NǸKAN Ń GBÓWÓ LÓRÍ! ỌGBỌ́N WO LO LÈ DÁ SÍ I
Ní Ìtẹ́lọ́rùn
Ọkàn àwọn tó bá nítẹ̀ẹ́lọ́rùn sábà máa ń balẹ̀. Tí nǹkan bá sì yí pa dà fún wọn, dípò tí wọ́n á fi máa ṣe jura wọn lọ, ńṣe ni wọ́n á máa fọgbọ́n lo ìwọ̀nba ohun tó ń wọlé fún wọn.
ÌDÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ
Onímọ̀ nípa ìrònú àti ìṣe ẹ̀dá tó ń jẹ́ Jessica Koehler sọ pé àwọn tó bá nítẹ̀ẹ́lọ́rùn kì í sábà jowú àwọn ẹlòmíì, wọ́n sì máa ń gbà pé nǹkan ṣì máa dáa. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé àwọn tó nítẹ̀ẹ́lọ́rùn kì í kọ́kàn sókè ju bó ṣe yẹ lọ, wọ́n sì máa ń láyọ̀. Kódà, ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń láyọ̀ jù láyé yìí ni kì í ṣe olówó. Ohun tó sì mú kó rí bẹ́ẹ̀ fáwọn kan nínú wọn ni pé àwọn nǹkan téèyàn ò lè fowó rà ni wọ́n kà sí pàtàkì jù. Bí àpẹẹrẹ, inú wọn máa ń dùn bí wọ́n ṣe ń wáyè láti wà pẹ̀lú àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn.
OHUN TÓ O LÈ ṢE
Má ṣe máa fi ara ẹ wé àwọn ẹlòmíì. Tó bá jẹ́ pé o ò fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́, tó o wá lọ ń fi ara ẹ wé àwọn ẹlòmíì tó dà bíi pé wọ́n lówó, tí wọ́n sì ń jayé orí wọn, o lè má nítẹ̀ẹ́lọ́rùn mọ́, kódà o lè bẹ̀rẹ̀ sí í jowú wọn. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn tó ò ń fi ara ẹ wé lè má lówó tó bó o ṣe rò. Ó tiẹ̀ lè jẹ́ pé gbèsè ǹlá ló wà lọ́rùn àwọn kan lára wọn. Nicole, tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Senegal sọ pé: “Kò dìgbà tí mo bá ní owó tó pọ̀ tàbí ohun ìní rẹpẹtẹ kí n tó lè láyọ̀. Tí mo bá ṣáà ti nítẹ̀ẹ́lọ́run, màá láyọ̀ táwọn èèyàn bá tiẹ̀ lówó jù mí lọ.”
Gbìyànjú èyí wò: Yẹra fáwọn ìpolówó ọjà tàbí àwọn ìkànnì àjọlò táwọn èèyàn ti ń fi owó àtàwọn nǹkan ìní wọn ṣe kárími.
Fi hàn pé o moore. Tí wọ́n bá fún ẹni tó moore ní nǹkan, ó máa ń tẹ́ ẹ lọ́rùn, kò sì ní máa ronú pé ó yẹ kí wọ́n fún òun jù bẹ́ẹ̀ lọ. Roberton, tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Haiti sọ pé: “Mo máa ń gbìyànjú láti ronú nípa àwọn nǹkan táwọn èèyàn ń ṣe láti ran èmi àti ìdílé mi lọ́wọ́. Bákan náà, mo máa ń jẹ́ káwọn tó ràn mí lọ́wọ́ mọ̀ pé mo mọyì ohun tí wọ́n ṣe fún mi. Mo sì tún kọ́ ọmọkùnrin mi tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ pé kó máa dúpẹ́ táwọn èèyàn bá fún un ní nǹkan.”
Gbìyànjú èyí wò: Ní ìwé kan tí wàá máa kọ àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ń ṣe fún ẹ sí lójoojúmọ́, kó o sì máa dúpẹ́. O lè dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run torí àwọn ọ̀rẹ́ ẹ, ìdílé ẹ tàbí ìlera ẹ, kódà o lè dúpẹ́ tó o bá rí ojú ọjọ́ tó rẹwà.
Ká sòótọ́, kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn láti nítẹ̀ẹ́lọ́rùn. Àmọ́, á ṣe wá láǹfààní tá a bá ní in! Tá a bá nítẹ̀ẹ́lọ́rùn, a máa láyọ̀, ìyẹn ò sì ṣeé fowó rà.