-
Báwo Ni Àwọn Alàgbà Ṣe Ń Ran Ìjọ Lọ́wọ́?Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
-
-
Ẹ̀KỌ́ 15
Báwo Ni Àwọn Alàgbà Ṣe Ń Ran Ìjọ Lọ́wọ́?
Orílẹ̀-èdè Finland
Wọ́n ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́
Wọ́n ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn
Wọ́n ń wàásù
A kò ní àwọn àlùfáà tó ń gba owó nínú ètò wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, a yan àwọn alábòójútó tó kúnjú ìwọ̀n sípò “láti ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run” bíi ti ìgbà tí ìjọ Kristẹni bẹ̀rẹ̀. (Ìṣe 20:28) Àwọn alàgbà yìí jẹ́ ẹni tó sún mọ́ Ọlọ́run gan-an, wọ́n ń mú ipò iwájú nínú ìjọ, wọ́n sì ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn, ‘kì í ṣe tipátipá àmọ́ tinútinú níwájú Ọlọ́run; kì í ṣe nítorí èrè tí kò tọ́, àmọ́ wọ́n ń fi ìtara ṣe é látọkàn wá.’ (1 Pétérù 5:1-3) Àwọn iṣẹ́ wo ni wọ́n ń ṣe nítorí wa?
Wọ́n ń bójú tó wa, wọ́n sì ń dáàbò bò wá. Àwọn alàgbà ń tọ́ wa sọ́nà, wọ́n sì ń mú kí ìjọ túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. Àwọn alàgbà mọ̀ pé iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé àwọn lọ́wọ́ ṣe pàtàkì, torí náà wọn kì í jọ̀gá lé àwọn èèyàn Ọlọ́run lórí, kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń mú kí àlàáfíà àti ayọ̀ wa pọ̀ sí i. (2 Kọ́ríńtì 1:24) Bí olùṣọ́ àgùntàn kan ṣe ń tọ́jú àwọn àgùntàn rẹ lọ́kọ̀ọ̀kan, bẹ́ẹ̀ ni àwọn alàgbà ṣe ń sapá láti mọ gbogbo ará ìjọ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.—Òwe 27:23.
Wọ́n ń kọ́ wa bí a ṣe lè ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, àwọn alàgbà máa ń darí àwọn ìpàdé ìjọ láti mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára sí i. (Ìṣe 15:32) Àwọn ọkùnrin tó ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn yìí tún máa ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wa lóde ẹ̀rí, wọ́n sì ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́ nínú gbogbo ọ̀nà tí à ń gbà wàásù.
Wọ́n ń fún wa ní ìṣírí lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Nítorí kí wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan láti túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run, àwọn alàgbà máa ń bẹ̀ wá wò ní ilé wa tàbí ní Gbọ̀ngàn Ìjọba láti fi Ìwé Mímọ́ tù wá nínú, kí wọ́n sì ràn wá lọ́wọ́.—Jémíìsì 5:14, 15.
Yàtọ̀ sí iṣẹ́ wọn nínú ìjọ, ọ̀pọ̀ àwọn alàgbà tún ní iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ àti ojúṣe nínú ìdílé tó ń gba àkókò àti àfiyèsí wọn. Ó yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fún àwọn arákùnrin wa tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára yìí.—1 Tẹsalóníkà 5:12, 13.
Kí ni iṣẹ́ àwọn alàgbà ìjọ?
Àwọn ọ̀nà wo ni àwọn alàgbà ń gbà fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan?
-
-
Kí Ni Ojúṣe Àwọn Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́?Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
-
-
Ẹ̀KỌ́ 16
Kí Ni Ojúṣe Àwọn Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́?
Orílẹ̀-èdè Myanmar
Nínú ìpàdé ìjọ
Àwùjọ àwọn tó fẹ́ lọ wàásù
Wọ́n ń tún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe
Bíbélì sọ pé àwùjọ méjì ni àwọn ọkùnrin tó ń bójú tó àwọn iṣẹ́ nínú ìjọ Kristẹni pín sí, ìyẹn sì ni “àwọn alábòójútó àti àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.” (Fílípì 1:1) Àwọn alábòójútó àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó wà ní ìjọ kọ̀ọ̀kan máa ń tó bíi mélòó kan. Àwọn iṣẹ́ tó ń ṣe wá láǹfààní wo ni àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ń ṣe?
Wọ́n ń ran ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà lọ́wọ́. Àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ jẹ́ àwọn ọkùnrin tó ń fi ọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Ọlọ́run, wọ́n ṣeé fọkàn tán, wọ́n sì máa ń fara balẹ̀ ṣe nǹkan, àwọn kan lára wọn jẹ́ ọ̀dọ́, àwọn míì sì jẹ́ àgbà. Wọ́n ń bójú tó àwọn iṣẹ́ tó jẹ mọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba àti àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ míì tó ṣe pàtàkì àmọ́ tí kì í ṣe iṣẹ́ àbójútó ìjọ. Èyí jẹ́ kí àwọn alàgbà lè gbájú mọ́ iṣẹ́ kíkọ́ni àti ṣíṣe olùṣọ́ àgùntàn.
Wọ́n ń ṣe àwọn iṣẹ́ tó ń ṣeni láǹfààní. A máa ń yan àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan pé kí wọ́n jẹ́ olùtọ́jú èrò, kí wọ́n máa kí àwọn tó bá wá sí ìpàdé káàbọ̀. Àwọn míì máa ń bójú tó ẹ̀rọ tó ń gbé ohùn sáfẹ́fẹ́, ìwé ìròyìn tàbí àkọsílẹ̀ ìnáwó ìjọ, àwọn kan sì máa ń fún àwọn ará ìjọ ní ibi tí wọ́n á ti wàásù. Wọ́n tún máa ń ṣèrànwọ́ láti tún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe. Àwọn alàgbà lè ní kí wọ́n ran àwọn àgbàlagbà lọ́wọ́. Iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá fún àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ pé kí wọ́n ṣe, wọ́n máa ń ṣe é tinútinú, èyí sì ń mú kí gbogbo èèyàn bọ̀wọ̀ fún wọn.—1 Tímótì 3:13.
