“Mi Ò Mọ̀ Pé Ọlọ́run Lórúkọ”
◼Ohun tóbìnrin kan sọ nìyẹn lẹ́yìn tó ka ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ó fi kún un pé, “ó bọ́gbọ́n mu pé kí Ọlọ́run lórúkọ. Nígbà tí mo wo inú Bíbélì mi, gàdàgbà gadagba lorúkọ Ọlọ́run wà níbẹ̀!” Ó ṣàlàyé pé: “Mi ò tíì kàwé tó wúlò, tó sì rọrùn tó báyìí rí nípa Bíbélì!”
Kì í ṣe pé ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni ṣàlàyé pé Ọlọ́run fẹ́ kí ayé jẹ́ Párádísè látìbẹ̀rẹ̀ nìkan ni, àmọ́ ó tún ṣàlàyé tó kún nípa bí Ọlọ́run ṣe máa mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ. Ìwé yẹn jẹ́ ká mọ ipa tí Jésù Kristi Ọmọ Ọlọ́run máa kó láti mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ. Ó jẹ́ ká mọ àwọn àlàyé tí Bíbélì ṣe lórí ohun tó fà á tá a fi ń darúgbó tá a sì ń kú, ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà àti bí Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa gbà wá lọ́wọ́ gbogbo ìjìyà.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tíì ju ọdún mẹ́ta lọ tá a ṣe ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, ó ti ju ẹ̀dà mílíọ̀nù mọ́kàndínlọ́gọ́rin [79] lọ tá a ti tẹ̀ jáde ní nǹkan bí èdè okòólérúgba [220]. Bó o bá fẹ́ gba ẹ̀dà kan, o lè kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà lójú ewé yìí kó o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.