Ìwé Tó Dáa Jù Lọ Láyé
Bíbélì ni ìwé tí wọ́n túmọ̀ sí èdè tó pọ̀ jù láyé yìí, òun sì ni ìwé tí wọ́n pín kiri jù lọ. Torí náà, ọgbọ́n inú rẹ̀ ti dé ibi gbogbo láyé, ó sì ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ kárí ayé. Kò sí ìwé míì tó tíì ṣe irú ẹ̀ láyé yìí. Àwọn ìsọfúnni díẹ̀ rèé nípa ohun tá à ń sọ:
ÌTUMỌ̀ BÍBÉLÌ ÀTI IYE TÓ TI DỌ́WỌ́ ÀWỌN ÈÈYÀN
- 96.5% ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo èèyàn tó wà láyé ló ní Bíbélì 
- 3,350 Èdè (LÓDINDI TÀBÍ LÁPÁ KAN) 
- 5,000,000,000 Èyí ni iye tí wọ́n ṣírò pé wọ́n ti tẹ̀ jáde, kò sí ìwé míì láyé yìí tí iye ẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ 
MỌ PÚPỌ̀ SÍ I
LỌ SÓRÍ ÌKÀNNÌ WA, JW.ORG/YO. NÍBẸ̀
- O lè ka Bíbélì lórí ìkànnì (ó wà ní èdè tó ju 260 lọ) 
- O lè wa Bíbélì jáde 
- O lè rí ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìbéèrè pàtàkì 
- O lè ka àwọn àpilẹ̀kọ nípa bí Bíbélì ṣe tún ayé ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe 
ÀWỌN BÍBÉLÌ TÍ ÀWA ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ TI TẸ̀ JÁDE
ÀWA ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ Ń TÚMỌ̀ BÍBÉLÌ, A SÌ Ń FÚN ÀWỌN ÈÈYÀN.
Díẹ̀ lára àwọn ìtumọ̀ Bíbélì tá a ti tẹ̀ jáde rèé:
- The American Standard Version of 1901 
- The Bible in Living English, Byington 
- The Emphatic Diaglott 
- The King James Version 
- Revised Standard Version 
- Tischendorf’s New Testament 
BÍBÉLÌ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN
- 180+ Èdè (LÓDINDI TÀBÍ LÁPÁ KAN) 
- 227 MÍLÍỌ̀NÙ BÍBÉLÌ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN TÓ TI JÁDE LÁTỌDÚN 1950 
a Ní báyìí, ó wà ní èdè Gẹ̀ẹ́sì àti Pótogí. A máa fi àwọn èdè mí ì kún un tó bá yá.