Wọ́n ń fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. Àwọn ìwà rere tó yẹ Kristẹni tí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní ló mú ká yàn wọ́n sípò. Tí wọ́n bá ṣiṣẹ́ ní ìpàdé, ó máa ń mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára. Bí wọ́n ṣe ń mú ipò iwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ń jẹ́ kí ìtara wa pọ̀ sí i. Bí wọ́n ṣe ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà ń mú kí ayọ̀ àti ìṣọ̀kan gbilẹ̀. (Éfésù 4:16) Tó bá yá, àwọn náà lè kúnjú ìwọ̀n láti di alàgbà.
Àwọn wo là ń pè ní ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́?
Kí làwọn ìránṣẹ́ máa ń ṣe láti mú kí nǹkan máa lọ déédéé nínú ìjọ?
-
-
Báwo Ni Àwọn Alábòójútó Àyíká Ṣe Ń Ràn Wá Lọ́wọ́?Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
-
-
Ẹ̀KỌ́ 17
Báwo Ni Àwọn Alábòójútó Àyíká Ṣe Ń Ràn Wá Lọ́wọ́?
Orílẹ̀-èdè Màláwì
Àwùjọ àwọn tó fẹ́ lọ wàásù
Wọ́n wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù
Ìpàdé àwọn alàgbà
Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì sọ̀rọ̀ nípa Bánábà àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Àwọn ọkùnrin yìí jẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò, wọ́n sì ń bẹ àwọn ìjọ wò nígbà yẹn. Kí nìdí? Ìdí ni pé ọ̀rọ̀ àwọn ará tí wọ́n jọ ń sin Ọlọ́run jẹ wọ́n lógún gan-an. Pọ́ọ̀lù sọ pé òun fẹ́ “pa dà lọ bẹ àwọn ará wò” kí òun lè rí bí wọ́n ṣe ń ṣe sí. Ó múra tán láti rin ìrìn àjò ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà kó lè lọ fún wọn ní ìṣírí. (Ìṣe 15:36) Ohun kan náà tí àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò wa ń ṣe lónìí nìyẹn.
Wọ́n ń bẹ̀ wá wò kí wọ́n lè fún wa níṣìírí. Alábòójútó àyíká máa ń bẹ nǹkan bí ogún (20) ìjọ wò, ó sì máa ń lo ọ̀sẹ̀ kan ní ìjọ kọ̀ọ̀kan lẹ́ẹ̀mejì lọ́dún. Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ la lè rí kọ́ látinú ìrírí àwọn arákùnrin yìí àti ti ìyàwó wọn, tí wọ́n bá ní ìyàwó. Wọ́n máa ń sapá láti mọ tèwe tàgbà, a jọ máa ń lọ wàásù, a sì jọ máa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn alábòójútó yìí àtàwọn alàgbà jọ máa ń ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn, wọ́n sì máa ń sọ àwọn àsọyé tó ń gbéni ró láwọn ìpàdé àtàwọn àpéjọ wa.—Ìṣe 15:35.
Wọ́n ń fìfẹ́ hàn sí gbogbo èèyàn. Àwọn alábòójútó àyíká máa ń wá bí ìjọ ṣe máa tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Wọ́n máa ń ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn alàgbà àti àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ láti ṣàyẹ̀wò bí ìjọ ṣe ń ṣe dáadáa sí, wọ́n sì máa ń fún wọn ní ìmọ̀ràn tó wúlò lórí bí wọ́n ṣe lè bójú tó iṣẹ́ wọn. Wọ́n máa ń ran àwọn aṣáájú-ọ̀nà lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn láṣeyọrí, wọ́n tún máa ń fẹ́ mọ àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń wá sípàdé àti bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ síwájú sí nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn arákùnrin yìí ló ń yọ̀ǹda ara wọn tinútinú, “a sì jọ ń ṣiṣẹ́ fún ire [wa].” (2 Kọ́ríńtì 8:23) Ó yẹ ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ àti ìfọkànsin wọn sí Ọlọ́run.—Hébérù 13:7.
Kí nìdí tí àwọn alábòójútó àyíká fi máa ń bẹ àwọn ìjọ wò?
Kí lo lè ṣe láti jàǹfààní látinú ìbẹ̀wò wọn?
-
-
Báwo La Ṣe Ń Ṣèrànwọ́ fún Àwọn Ará Wa Tí Àjálù Bá?Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
-
-
Ẹ̀KỌ́ 18
Báwo La Ṣe Ń Ṣèrànwọ́ fún Àwọn Ará Wa Tí Àjálù Bá?
Orílẹ̀-èdè Dominican Republic
Orílẹ̀-èdè Japan
Orílẹ̀-èdè Haiti
Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣètò ìrànwọ́ tó máa mú kí ara tu àwọn ará wa tí àjálù bá. Irú ìrànwọ́ bẹ́ẹ̀ máa ń fi hàn pé ìfẹ́ tòótọ́ ló wà láàárín wa. (Jòhánù 13:34, 35; 1 Jòhánù 3:17, 18) Àwọn ìrànlọ́wọ́ wo la máa ń ṣe?
A máa ń fowó ṣèrànwọ́. Nígbà tí ìyàn ńlá mú ní Jùdíà, àwọn tó kọ́kọ́ di Kristẹni ní ìlú Áńtíókù fi owó ránṣẹ́ láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ará wọn ní Jùdíà. (Ìṣe 11:27-30) Lọ́nà kan náà, tá a bá gbọ́ pé nǹkan nira fún àwọn ará wa láwọn apá ibì kan láyé, a máa ń fi owó ṣètìlẹyìn láwọn ìjọ wa, kí wọ́n lè fi pèsè àwọn nǹkan tí àwọn ará náà nílò lásìkò tí nǹkan nira fún wọn.—2 Kọ́ríńtì 8:13-15.
