ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 4/08 ojú ìwé 14-15
  • Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Rẹ?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Rẹ?
  • Jí!—2008
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tó Túmọ̀ sí Láti Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run Pẹ̀lú Gbogbo Ọkàn Àyà Wa
  • Bó O Ṣe Lè Ṣàṣeyọrí Nínú Fífi Ohun Tó Yẹ Sípò Àkọ́kọ́
  • Bí a Ṣe Ń fi Hàn Pé A Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run Tó Nífẹ̀ẹ́ Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Nípa Ọlọ́run Tòótọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • “Ẹ Sún Mọ́ Ọlọ́run, Á sì Sún Mọ́ Yín”
    Sún Mọ́ Jèhófà
Àwọn Míì
Jí!—2008
g 4/08 ojú ìwé 14-15

Ojú Ìwòye Bíbélì

Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Rẹ?

ỌWỌ́ wa máa ń dí nígbà gbogbo torí pé a ní ohun to pọ̀ láti ṣe. Ìgbà míì wà tó jẹ́ pé àfi ká sapá gidigidi ká tó lè ṣe ojúṣe wa. Síbẹ̀, a ò gbọ́dọ̀ gbàgbé pé wíwà tá a wà láàyè jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. (Sáàmù 36:9) Báwo wá ni àkókò àti okun tí Ọlọ́run fẹ́ ká máa lò fóun ṣe gbọ́dọ̀ pọ̀ tó? Inú Bíbélì la ti lè rí ìdáhùn tó ń fúnni níṣìírí.

Jésù tó jẹ́ ọmọ Ọlọ́run nìkan ló mọ ohun tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ àwa èèyàn lámọ̀dunjú. (Mátíù 11:27) Nígbà tí wọ́n bi Jésù pé òfin wo ló tóbi jù lọ, ó ní: “Kí ìwọ . . . nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò-inú rẹ àti pẹ̀lú gbogbo okun rẹ.” (Máàkù 12:30) Kí lèyí túmọ̀ sí? Ṣé kò ti pọ̀ jù báyìí?

Ohun Tó Túmọ̀ sí Láti Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run Pẹ̀lú Gbogbo Ọkàn Àyà Wa

Ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run á máa pọ̀ sí i bá a ti ń ronú lórí inú rere tí kò láàlà tó ń fi hàn sí wa. Bá a bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ọkàn àyà wa, ìfẹ́ yẹn á mú ká máa fún un ní èyí tó dára jù lọ nínú ohun yòówù tá a bá ni. Bíi ti ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì ló máa rí lára wa, ó béèrè pé: “Kí ni èmi yóò san padà fún Jèhófà nítorí gbogbo àǹfààní tí mo rí gbà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀?” (Sáàmù 116:12) Báwo ni nínífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run lọ́nà yìí ṣe kan bá a ṣe ń lo àkókò wa?

Bíbélì ò sọ iye àkókò kan pàtó tá a gbọ́dọ̀ máa yà sọ́tọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti fi jọ́sìn Ọlọ́run. Àmọ́, ó sọ àwọn ìgbòkègbodò tá a gbọ́dọ̀ máa fi sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa, ó sì ṣàlàyé ìdí tó fi yẹ kó rí bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Jésù kọ́ni pé níní ìmọ̀ Ọlọ́run wà lára ìgbésẹ̀ pàtàkì téèyàn gbọ́dọ̀ gbé kó tó lè ní “ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 17:3) Ó tún sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun gbọ́dọ̀ ran àwọn tí kò mọ Ọlọ́run lọ́wọ́ láti jèrè ìyè nípa fífi ìmọ̀ Ọlọ́run kọ́ wọn. (Mátíù 28:19, 20) Bíbélì fún wa nítọ̀ọ́ni pé ká máa pé jọ pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ déédéé ká lè túbọ̀ jẹ́ alágbára nípa tẹ̀mí, ká sì lè máa fún ara wa níṣìírí. (Hébérù 10:24, 25) Ṣíṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí ń gba àkókò.

Ṣé ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ ni pé ká wa ẹ̀sìn máyà? Rárá o! Ó yẹ ká máa fún gbígbọ́ bùkátà ojoojúmọ́ láfiyèsí pẹ̀lú. Bíbélì fún àwọn olórí ìdílé nítọ̀ọ́ni láti máa gbọ́ ti ìdílé wọn nígbà tó sọ pé: “Dájúdájú, bí ẹnì kan kò bá pèsè fún àwọn tí í ṣe tirẹ̀, àti ní pàtàkì fún àwọn tí í ṣe mẹ́ńbà agbo ilé rẹ̀, ó . . . burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.”—1 Tímótì 5:8.

Ọlọ́run ò dá wa fúnyà jẹ. Torí náà, kò sóhun tó burú nínú káwa àtàwọn mọ̀lẹ́bí wa, àtàwọn ọ̀rẹ́ wa jọ máa gbádùn ara wa, ká sì máa jẹ oúnjẹ aládùn. Ọba Sólómọ́nì kọ̀wé nípa àwa èèyàn pé: “Mo ti wá mọ̀ pé kò sí ohun tí ó sàn ju pé kí wọ́n máa yọ̀ kí wọ́n sì máa ṣe rere nígbà ìgbésí ayé [wọn]; pẹ̀lúpẹ̀lù, pé kí olúkúlùkù ènìyàn máa jẹ, kí ó sì máa mu ní tòótọ́, kí ó sì rí ohun rere nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀. Ẹ̀bùn Ọlọ́run ni.”—Oníwàásù 3:12, 13.

