APÁ 7
Ìgbà Tí Jésù Jíǹde sí Ìgbà Tí Wọ́n Ju Pọ́ọ̀lù Sẹ́wọ̀n
Ní ọjọ́ kẹta tí Jésù kú, Ọlọ́run jí i dìde. Lọ́jọ́ yẹn, ìgbà márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló fara han àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Ogójì [40] ọjọ́ ló sì fi ń fara hàn wọ́n. Lẹ́yìn náà, níṣojú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tó ń wò ó, ó gòkè lọ sọ́run. Ní ọjọ́ mẹ́wàá lẹ́yìn náà, Ọlọ́run tú ẹ̀mí mímọ́ sórí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí wọ́n wà ní Jerúsálẹ́mù.
Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, àwọn ọ̀tá Ọlọ́run mú káwọn èèyàn gbé àwọn àpọ́sítélì jù sẹ́wọ̀n. Àwọn alátakò sọ Sítéfánù lókùúta pa. Àmọ́, a óò rí bí Jésù ṣe yan ọ̀kan lára àwọn alátakò náà láti di ìránṣẹ́ rẹ̀ pàtàkì. Ẹni náà ló di àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ní ọdún mẹ́ta ààbọ̀ lẹ́yìn ikú Jésù, Ọlọ́run rán àpọ́sítélì Pétérù pé kó lọ wàásù fún ọkùnrin kan tí kì í ṣe Júù, ìyẹn ni Kọ̀nílíù àti ìdílé rẹ̀.
Ní nǹkan bí ọdún mẹ́tàlá lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò ìwàásù rẹ̀ àkọ́kọ́. Nígbà ìrìn àjò ìwàásù rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kejì, Tímótì bẹ̀rẹ̀ sí í bá a rìnrìn àjò. A óò rí bí Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n ń bá a rìnrìn àjò ṣe ní ìrírí tó mọ́kàn wọn yọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ Ọlọ́run. Níkẹyìn, wọ́n ju Pọ́ọ̀lù sẹ́wọ̀n ní Róòmù. Ní ọdún méjì lẹ́yìn náà, wọ́n dá a sílẹ̀, àmọ́ wọ́n tún padà jù ú sẹ́wọ̀n wọ́n sì pa á. Ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín ohun tó lé lọ́dún méjìlélọ́gbọ̀n [32] ló wà nínú APÁ 7 yìí.