A máa ń pèsè ohun tí wọ́n nílò. Àwọn alàgbà tó bá wà níbi tí àjálù ti ṣẹlẹ̀ máa ń wá ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìjọ kàn, láti rí i pé gbogbo wọn wà lálàáfíà. Ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó ètò ìrànwọ́ máa ń ṣètò oúnjẹ, omi tó mọ́, aṣọ, ilé gbígbé, wọ́n sì ń bójú tó ìlera àwọn tọ́rọ̀ kàn. Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n mọ iṣẹ́ tí wọ́n lè fi ṣàtúnṣe ibi tí àjálù bà jẹ́, máa ń ná owó ara wọn láti lọ ṣèrànwọ́ fún àwọn tí àjálù bá tàbí kí wọ́n lọ tún àwọn ilé àti Gbọ̀ngàn Ìjọba tó bà jẹ́ ṣe. Bá a ṣe wà níṣọ̀kan nínú ètò wa àti ìrírí tá a ti ní bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ máa ń jẹ́ ká lè tètè kóra jọ láti ṣèrànwọ́ nígbà ìṣòro. Bí a ṣe ń ṣèrànwọ́ fún “àwọn tó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́,” la tún ń ṣèrànwọ́ fún àwọn míì tó bá ṣeé ṣe, láìka ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe sí.—Gálátíà 6:10.
A máa ń fi Ìwé Mímọ́ tu àwọn èèyàn nínú. Àwọn tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ sí máa ń nílò ìtùnú gan-an. Nírú àkókò bẹ́ẹ̀, a máa ń rí okun gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà, “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.” (2 Kọ́ríńtì 1:3, 4) Inú wa máa ń dùn láti sọ àwọn ìlérí Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì fún àwọn tí ìdààmú bá, à ń mú un dá wọn lójú pé láìpẹ́ Ìjọba Ọlọ́run máa fòpin sí gbogbo àjálù tó ń fa ìrora àti ìjìyà bá aráyé.—Ìfihàn 21:4.
Kí ló mú kó ṣeé ṣe fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti máa tètè ṣèrànwọ́ nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀?
Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo la lè fi sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn tó yè bọ́ nínú àjálù?
-
-
Ta Ni Ẹrú Olóòótọ́ àti Olóye?Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
-
-
Ẹ̀KỌ́ 19
Ta Ni Ẹrú Olóòótọ́ àti Olóye?
Gbogbo wa là ń jàǹfààní látinú oúnjẹ tẹ̀mí
Nígbà tí ikú Jésù ti sún mọ́lé gan-an, ó bá mẹ́rin lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀ ní ìdákọ́ńkọ́, ìyẹn Pétérù, Jémíìsì, Jòhánù àti Áńdérù. Bó ṣe ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àmì tó máa fi hàn pé òun ti wà níhìn-ín ní ọjọ́ ìkẹyìn, ó béèrè ìbéèrè pàtàkì kan pé: “Ní tòótọ́, ta ni ẹrú olóòótọ́ àti olóye tí ọ̀gá rẹ̀ yàn pé kó máa bójú tó àwọn ará ilé rẹ̀, kó máa fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tó yẹ?” (Mátíù 24:3, 45; Máàkù 13:3, 4) Jésù fi dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lójú pé òun tí òun jẹ́ “ọ̀gá” wọn, máa yan àwọn táá máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí déédéé fún àwọn ọmọlẹ́yìn òun ní àkókò òpin. Àwọn wo ló máa para pọ̀ jẹ́ ẹrú náà?
Ó jẹ́ àwùjọ kékeré lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí yàn. “Ẹrú” náà ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó máa ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí tó bọ́ sákòókò fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ olùjọsìn Jèhófà. A gbára lé ẹrú olóòótọ́ yìí láti máa fún wa ní “ìwọ̀n oúnjẹ” wa “ní àkókò tó yẹ.”—Lúùkù 12:42.
Ó ń bójú tó agbo ilé Ọlọ́run. (1 Tímótì 3:15) Jésù gbé iṣẹ́ ńlá fún ẹrú náà láti máa bójú tó iṣẹ́ tó jẹ́ ti apá orí ilẹ̀ ayé lára ètò Jèhófà, ìyẹn bíbójútó àwọn ohun ìní rẹ̀, dídarí iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ wa nípasẹ̀ ìjọ. Nítorí náà, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń pèsè ohun tá a nílò fún wa ní àkókò tó yẹ, wọ́n sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ bí wọ́n ṣe ń fún wa ní oúnjẹ tẹ̀mí nípasẹ̀ àwọn ìwé tí à ń lò nínú iṣẹ́ ìwàásù àti nípasẹ̀ àwọn ohun tí à ń kọ́ ní àwọn ìpàdé àtàwọn àpéjọ wa.
Ẹrú náà jẹ́ olóòótọ́ sí ohun tí Bíbélì fi kọ́ni àti iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere tí Bíbélì pa láṣẹ, ó sì jẹ́ olóye torí pé ó ń fi ọgbọ́n bójú tó àwọn ohun ìní Kristi láyé. (Ìṣe 10:42) Jèhófà ń bù kún iṣẹ́ ẹrú náà, ó ń jẹ́ kí àwọn èèyàn rẹ̀ pọ̀ sí i, ó sì ń mú kí wọ́n ní oúnjẹ tẹ̀mí tó pọ̀ gan-an.—Àìsáyà 60:22; 65:13.
Ta ni Jésù yàn pé kó máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀?
Kí ni ẹrú náà ń ṣe tó fi hàn pé ó jẹ́ olóòótọ́ àti olóye?
-
-
Ọ̀nà Wo Ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí Gbà Ń Ṣiṣẹ́ Lóde Òní?Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
-
-
Ẹ̀KỌ́ 20
Ọ̀nà Wo Ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí Gbà Ń Ṣiṣẹ́ Lóde Òní?
Ìgbìmọ̀ olùdarí ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní
Wọ́n ń ka lẹ́tà tí ìgbìmọ̀ olùdarí kọ
Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwùjọ kékeré kan, ìyẹn “àwọn àpọ́sítélì àti àwọn alàgbà ní Jerúsálẹ́mù,” ló jẹ́ ìgbìmọ̀ olùdarí tó ń ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì tó kan gbogbo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró. (Ìṣe 15:2) Ìwé Mímọ́ tí wọ́n máa ń jíròrò àti bí wọ́n ṣe ń jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run darí wọn, ló ń mú kí wọ́n lè máa fohùn ṣọ̀kan nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìpinnu. (Ìṣe 15:25) Àpẹẹrẹ yẹn là ń tẹ̀ lé lóde òní.
