Ìwé Àtijọ́ Kan Tó Wúlò Lóde Òní
Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ló mọyì Bíbélì, wọ́n sì gbà pé ìwé mímọ́ pàtàkì kan tí wọ́n ń lò nínú ẹ̀sìn ni. Àmọ́ Bíbélì kì í ṣe ìwé ẹ̀sìn nìkan, ó tún ń fúnni nímọ̀ràn tó lè jẹ́ kéèyàn gbé ìgbé ayé tó dára.
Bí àpẹẹrẹ, wo díẹ̀ lára àǹfààní táwọn kan ti rí torí pé wọ́n ń ka Bíbélì, wọ́n sì ń tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn inú rẹ̀.
“Ayé mi ti túbọ̀ lójú. Mo ti ń ronú lọ́nà tó tọ́, ìlera mi sì ti sunwọ̀n sí i. Mo ti wá ń láyọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.”—Fiona.
“Bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti jẹ́ kí ìgbésí ayé mi nítumọ̀.”—Gnitko.
“Bíbélì ti tún ayé mi ṣe gan-an. Ní báyìí, mo ti dín àkókò tí mo fi ń ṣiṣẹ́ kù, mo sì máa ń wá àyè láti gbọ́ ti ìdílé mi.”—Andrew.
Díẹ̀ lèyí jẹ́ lára àwọn èèyàn tí Bíbélì ti ràn lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé ti rí i pé Bíbélì wúlò gan-an, ìmọ̀ràn inú rẹ̀ sì ṣàǹfààní.
Ẹ jẹ́ ká wo bí Bíbélì ṣe lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ . . .
- Láti ní ìlera tó dáa 
- Láti jẹ́ onísùúrù 
- Láti ní ìdílé aláyọ̀ àti ọ̀rẹ́ àtàtà 
- Láti máa rówó gbọ́ bùkátà 
- Láti sún mọ́ Ọlọ́run 
Àwọn àpilẹ̀kọ tó kàn máa jẹ́ kó o rí i pé kì í ṣe ìjọsìn nìkan ni Bíbélì wúlò fún, ó tún lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ ní gbogbo apá ìgbésí ayé rẹ.