Báwọn Èwe Ṣe Lè Ṣẹ́pá Ìsoríkọ́
WỌ́N ní káwọn akẹ́kọ̀ọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò múra ohun tí wọ́n máa sọ sílẹ̀ lórí kókó ọ̀rọ̀ tó bá wù wọ́n. Akẹ́kọ̀ọ́ kan tó ń jẹ́ Maritza ṣàlàyé pé: “Ó ti ṣe díẹ̀ tí mo ti ń sorí kọ́, ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà, “Ìrànwọ́ fún Àwọn Èwe Tó Sorí Kọ́,” tó wà nínú Jí! September 8, 2001, sì ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an. Nítorí náà, mo lo àwọn ìsọfúnni tó wà nínú ìwé ìròyìn náà, wọ́n sì fún mi ní máàkì tó dára jù lọ. Lẹ́yìn ìyẹn, mo fáwọn akẹgbẹ́ mi àtàwọn olùkọ́ ní ẹ̀dà ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà.”
Ní ọdún méjì lẹ́yìn náà, nígbà tí Maritza wà lóde ẹ̀rí, ó ṣèbẹ̀wò sílé akẹ́kọ̀ọ́ kan tó ń kọ́ irú ẹ̀kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì yẹn. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún Maritza nígbà tí akẹ́kọ̀ọ́ náà fi ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tó sọ nípa àwọn èwe tó sorí kọ́ hàn án. Ó dà bíi pé olùkọ́ wọn mọrírì rẹ̀ gan-an débi pé ó fún olúkúlùkù wọn ní ẹ̀dà àpilẹ̀kọ náà!
O lè rí ìsọfúnni síwájú sí i lórí àwọn èwe tó sorí kọ́ nínú ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́. Lára àwọn àpilẹ̀kọ tó wà nínú ẹ̀ nìwọ̀nyí: “Eeṣe Ti Emi Kò Fi Fẹran Araami?,” “Eeṣe Ti Mo Fi Maa Ń Sorikọ Tóbẹ́ẹ̀?,” àti “Bawo Ni Mo Ṣe Lè Mú Ki Ìdánìkanwà Mi Lọ?” Bó o bá fẹ́ gba ẹ̀dà kan, o lè kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà lójú ewé yìí kó o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.