Ọlọ́run ń lo ìgbìmọ̀ náà láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Àwọn ẹni àmì òróró tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gan-an, àwọn arákùnrin yìí sì ní ìrírí tó pọ̀ nínú bá a ṣe ń bójú tó àwọn ohun tó jẹ mọ́ iṣẹ́ àti ìjọsìn wa. Wọ́n máa ń pàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí ẹgbẹ́ ará wa kárí ayé nílò. Bíi ti àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, à ń rí àwọn ìtọ́ni tá a gbé ka Bíbélì gbà nípasẹ̀ lẹ́tà tàbí nípasẹ̀ àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àti àwọn míì. Èyí ń jẹ́ kí èrò àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣọ̀kan, kí wọ́n sì máa ṣe ohun kan náà. (Ìṣe 16:4, 5) Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló ń bójú tó bá a ṣe ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí, wọ́n ń rọ àwọn ará láti fi ọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n sì ń bójú tó bá a ṣe ń yan àwọn arákùnrin sípò.
Ìgbìmọ̀ náà ń jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run darí òun. Ìgbìmọ̀ Olùdarí gbára lé Jèhófà, Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run àti Jésù tó jẹ́ Orí ìjọ, ó sì ń tẹ̀ lé bí wọ́n ṣe ń tọ́ ọ sọ́nà. (1 Kọ́ríńtì 11:3; Éfésù 5:23) Àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ yìí kì í wo ara wọn bí aṣáájú àwọn èèyàn Ọlọ́run. Àwọn àti gbogbo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró “ń tẹ̀ lé Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà [Jésù] lọ síbikíbi tó bá ń lọ.” (Ìfihàn 14:4) Àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí mọyì àdúrà tí à ń gbà nítorí wọn.
Àwọn wo ló wà nínú ìgbìmọ̀ olùdarí ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní?
Báwo ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣe ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run lóde òní?
-
-
Ibo Là Ń Pè Ní Bẹ́tẹ́lì?Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
-
-
Ẹ̀KỌ́ 21
Ibo Là Ń Pè Ní Bẹ́tẹ́lì?
Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán, Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà
Orílẹ̀-èdè Jámánì
Orílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà
Orílẹ̀-èdè Kòlóńbíà
Bẹ́tẹ́lì jẹ́ orúkọ kan lédè Hébérù tó túmọ̀ sí “Ilé Ọlọ́run.” (Jẹ́nẹ́sísì 28:17, 19, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé) Orúkọ tó bá a mu yìí là ń pe àwọn ibi tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ kárí ayé, tí à ń lò láti darí iṣẹ́ ìwàásù, tí a sì fi ń ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ náà. Orílé-iṣẹ́ wa wà ní ìpínlẹ̀ New York lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ibẹ̀ sì ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti ń bójú tó iṣẹ́ àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Ìdílé Bẹ́tẹ́lì là ń pe àwùjọ àwọn tó ń sìn ní àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Bí ìdílé kan, wọ́n ń gbé pa pọ̀, wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́, wọ́n jọ ń jẹun, wọ́n sì ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan.—Sáàmù 133:1.
Bẹ́tẹ́lì jẹ́ ibi àrà ọ̀tọ̀ tí àwọn èèyàn ti máa ń yọ̀ǹda ara wọn tinútinú. Ní gbogbo ilé Bẹ́tẹ́lì, wàá rí àwọn Kristẹni lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tọkàntọkàn, tí wọ́n sì ń lo èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò wọn láti bójú tó àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run. (Mátíù 6:33) Wọn kì í gba owó oṣù, àmọ́ wọ́n fún wọn ní yàrá, oúnjẹ àti owó ìtìlẹ́yìn tí wọ́n lè fi ra àwọn nǹkan tí wọ́n nílò. Gbogbo ẹni tó wà ní Bẹ́tẹ́lì la yan iṣẹ́ fún, yálà ní ọ́fíìsì, ní ilé ìdáná tàbí ní yàrá ìjẹun. Àwọn kan ń ṣiṣẹ́ ní ilé ìtẹ̀wé tàbí ibi tí wọ́n ti ń di ìwé pọ̀, àwọn míì ń tọ́jú ilé tàbí kí wọ́n máa fọṣọ, kí wọ́n máa tún nǹkan ṣe tàbí kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ míì.
Wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára láti ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Ìdí tí a fi kọ́ àwọn ilé Bẹ́tẹ́lì ni láti jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni. Àpẹẹrẹ kan ni ìwé yìí. A kọ ọ́ lábẹ́ àbójútó Ìgbìmọ̀ Olùdarí, a fi í ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà sí ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn atúmọ̀ èdè káàkiri ayé, a fi ẹ̀rọ tó ń yára tẹ̀ ẹ́ ní àwọn ilé Bẹ́tẹ́lì tí a ti ń tẹ̀wé, a sì kó o lọ sí àwọn ìjọ tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́fà (110,000). Gbogbo iṣẹ́ yìí ni ìdílé Bẹ́tẹ́lì fi ń ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ tó jẹ́ kánjúkánjú jù lọ, ìyẹn iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere.—Máàkù 13:10.
Àwọn wo ló ń ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì, báwo la sì ṣe ń tọ́jú wọn?
Iṣẹ́ tó jẹ́ kánjúkánjú wo ni ìdílé Bẹ́tẹ́lì kọ̀ọ̀kan ń tì lẹ́yìn?
-
-
Kí Là Ń Ṣe ní Àwọn Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa?Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
-
-
Ẹ̀KỌ́ 22
Kí Là Ń Ṣe ní Àwọn Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa?
Orílẹ̀-èdè Solomon Islands
Orílẹ̀-èdè Kánádà
Orílẹ̀-èdè South Africa
Ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àwọn tó wà ní Bẹ́tẹ́lì ti ń ṣiṣẹ́, wọ́n sì ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù ní orílẹ̀-èdè kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Wọ́n lè máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn atúmọ̀ èdè, kí wọ́n máa tẹ ìwé ìròyìn, kí wọ́n máa di ìwé pọ̀, kí wọ́n máa tọ́jú àwọn ìwé, kí wọ́n máa gba ohùn tàbí àwòrán sílẹ̀ tàbí kí wọ́n máa bójú tó àwọn nǹkan míì tó jẹ mọ́ agbègbè tó wà lábẹ́ àbójútó wọn.
Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ló ń bójú tó iṣẹ́ ẹ̀ka kọ̀ọ̀kan. Ìgbìmọ̀ Olùdarí fa àbójútó ẹ̀ka kọ̀ọ̀kan lé Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka lọ́wọ́, àwọn alàgbà mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tó kúnjú ìwọ̀n ló máa ń wà nínú ìgbìmọ̀ yìí. Wọ́n máa ń jẹ́ kí Ìgbìmọ̀ Olùdarí mọ ìtẹ̀síwájú tó ń bá iṣẹ́ wa láwọn ilẹ̀ tó wà lábẹ́ Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka náà àti ìṣòro tó bá yọjú. Èyí ń jẹ́ kí Ìgbìmọ̀ Olùdarí mọ ohun tí wọ́n máa gbé jáde àti ohun tó yẹ ká jíròrò ní àwọn ìpàdé àtàwọn àpéjọ lọ́jọ́ iwájú. Ìgbìmọ̀ Olùdarí tún máa ń rán àwọn aṣojú wọn látìgbàdégbà pé kí wọ́n lọ bẹ àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wò kí wọ́n sì tọ́ àwọn Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka sọ́nà nípa bí wọ́n ṣe máa bójú tó iṣẹ́ wọn. (Òwe 11:14) Lára àkànṣe ètò tí wọ́n máa ń ṣe nígbà ìbẹ̀wò náà ni àsọyé tí aṣojú orílé-iṣẹ́ máa ń sọ láti fún àwọn tó ń gbé láwọn ibi tí ẹ̀ka ọ́fíìsì náà ń bójú tó níṣìírí.
Wọ́n máa ń ṣèrànwọ́ fún àwọn ìjọ tó wà lágbègbè wọn. A fún àwọn arákùnrin kan ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa láṣẹ láti fọwọ́ sí i pé ká dá ìjọ tuntun sílẹ̀. Àwọn kan sì ń bójú tó iṣẹ́ àwọn aṣáájú-ọ̀nà, míṣọ́nnárì àtàwọn alábòójútó àyíká tó ń sìn láwọn ibi tí ẹ̀ka náà ń bójú tó. Wọ́n máa ń ṣètò àpéjọ àyíká àti àpéjọ agbègbè, wọ́n ń darí kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun, wọ́n sì ń rí i dájú pé à ń fi àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí àwọn ìjọ nílò ránṣẹ́ sí wọn. Gbogbo iṣẹ́ tí à ń ṣe ní ẹ̀ka ọ́fíìsì ló ń mú kí iṣẹ́ ìwàásù máa lọ létòlétò.—1 Kọ́ríńtì 14:33, 40.
Báwo ni àwọn Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ṣe ń ran Ìgbìmọ̀ Olùdarí lọ́wọ́?
Àwọn iṣẹ́ wo là ń ṣe láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa?
-
-
Báwo La Ṣe Ń Kọ Àwọn Ìwé Wa, Tí A sì Ń Túmọ̀ Wọn?Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
-
-
Ẹ̀KỌ́ 23
Báwo La Ṣe Ń Kọ Àwọn Ìwé Wa, Tí A sì Ń Túmọ̀ Wọn?
Ẹ̀ka Ìwé Kíkọ ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà
Orílẹ̀-èdè South Korea
Orílẹ̀-èdè Àméníà
Orílẹ̀-èdè Bùrúńdì
Orílẹ̀-èdè Sri Lanka
Ká lè sọ “ìhìn rere” náà fún “gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti èèyàn,” èdè tó lé ní ọgọ́rùn-ún méje àti àádọ́ta (750) la fi ń tẹ ìwé jáde. (Ìfihàn 14:6) Báwo la ṣe ń ṣe iṣẹ́ bàǹtàbanta yìí? À ń lo àwọn òǹkọ̀wé wa tí wọ́n wà káàkiri ayé àti àwọn atúmọ̀ èdè tó ń fi tọkàn tara ṣiṣẹ́, gbogbo wọn pátá sì jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Èdè Gẹ̀ẹ́sì la fi ń kọ àwọn ìwé wa ká tó tú u sí àwọn èdè míì. Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló ń bójú tó Ẹ̀ka Ìwé Kíkọ ní orílé-iṣẹ́ wa lágbàáyé. Ẹ̀ka yìí ló ń ṣètò iṣẹ́ àwọn òǹkọ̀wé tó wà ní orílé-iṣẹ́ wa àtàwọn tó wà láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa kan. Àwọn òǹkọ̀wé wa wá láti àwọn ibi tó yàtọ̀ síra, èyí ń jẹ́ ká lè sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀kọ́ tó wúlò fún àwọn tí àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ síra, ó sì ń jẹ́ kí àwọn èèyàn láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ohun tí à ń gbé jáde.
A máa ń fi ohun tá a kọ ránṣẹ́ sí àwọn atúmọ̀ èdè. Lẹ́yìn tá a bá ṣàtúnṣe sí ohun tí àwọn òǹkọ̀wé wa kọ, tá a sì fọwọ́ sí i, a máa ń fi ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà sí àwọn atúmọ̀ èdè káàkiri ayé, kí wọ́n lè túmọ̀ rẹ̀, kí wọ́n yẹ̀ ẹ́ wò dáadáa, kí wọ́n sì rí i pé ó dùn-ún kà lédè wọn. Wọ́n máa ń rí i dájú pé àwọn lo “àwọn ọ̀rọ̀ tó péye tó sì jẹ́ òtítọ́” kí wọ́n lè gbé ìtumọ̀ ohun tí a sọ lédè Gẹ̀ẹ́sì yọ dáadáa ní èdè ìbílẹ̀ wọn.—Oníwàásù 12:10.