Jèhófà Ọlọ́run tún mọ ibi tágbára àwa èèyàn mọ, “ó rántí pé ekuru ni wá.” (Sáàmù 103:14) Bíbélì pàápàá jẹ́ ká mọ̀ pé a nílò ìsinmi dáadáa. Lẹ́yìn táwọn àpọ́sítélì Jésù ti ṣiṣẹ́ lọ́jọ́ kan, tó sì ti rẹ̀ wọ́n, Jésù sọ fún wọn pé kí wọ́n lọ ‘ní àwọn nìkan sí ibi tí ó dá, kí wọ́n sì sinmi díẹ̀.’—Máàkù 6:31.

Nítorí náà, ìgbésí ayé tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, tí kò sì káni lọ́wọ́ kò ni inú Ọlọ́run máa ń dùn sí. Àmọ́ ṣá o, ohunkóhun tá a bá ń ṣe, yálà ó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run tàbí kò jẹ mọ́ ọn, gbọ́dọ̀ máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run látọkàn wá. Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn pé: “Yálà ẹ ń jẹ tàbí ẹ ń mu tàbí ẹ ń ṣe ohunkóhun mìíràn, ẹ máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.”—1 Kọ́ríńtì 10:31.

Bó O Ṣe Lè Ṣàṣeyọrí Nínú Fífi Ohun Tó Yẹ Sípò Àkọ́kọ́

Àbí fífi ìjọsìn Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ dà bí ohun àléèbá fún ẹ? Òótọ́ ni pé ká tó lè ṣe ohun tí Ọlọ́run ń béèrè, àfi ká yí bá a ṣe ń lo àkókò wa padà, kódà ó lè gba pé ká yááfì àwọn nǹkan kan pàápàá. Àmọ́, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ kò béèrè ohun tó ju agbára wa lọ lọ́wọ́ wa. Kódà, ọ̀pọ̀ nǹkan tó lè ràn wá lọ́wọ́ ni Ọlọ́run ti pèsè fún wa ká lè ṣe ìfẹ́ rẹ̀. A lè ṣàṣeyọrí, tá a bá gbára lé “okun tí Ọlọ́run ń pèsè.”—1 Pétérù 4:11.

Ó lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fún ẹ láti fàwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí kún àwọn ohun tó o máa ń ṣe lójoojúmọ́. Wá àkókò láti máa bá Jèhófà “Olùgbọ́ àdúrà” sọ̀rọ̀ déédéé. (Sáàmù 65:2) O lè sọ ohunkóhun tó bá ń gbé ẹ lọ́kàn fún un nínú àdúrà, níwọ̀n bó o ti mọ̀ pé “ó bìkítà fún [ẹ].” (1 Pétérù 5:7) Ọba Dáfídì gbàdúrà pé: “Kọ́ mi láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ, nítorí pé ìwọ ni Ọlọ́run mi.” (Sáàmù 143:10) Ìwọ pẹ̀lú lè bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run kó o lè ṣe àwọn àtúnṣe tó bá yẹ nígbèésí ayé ẹ.

Ìkésíni tó fani lọ́kàn mọ́ra yìí wà nínú Bíbélì pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” (Jákọ́bù 4:8) Bó o ti bẹ̀rẹ̀ sí lọ́wọ́ sáwọn ìgbòkègbodò tó ń múnú Ọlọ́run dùn, irú bíi kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti lílọ sáwọn ìpàdé ìjọ, wàá túbọ̀ máa sún mọ́ Ọlọ́run. Ọlọ́run yóò sì máa fún ẹ lókun láti túbọ̀ tẹ̀ síwájú.

Nígbà tí Jelena, táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìsapá tó ti ṣe kó lè máa fàwọn ohun tó yẹ sípò àkọ́kọ́, ó sọ pé, “Kò rọrùn fún mi rárá.” Ó wá fi kún un pé: “Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni báyìí, ni mo ti ń rí okun gbà láti lè máa fàwọn ohun tí Bíbélì sọ sílò. Báwọn ará ò ṣe dá mi dá ọ̀ràn ara mi ti ràn mí lọ́wọ́ pẹ̀lú.” Ó túbọ̀ máa ń wu èèyàn láti sin Ọlọ́run, tó bá ń rí àwọn àǹfààní tó wà níbẹ̀. (Éfésù 6:10) Jelena sọ pé, “Àjọṣe èmi àti ọkọ mi ti dán mọ́rán sí i, mo sì tún ti mọ bó ṣe yẹ kí n máa bá àwọn ọmọ mi wí.”

Láìka kòókòó jàn-án jàn-án ayé òde òní sí, ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà tí kì í bà á tì, lè fún ẹ lókun, kó sì mú kó o ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó o fi ṣípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé, á tún jẹ́ kó o lè ‘ra àkókò padà’ láti sin Ọlọ́run. (Éfésù 3:16; 5:15-17) Jésù sọ pé: “Àwọn ohun tí kò ṣeé ṣe fún ènìyàn ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.”—Lúùkù 18:27.

KÍ LÈRÒ Ẹ?

◼ Kí nìdí tó fi yẹ kó o fi ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé rẹ?—Sáàmù 116:12; Máàkù 12:30.

◼ Ìgbòkègbodò wo ni Ọlọ́run retí pé kó o máa lọ́wọ́ sí?—Mátíù 28:19, 20; Jòhánù 17:3; Hébérù 10:24, 25.

◼ Báwo lo ṣe lè ṣàtúnṣe àwọn ohun tó o fi sípò àkọ́kọ́ lọ́nà tó máa múnú Ọlọ́run dùn?—Éfésù 5:15-17; Jákọ́bù 4:8.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

A gbọ́dọ̀ wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì ká tó lè múnú Ọlọ́run dùn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́