ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • gf ẹ̀kọ́ 15 ojú ìwé 24-25
  • Àwọn Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run A Máa Ṣe Rere

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run A Máa Ṣe Rere
  • Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdílé Rẹ Lè Láyọ̀
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • Kọ́kọ́rọ́ Méjì sí Ìgbéyàwó Wíwà Pẹ́ Títí
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Ìgbésí Ayé Ìdílé Tí Inú Ọlọrun Dùn Sí
    Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?
  • Báwo Ni Ìdílé Rẹ Ṣe Lè Ní Ayọ̀?
    Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé
Àwọn Míì
Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!
gf ẹ̀kọ́ 15 ojú ìwé 24-25

Ẹ̀kọ́ 15

Àwọn Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run a Máa Ṣe Rere

Bóo ba ní ọ̀rẹ́ kan, tóo gba tiẹ̀, tóo sì bọ̀wọ̀ fún, wàá gbìyànjú láti dà bíi rẹ̀. Bíbélì wí pé: “Ẹni rere àti adúróṣánṣán ni Jèhófà.” (Sáàmù 25:8) Láti jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni rere àti adúróṣánṣán. Bíbélì wí pé: “Ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n, kí ẹ sì máa bá a lọ ní rírìn nínú ìfẹ.” (Éfésù 5:1, 2) Àwọn ọ̀nà díẹ̀ nìyí tí a lè gbà ṣe ìyẹn:

Àwọn ọkùnrin méjì jọ ń kọ́lé

Máa ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. “Ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn.”—Gálátíà 6:10.

Máa ṣiṣẹ́ kára. “Kí ẹni tí ń jalè má jalè mọ́, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, kí ó máa ṣe iṣẹ́ àṣekára, kí ó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe ohun tí ó jẹ́ iṣẹ́ rere.”—Éfésù 4:28.

Jẹ́ mímọ́ nípa ti ara àti nínú ìwà híhù. “Ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí, kí a máa sọ ìjẹ́mímọ́ di pípé nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.”—2 Kọ́ríńtì 7:1.

Ìdílé kan fẹ́ jẹun

Fẹ́ràn àwọn mẹ́ńbà ìdílé rẹ, kí o sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn. “Kí olúkúlùkù yín . . . máa nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀; ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, kí aya ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀. Ẹ̀yin ọmọ, ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí yín.”—Éfésù 5:33–6:1.

Máa fi ìfẹ́ hàn sí àwọn ẹlòmíràn. “Ẹ jẹ́ kí a máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì, nítorí pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìfẹ́ ti wá.”—1 Jòhánù 4:7.

Máa ṣègbọ́ràn sí àwọn òfin orílẹ̀-èdè. “Kí olúkúlùkù ọkàn wà lábẹ́ [ìjọba] . . . Ẹ fi ẹ̀tọ́ gbogbo ènìyàn fún wọn, ẹni tí ó béèrè fún owó orí, ẹ fún un ní owó orí.”—Róòmù 13:1, 7.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́