Kọ̀ǹpútà ń mú kí iṣẹ́ wọn yára kánkán. A ò lè fi kọ̀ǹpútà rọ́pò àwọn òǹkọ̀wé àtàwọn atúmọ̀ èdè. Àmọ́, iṣẹ́ wọn máa ń yá tí wọ́n bá lo àwọn ìwé atúmọ̀ èdè tó wà lórí kọ̀ǹpútà, àwọn ètò orí kọ̀ǹpútà tó wà fún èdè wọn àtàwọn ohun tí wọ́n lè fi ṣe ìwádìí. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ètò orí kọ̀ǹpútà kan tá a pè ní Multilanguage Electronic Publishing System (ìyẹn MEPS) tó máa jẹ́ ká lè tẹ ọ̀rọ̀ ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè, ká fi àwòrán sí i, ká sì ṣètò rẹ̀ bó ṣe máa wà lórí ìwé.
Kí nìdí tá a fi ń ṣe gbogbo iṣẹ́ yìí, kódà láwọn èdè tó jẹ́ pé àwọn tó ń sọ ọ́ kò ju ẹgbẹ̀rún mélòó kan lọ? Ìdí ni pé ó jẹ́ ìfẹ́ Jèhófà pé “ká gba onírúurú èèyàn là, kí wọ́n sì ní ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́.”—1 Tímótì 2:3, 4.
Báwo la ṣe ń kọ àwọn ìwé wa?
Kí nìdí tá a fi ń túmọ̀ àwọn ìwé wa sí ọ̀pọ̀ èdè?
-
-
Báwo La Ṣe Ń Rí Owó fún Iṣẹ́ Wa Kárí Ayé?Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
-
-
Ẹ̀KỌ́ 24
Báwo La Ṣe Ń Rí Owó fún Iṣẹ́ Wa Kárí Ayé?
Orílẹ̀-èdè Nepal
Orílẹ̀-èdè Tógò
Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì
Ètò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù Bíbélì àtàwọn ìwé míì lọ́dọọdún, a sì ń pín wọn fún àwọn èèyàn láì díye lé e. À ń kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àtàwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì, a sì ń tún wọn ṣe. À ń ṣètìlẹ́yìn fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì àtàwọn míṣọ́nnárì, a sì ń ṣèrànwọ́ nígbà àjálù. Nítorí náà, o lè máa wò ó pé, ‘Ibo la ti ń rówó ṣe gbogbo àwọn nǹkan yìí?’
A kì í san ìdámẹ́wàá, a kì í bu owó fúnni, a kì í sì í gbégbá ọrẹ. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé owó kékeré kọ́ là ń ná sórí iṣẹ́ ìwàásù wa, a kì í tọrọ owó. Ní ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ sọ nínú ẹ̀dà kejì tó jáde pé, a gbà pé Jèhófà ni alátìlẹyìn wa àti pé a “kò ní tọrọ ohunkóhun bẹ́ẹ̀ ni [a] kò ní bẹ̀bẹ̀ láé pé káwọn èèyàn wá ṣètìlẹ́yìn,” a ò sì tíì ṣe bẹ́ẹ̀!—Mátíù 10:8.
Ọrẹ àtinúwá la fi ń ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ wa. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọyì iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí à ń ṣe, wọ́n sì máa ń fi ọrẹ ṣètìlẹ́yìn. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń dùn láti fi àkókò wọn, agbára wọn, owó wọn àtàwọn nǹkan míì ṣètìlẹ́yìn fún ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run kárí ayé. (1 Kíróníkà 29:9) Àwọn àpótí téèyàn lè fi ọrẹ sí wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àti àwọn àpéjọ wa, àwọn tó bá fẹ́ fi ọrẹ síbẹ̀ lè ṣe bẹ́ẹ̀. Bákan náà, èèyàn lè ṣètọrẹ lórí ìkànnì wa, jw.org/yo. Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó ń fi owó ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ wa ni kò fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́, bíi ti opó aláìní tí Jésù sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, tó fi ẹyọ owó kékeré méjì sínú àpótí ìṣúra ní tẹ́ńpìlì. (Lúùkù 21:1-4) Nítorí náà, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè máa “ya ohun kan sọ́tọ̀” déédéé láti fi ṣètọrẹ “gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn rẹ̀.”—1 Kọ́ríńtì 16:2; 2 Kọ́ríńtì 9:7.
Ó dá wa lójú pé Jèhófà á máa mú kí àwọn tí wọ́n fẹ́ ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ‘fi àwọn ohun ìní wọn tó níye lórí bọlá fún òun’ kí ìfẹ́ rẹ̀ lè ṣẹ.—Òwe 3:9.
Kí ló mú kí ètò wa yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀sìn míì?
Báwo la ṣe ń lo ọrẹ àtinúwá tí àwọn èèyàn fi ń ṣètìlẹ́yìn?
-
-
Kí Nìdí Tá A Fi Ń Kọ́ Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, Báwo La sì Ṣe Ń Kọ́ Wọn?Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
-
-
Ẹ̀KỌ́ 25
Kí Nìdí Tá A Fi Ń Kọ́ Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, Báwo La sì Ṣe Ń Kọ́ Wọn?
Orílẹ̀-èdè Bolivia
Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, bó ṣe rí tẹ́lẹ̀ àti bó ṣe rí báyìí
Orílẹ̀-èdè Tahiti
Bí orúkọ Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe fi hàn, ohun tí à ń jíròrò níbẹ̀ ni ẹ̀kọ́ pàtàkì látinú Bíbélì nípa Ìjọba Ọlọ́run, èyí sì ni ẹ̀kọ́ Jésù dá lé.—Lúùkù 8:1.
Wọ́n jẹ́ ibi tá a ti ń jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ ní àdúgbò wa. A máa ń ṣètò iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run láwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa. (Mátíù 24:14) Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba máa ń tóbi ju ara wọn lọ, wọ́n yàtọ̀ síra, wọ́n sì máa ń mọ níwọ̀n. Ìjọ tó ń lo ọ̀pọ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba máa ń ju ẹyọ kan lọ. Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, a ti kọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún Gbọ̀ngàn Ìjọba (tá a bá pín in lọ́gbọọgba, márùn-ún là ń kọ́ lójúmọ́) ká lè rí àyè fún àwọn ìjọ wa tó ń pọ̀ sí i. Kí ló mú kí èyí ṣeé ṣe?—Mátíù 19:26.
Ọrẹ tí gbogbo wa ń mú wá la fi ń kọ́ wọn. A máa ń fi ọrẹ yìí ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa kí wọ́n lè fi owó ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ tó fẹ́ kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí tí wọ́n fẹ́ tún un ṣe.
