NǸKAN Ń GBÓWÓ LÓRÍ! ỌGBỌ́N WO LO LÈ DÁ SÍ I?
Gbà Pé Ńṣe Ni Nǹkan Á Máa Wọ́n Sí I
Táwọn nǹkan bá ń gbówó lórí díẹ̀díẹ̀, èèyàn lè má tètè mọ̀ ọ́n lára, àgàgà tí owó tó ń wọlé fúnni bá ń pọ̀ sí i. Àmọ́ tówó ọjà bá lọ sókè lójijì, tí owó tó ń wọlé ò sì pọ̀ sí i, èèyàn lè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́kàn sókè. Kódà, ó lè mú káyé súni, pàápàá téèyàn bá láwọn tó ń gbọ́ bùkátà ẹ̀.
Òótọ́ kan ni pé, kò sóhun tá a lè ṣe tí nǹkan ò fi ní máa wọ́n sí i. Tá a bá ń fi èyí sọ́kàn, ó máa ṣe wá láǹfààní.
ÌDÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ
Téèyàn bá gbà pé ńṣe ni nǹkan á máa wọ́n sí i . . .
kò ní máa kọ́kàn sókè ju bó ṣe yẹ lọ. Èyí á jẹ́ kó lè máa ronú jinlẹ̀, á sì máa ṣe àwọn nǹkan tó mọ́gbọ́n dání.
kò ní máa ṣe àwọn nǹkan táá kó o sí gbèsè. Bí àpẹẹrẹ, á máa san àwọn owó tó yẹ kó san lásìkò, kó má bàa di pé èlé á gorí ẹ̀ nígbà tó bá yá. Kò sì ní máa náwó nínàákúnàá.
kò ní jẹ́ kí ọ̀rọ̀ owó máa dá wàhálà sílẹ̀ nínú ìdílé.
á máa wá bó ṣe máa ṣọ́wó ná. Bí àpẹẹrẹ, kò ní máa náwó sórí àwọn nǹkan tí kò ṣe pàtàkì.
OHUN TÓ O LÈ ṢE
Ṣe tán láti ṣe àwọn àyípadà kan. Lásìkò tí nǹkan bá ń gbówó lórí, á dáa kéèyàn máa ṣọ́wó ná. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan máa ń tọrùn bọ gbèsè torí kí wọ́n lè ṣe fàájì tàbí kí wọ́n lè bẹ́gbẹ́ pé. Ìyẹn ò wá ní jẹ́ kọ́kàn wọn balẹ̀. Torí ṣe ni wọ́n á kàn máa ṣe kìràkìtà lásán, awọ ò sì ní kájú ìlù. Tó bá jẹ́ torí kó o lè máa bójú tó ìdílé ẹ lo ṣe ń forí ṣe fọrùn ṣe, ìyẹn dáa. Síbẹ̀, ó yẹ kó o máa rántí pé: Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kó o máa wáyè fún ìdílé ẹ, kẹ́ ẹ jọ máa sọ̀rọ̀, kó o sì máa fìfẹ́ hàn sí wọn.
Téèyàn bá ń tọrùn bọ gbèsè torí fàájì tàbí kó lè bẹ́gbẹ́ pé, ọkàn ẹ̀ ò ní balẹ̀, ṣe lá kàn máa ṣe kìràkìtà lásán, awọ ò sì ní kájú ìlù