NǸKAN Ń GBÓWÓ LÓRÍ! ỌGBỌ́N WO LO LÈ DÁ SÍ I?
Máa Fọgbọ́n Náwó
Kò sẹ́ni tọ́rọ̀ owó ọjà tó ń lọ sókè ò kàn, gbogbo wa pátá ló ń ni lára. Àmọ́, ṣó wá yẹ kíyẹn mú kó o máa kárí sọ? Rárá o. Àwọn nǹkan kan wà tó o lè ṣe tó ò fi ní máa kọ́kàn sókè ju bó ṣe yẹ lọ.
ÌDÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ
Tẹ́nì kan ò bá fọgbọ́n ná owó tó ń wọlé fún un, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ gbèsè. Ìyẹn ò sì ní jẹ́ kọ́kàn ẹ̀ balẹ̀, kódà ńṣe ló máa dá kún ìṣòro ẹ̀. Tó ò bá tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́, àwọn nǹkan kan wà tó o lè ṣe kó o lè máa fọgbọ́n náwó.
OHUN TÓ O LÈ ṢE
Ṣe bó o ti mọ. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, o ò ní máa náwó nínàákúnàá. Ìyẹn ò sì ní jẹ́ kó o máa kọ́kàn sókè ju bó ṣe yẹ lọ tí nǹkan àìròtẹ́lẹ̀ bá ṣẹlẹ̀.
Kó o má bàa máa náwó nínàákúnàá, á dáa kó o ṣètò bí wàá ṣe máa náwó. Ìyẹn máa gba pé kó o kọ iye tó ń wọlé fún ẹ àti iye tó o fẹ́ ná. Lẹ́yìn náa, rí i dájú pé o mọ àwọn nǹkan tó o nílò gangan. Kó o wá pinnu pé o ò ní ná ju iye tó o kọ sílẹ̀ lọ. Tí iye tó ń wọlé fún ẹ bá yí pa dà tàbí tí owó ọjà yí pa dà, kó o yí ohun tó o kọ sílẹ̀ náà pa dà. Tó o bá sì ti ní ọkọ tàbí aya, á dáa kó jẹ́ pé ẹ̀yin méjèèjì lẹ jọ máa ṣètò ìnáwó náà.
Gbìyànjú èyí wò: Dípò tí wàá fi máa ra nǹkan láwìn, tó bá ṣeé ṣe, máa san owó nǹkan tó o bá rà lójú ẹsẹ̀. Àwọn kan ti gbìyànjú ẹ̀, wọ́n sì rí i pé kì í jẹ́ káwọn náwó nínàákúnàá, wọn kì í sì í jẹ gbèsè. Bákan náà, máa fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ báǹkì ẹ tàbí kó o máa ṣàkọsílẹ̀ bó o ṣe ń náwó, kó o lè mọ iye tó ń wọlé àti iye tó ń jáde lóṣooṣù. Tó o bá mọ iye tó o ní lọ́wọ́, o ò ní máa náwó yàlàyòlò débi tí wàá fi jẹ gbèsè, tí wàá sì máa kọ́kàn sókè.
Ká sòótọ́, kì í rọrùn láti máa sọ́wó ná. Àmọ́, o lè rí i ṣe tó o bá ń fara balẹ̀ ṣètò bó o ṣe ń náwó, tó ò sì ṣe jura ẹ lọ. Ìyẹn ò ní jẹ́ kó o máa ṣàníyàn ju bó ṣe yẹ lọ.
Má ṣe jẹ́ kí ọ̀nà àtijẹ ẹ dí. Ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe kíṣẹ́ má bàa bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́. Ara ohun tó o lè ṣe nìyí: Máa tètè dé ibiṣẹ́. Máa fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ ẹ. Máa ṣe ohun tó yẹ kó o ṣe níbiṣẹ́ láìjẹ́ pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń sọ fún ẹ, má sì fiṣẹ́ ṣeré. Máa pọ́n àwọn èèyàn lé. Máa pa òfin ibiṣẹ́ mọ́, kó o sì máa wá bó o ṣe lè jáfáfá sí i lẹ́nu iṣẹ́ ẹ.
Má ṣe máa fowó ṣòfò. Bi ara ẹ pé, ‘Ṣé mi kì í náwó tó pọ̀ lórí àwọn nǹkan tí kò ṣe pàtàkì tàbí àwọn nǹkan tó lè pa mí lára?’ Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń forí ṣe fọrùn ṣe kí wọ́n tó rówó, tí wọ́n bá wá rówó náà tán, wọ́n á máa ná an sórí oògùn olóró, tẹ́tẹ́, sìgá àti ọtí àmujù. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn nǹkan yìí lè kó bá ìlera wọn, ó sì lè mú kíṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ wọn.
Máa fowó pa mọ́ torí ohun àìròtẹ́lẹ̀. Tó bá ṣeé ṣe, máa tọ́jú owó díẹ̀ pa mọ́ kó o lè rí i lò tí ohun àìròtẹ́lẹ̀ bá ṣẹlẹ̀. Irú owó bẹ́ẹ̀ lè wúlò tí ìwọ tàbí mọ̀lẹ́bí ẹ kan bá ń ṣàìsàn, tíṣẹ́ bá bọ́ lọ́wọ́ ẹ tàbí táwọn ohun àìròtẹ́lẹ̀ míì bá ṣẹlẹ̀.