Onírúurú èèyàn tó yọ̀ǹda ara wọn láìgbowó ló máa ń kọ́ ọ. Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, a ti ṣètò Ẹgbẹ́ Àwọn Tí Ń Kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àwùjọ àwọn tó ń kọ́lé àtàwọn tó yọ̀ǹda ara wọn máa ń lọ láti ìjọ kan sí òmíì, kódà wọ́n ń lọ sí àwọn ibi tó jìnnà ní orílẹ̀-èdè kan náà, kí wọ́n lè ran àwọn ìjọ lọ́wọ́ láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn. Ní àwọn ilẹ̀ míì, àwọn arákùnrin tí wọ́n kọ́ṣẹ́ mọṣẹ́ máa ń bójú tó kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba àti ṣíṣe àtúnṣe sí àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà lágbègbè kan. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ máa ń yọ̀ǹda ara wọn láwọn ibi tá a ti ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, àwọn ará ìjọ tó máa lo gbọ̀ngàn náà ló máa ń pọ̀ jù lára àwọn tó ń ṣiṣẹ́ náà. Ẹ̀mí Jèhófà àti iṣẹ́ àṣekára táwọn èèyàn rẹ̀ ṣe tinútinú ló ń mú kí gbogbo èyí ṣeé ṣe.—Sáàmù 127:1; Kólósè 3:23.
Kí nìdí tá a fi ń pe ilé ìjọsìn wa ní Gbọ̀ngàn Ìjọba?
Kí ló mú kó ṣeé ṣe fún wa láti kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba káàkiri ayé?
-
-
Kí La Lè Ṣe Láti Máa Tọ́jú Gbọ̀ngàn Ìjọba Wa?Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
-
-
Ẹ̀KỌ́ 26
Kí La Lè Ṣe Láti Máa Tọ́jú Gbọ̀ngàn Ìjọba Wa?
Orílẹ̀-èdè Estonia
Orílẹ̀-èdè Sìǹbábúwè
Orílẹ̀-èdè Mòǹgólíà
Orílẹ̀-èdè Puerto Rico
Orúkọ mímọ́ Ọlọ́run la fi ń pe gbogbo Gbọ̀ngàn Ìjọba àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nítorí náà, a gbà pé àǹfààní ló jẹ́ láti máa mú kí ilé yìí wà ní mímọ́ tónítóní, kó dùn-ún wò, ká sì máa tún un ṣe. Èyí jẹ́ apá pàtàkì lára ìjọsìn mímọ́ wa. Gbogbo wa la lè kópa nínú iṣẹ́ yìí.
Yọ̀ǹda ara rẹ láti ṣe ìmọ́tótó lẹ́yìn ìpàdé. Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin máa ń fayọ̀ ṣe iṣẹ́ ìmọ́tótó pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ lẹ́yìn ìpàdé, kí Gbọ̀ngàn Ìjọba lè wà ní mímọ́ tónítóní. Wọ́n sì tún máa ń ṣe ìmọ́tótó tó pọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan ló máa ń ṣe kòkáárí iṣẹ́ náà, ó sábà máa ń wo àkọsílẹ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe. Ẹnì kọ̀ọ̀kan máa ń yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti ṣe àwọn iṣẹ́ tó bá wà, irú bíi gbígbálẹ̀, fífi omi tàbí ẹ̀rọ fọ ilẹ̀ tàbí nínu eruku, títo àga, fífọ ilé ìgbọ̀nsẹ̀ àti bíbu oògùn apakòkòrò sí i, fífọ fèrèsé àti dígí, kíkó pàǹtírí dà nù tàbí ṣíṣe ìmọ́tótó ara ilé àti ríro àyíká. Ó kéré tán, lẹ́ẹ̀kan lọ́dún, a máa ń ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ fún ṣíṣe gbogbo iṣẹ́ ìmọ́tótó Gbọ̀ngàn Ìjọba tinú tòde. A máa ń jẹ́ kí àwọn ọmọ wa lọ́wọ́ sí iṣẹ́ náà, kí wọ́n lè máa kẹ́kọ̀ọ́ láti bọ̀wọ̀ fún ibi ìjọsìn wa.—Oníwàásù 5:1.
Yọ̀ǹda ara rẹ láti ṣe àtúnṣe tó bá yẹ. Lọ́dọọdún, a máa ń yẹ tinú tòde Gbọ̀ngàn Ìjọba wò fínnífínní. Àyẹ̀wò yìí máa ń mú ká tún àwọn nǹkan ṣe látìgbàdégbà kí gbọ̀ngàn náà lè wà bó ṣe yẹ, èyí sì ń jẹ́ ká lè máa ṣọ́ owó ná. (2 Kíróníkà 24:13; 34:10) Gbọ̀ngàn Ìjọba tó mọ́ tónítóní tá a sì tún ṣe dáadáa ni ibi tó yẹ ká ti máa jọ́sìn Ọlọ́run wa. Tá a bá ń kópa nínú iṣẹ́ yìí, à ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a sì mọyì ibi ìjọsìn wa. (Sáàmù 122:1) Èyí tún máa ń jẹ́ káwọn èèyàn fojú tó dára wò wá ládùúgbò.—2 Kọ́ríńtì 6:3.
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa tọ́jú ibi ìjọsìn wa?
Àwọn ètò wo la ṣe láti mú kí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà ní mímọ́ tónítóní?
-
-
Báwo Ni Ibi Ìkówèésí Gbọ̀ngàn Ìjọba Ṣe Ń Ṣe Wá Láǹfààní?Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
-
-
Ẹ̀KỌ́ 27
Báwo Ni Ibi Ìkówèésí Gbọ̀ngàn Ìjọba Ṣe Ń Ṣe Wá Láǹfààní?
Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì
Orílẹ̀-èdè Czech
Orílẹ̀-èdè Benin
Àwọn Erékùṣù Cayman
Ṣé wàá fẹ́ ṣe àwọn ìwádìí kan kí ìmọ̀ rẹ nínú Bíbélì lè pọ̀ sí i? Ṣé ó wù ẹ́ pé kó o mọ̀ sí i nípa ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tàbí ẹnì kan, ibì kan tàbí ohun kan tí Bíbélì mẹ́nu bà? Àbí ò ń wò ó bóyá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí ohun kan tó ò ń ṣàníyàn nípa rẹ̀? Lọ ṣèwádìí níbi ìkówèésí tó wà nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba.
