ààbọ̀ òwúrọ̀. Lọ́jọ́ Friday, a óò jíròrò àwọn kókó ọ̀rọ̀ bíi “Ẹ Jẹ́ Ká Fiyè sí Àwọn Ìlérí Ìdáǹdè Tí Jèhófà Ṣe” àti “Bí Jèhófà Ṣe Ń Dá Àwọn Tójú Ń Pọ́n Tí Wọ́n Ń Kígbe fún Ìrànlọ́wọ́ Nídè.” Lájorí àsọyé, tí ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́, “Àwọn Ohun Tí Jèhófà Ṣe Ká Lè Rí ‘Ìdáǹdè Àìnípẹ̀kun,’” la ó fi kádìí ìpàdé òwúrọ̀.
Lára àwọn àsọyé tá a máa gbọ́ lọ́sàn-án Friday ni “Jèhófà Máa Ń Ṣìkẹ́ Àwọn Àgbàlagbà,” “Ìdáǹdè Kúrò Nínú Ìnira,” àti “Ipa Táwọn Áńgẹ́lì Ń Kó Nínú Ṣíṣe ‘Iṣẹ́ Ìsìn fún Gbogbo Ènìyàn.’” Lẹ́yìn àpínsọ àsọyé alápá-mẹ́rin tí ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ “Jèhófà Ni ‘Olùpèsè Àsálà’” la máa gbọ́ àwíyé tó kẹ́yìn lọ́sàn-án Friday, ẹṣin ọ̀rọ̀ àsọyé náà ni “Kò Sí Ohun Ìjà Tàbí Ahọ́n Èyíkéyìí Tí Wọ́n Bá Fi Bá Wa Jà Tó Máa Ṣàṣeyọrí.”
Lára àwọn ọ̀rọ̀ tá a máa gbọ́ lówùúrọ̀ Saturday ni àpínsọ àsọyé alápá-mẹ́ta kan tí àkòrí ẹ̀ jẹ́ “Máa Ṣe Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Nìṣó ‘Láìdẹwọ́,’” àtàwọn àsọyé bí “Ó Dá Wa Nídè Kúrò Nínú Pańpẹ́ Pẹyẹpẹyẹ” àti “Bá A Ṣe Lè Wádìí ‘Àwọn Ohun Ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run.’” Àsọyé kan, tí ọ̀rọ̀ ìrìbọmi fáwọn tó bá tóótun láti ṣèrìbọmi, máa tẹ̀ lé ló máa parí ìpàdé òwúrọ̀.
Lára àwọn àsọyé tá a máa gbádùn lọ́sàn-án Saturday làwọn tó ní ẹṣin ọ̀rọ̀ náà “Máa Fi Ojú Tó Bá Ìwé Mímọ́ Mu Wo Ìtọ́jú Ara,” “Ẹ̀mí Wo Ló Ń Darí Rẹ?,” “Máa Rí I Pé ‘Okùn Onífọ́nrán Mẹ́ta’ Ni Ìgbéyàwó Rẹ,” àti “Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ẹ ‘Rántí Ẹlẹ́dàá Yín Atóbilọ́lá Nísinsìnyí.’” Àsọyé tó ní ẹṣin ọ̀rọ̀ náà, “Ǹjẹ́ Ò Ń Fi Ọjọ́ Jèhófà Sọ́kàn?,” la máa gbọ́ kẹ́yìn lọ́sàn-án Saturday, ó sì ní ìmọ̀ràn tó wúlò fún wa gan-an lákòókò tá à ń gbé yìí.
Àpínsọ àsọyé tó ní ẹṣin ọ̀rọ̀ náà “Ìjọba Ọrùn Dà bí . . . ” wà lára ọ̀rọ̀ tá a máa gbọ́ lówùúrọ̀ Sunday. Wọ́n jẹ́ àsọyé mẹ́rin tó jíròrò díẹ̀ lára àwọn àkàwé Jésù ṣókí ṣókí.
Bí ìpàdé òwúrọ̀ bá ti ń bá a nìṣó, a óò gbọ́ àsọyé tó dá lórí ọ̀kan pàtàkì lára ohun tá a óò gbádùn ní àpéjọ náà, ìyẹn ni àwòkẹ́kọ̀ọ́ nínú èyí táwọn èèyàn á ti múra bí àwọn ara ìgbàanì, èyí tó dá lórí ìwé Àwọn Ọba Kìíní, orí 13. Lọ́sàn-án Sunday, tó jẹ́ apá tó gbẹ̀yìn àpéjọ náà, a óò gbọ́ àsọyé fún gbogbo ènìyàn, àkòrí rẹ̀ ni “Ìdáǹdè Nípasẹ̀ Ìjọba Ọlọ́run Kù sí Dẹ̀dẹ̀!”
Máa gbára dì báyìí kó o bàa lọ síbẹ̀. Bó o bá fẹ́ mọ ibi tó sún mọ́ ọ jù lọ tí àpéjọ náà á ti wáyé, kàn sí Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí kó o kọ̀wé sí àwọn tó tẹ ìwé ìròyìn yìí.