Àwọn ohun téèyàn lè fi ṣèwádìí wà níbẹ̀. O ṣeé ṣe kó o má ní gbogbo ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó dá lórí Bíbélì ní èdè rẹ. Àmọ́, ọ̀pọ̀ àwọn ìwé tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ tẹ̀ jáde máa wà níbi ìkówèésí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àwọn ìwé tó tún lè wà níbẹ̀ ni oríṣiríṣi Bíbélì, ìwé atúmọ̀ èdè àtàwọn ìwé míì tá a lè fi ṣèwádìí. O lè lo àwọn ìwé tó wà níbi ìkówèésí yìí kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀ tàbí lẹ́yìn ìpàdé. Tí kọ̀ǹpútà bá wà níbẹ̀, ó lè ní ètò Watchtower Library (ìyẹn àkójọ ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà). Ètò ìṣiṣẹ́ kọ̀ǹpútà yìí ní àkójọ àwọn ìwé wa, ó sì rọrùn láti fi ṣe ìwádìí nípa ẹ̀kọ́ kan, ọ̀rọ̀ kan tàbí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan.
Ó wúlò fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni. O lè lo ibi ìkówèésí Gbọ̀ngàn Ìjọba tó o bá ń múra iṣẹ́ rẹ sílẹ̀. Alábòójútó Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ló ń bójú tó ibi ìkówèésí náà. Ó máa ń rí i pé àwọn ìwé tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde wà níbẹ̀ àti pé gbogbo ìwé ibẹ̀ wà létòlétò. Òun tàbí ẹni tó ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lè fi bó o ṣe máa rí ohun tó o nílò hàn ẹ́. Àmọ́, má ṣe mú ìwé èyíkéyìí kúrò níbi ìkówèésí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bákan náà, ó yẹ ká máa tọ́jú àwọn ìwé náà dáádáá ká má sì kọ nǹkan kan sínú wọn.
Bíbélì ṣàlàyé pé tá a bá fẹ́ “rí ìmọ̀ Ọlọ́run,” a gbọ́dọ̀ máa “wá a kiri bí àwọn ìṣúra tó fara sin.” (Òwe 2:1-5) O lè lo ibi ìkówèésí Gbọ̀ngàn Ìjọba láti bẹ̀rẹ̀ sí í wá a.
Kí làwọn ohun tá a lè fi ṣe ìwádìí níbi ìkówèésí Gbọ̀ngàn Ìjọba?
Ta ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ bó o ṣe lè lo ibi ìkówèésí Gbọ̀ngàn Ìjọba dáadáa?
-
-
Kí Ló Wà Lórí Ìkànnì Wa?Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
-
-
Ẹ̀KỌ́ 28
Kí Ló Wà Lórí Ìkànnì Wa?
Orílẹ̀-èdè Faransé
Orílẹ̀-èdè Poland
Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà
Jésù Kristi sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn èèyàn, kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ rere yín, kí wọ́n sì fògo fún Baba yín tó wà ní ọ̀run.” (Mátíù 5:16) Ìdí nìyẹn tá a fi ń lo ìmọ̀ ẹ̀rọ òde òní, títí kan Íńtánẹ́ẹ̀tì fún iṣẹ́ wa. Ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, jw.org, ni ibi tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kó ìsọfúnni sí nípa ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́ wa. Kí làwọn ohun tó wà níbẹ̀?
Ìdáhùn Bíbélì sí àwọn ìbéèrè táwọn èèyàn sábà máa ń béèrè. O lè rí ìdáhùn sí díẹ̀ lára àwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì gan-an táwọn èèyàn ti béèrè. Bí àpẹẹrẹ, ìwé àṣàrò kúkúrú tá a pè ní Ǹjẹ́ Ìyà Lè Dópin? àti Ǹjẹ́ Àwọn Òkú Lè Jíǹde? wà lórí ìkànnì wa ní èdè tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600). Wàá tún rí Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun níbẹ̀ ní èdè tó lé ní àádóje (130). Àwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà wà níbẹ̀, títí kan ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? àtàwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde. O lè ka ọ̀pọ̀ lára àwọn ìwé yìí tàbí kó o tẹ́tí sí wọn lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, o sì lè wà wọ́n jáde lóríṣiríṣi ọ̀nà táwọn èèyàn ń lò, irú bíi MP3, PDF tàbí EPUB. O tiẹ̀ lè tẹ ojú ìwé mélòó kan jáde fún ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ sí ìwé náà lédè rẹ̀! Àwọn fídíò tún wà ní oríṣiríṣi èdè àwọn adití. Àwọn ohun tó o tún lè wà jáde ni Bíbélì kíkà bí ẹni ṣe eré ìtàn, àwòkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn orin aládùn tó o lè gbádùn nígbà tó bá rọ̀ ẹ́ lọ́rùn.
Ohun tó jóòótọ́ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ohun míì tá a tún ń gbé sórí ìkànnì wa ni àwọn ìròyìn ohun tó ń lọ àti fídíò nípa iṣẹ́ wa kárí ayé, àwọn ohun tó ṣẹ̀lẹ̀ sí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ìrànwọ́ tá a ṣe fún àwọn tí àjálù bá. O lè mọ̀ nípa àwọn àpéjọ tó ń bọ̀ àti ibi táwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa wà.
Lọ́nà yìí, à ń tan ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ dé apá ibi tó jìnnà jù lọ láyé. Àwọn èèyàn láti ibi gbogbo, títí kan ilẹ̀ Antarctica, ló ń jàǹfààní rẹ̀. Àdúrà wa ni pé “kí ọ̀rọ̀ Jèhófà lè máa gbilẹ̀ kíákíá” títí dé gbogbo ayé fún ògo Ọlọ́run.—2 Tẹsalóníkà 3:1.
Báwo ni ìkànnì wa, jw.org ṣe ń ran àwọn èèyàn púpọ̀ sí i lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ látinú Bíbélì?
Kí lo máa fẹ́ ṣèwádìí nípa rẹ̀ lórí ìkànnì wa?
-