ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • bhs ojú ìwé 3-7
  • Kí Ni Ọlọ́run Ní Lọ́kàn fún Wa?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Ọlọ́run Ní Lọ́kàn fún Wa?
  • Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • Ká à ní Bíbélì Fi Kọ́ni
  • Ìsọ̀rí
  • BÍBÉLÌ KỌ́ WA PÉ ỌLỌ́RUN MÁA ṢE ÀWỌN OHUN ÌYANU LÁYÉ.
  • ÀǸFÀÀNÍ TÍ WÀÁ RÍ TÓ O BÁ KẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ
Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
bhs ojú ìwé 3-7

Kí Ni Ọlọ́run Ní Lọ́kàn fún Wa?

TÓ O bá ka ìwé ìròyìn, tó o wo tẹlifíṣọ̀n tàbí tó o gbọ́ rédíò, wàá rí ìwà ọ̀daràn àti ogun tó ń ṣẹlẹ̀, wàá sì tún rí ọṣẹ́ táwọn afẹ̀míṣòfò ń ṣe. Ó ṣeé ṣe kí àìsàn ti fi ojú rẹ rí màbo tàbí kí ikú ẹnì kan tó o fẹ́ràn máa kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ.

Ìdílé kan ń gbọ́ ìròyìn lórí rédíò

Bi ara rẹ pé:

  • Ṣé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kó ṣẹlẹ̀ sí èmi àti ìdílé mi rèé?

  • Ibo ni mo ti lè rí ìrànlọ́wọ́ láti fara da àwọn ìṣòro mi?

  • Ṣé àlàáfíà tòótọ́ ṣì máa wà láyé?

Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè yẹn lọ́nà tó tẹ́ni lọ́rùn.

BÍBÉLÌ KỌ́ WA PÉ ỌLỌ́RUN MÁA ṢE ÀWỌN OHUN ÌYANU LÁYÉ.

  • Àwọn èèyàn ò ní jẹ̀rora mọ́, wọn ò ní máa darúgbó mọ́, wọn ò sì ní máa kú mọ́.​—Ìfihàn 21:4

  • “Ẹni tó yarọ máa fò sókè bí àgbọ̀nrín.”​—Àìsáyà 35:6

  • “Ojú àwọn afọ́jú máa là.”​—Àìsáyà 35:5

  • Àwọn òkú máa jíǹde.​—Jòhánù 5:28, 29

  • Ẹnì kankan ò ní ṣàìsàn mọ́.​—Àìsáyà 33:24

  • Ọ̀pọ̀ oúnjẹ máa wà fún gbogbo èèyàn.​—Sáàmù 72:16

    Arúgbó di ọ̀dọ́, arọ fò sókè, àwọn òkú jíǹde, àwọn aláìsàn rí ìwòsàn, ojú afọ́jú sì là

ÀǸFÀÀNÍ TÍ WÀÁ RÍ TÓ O BÁ KẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ

Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ ọkùnrin kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé àlá tí ò lè ṣẹ làwọn àyípadà tó o kẹ́kọ̀ọ́ pé ó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ láyé yìí. Àmọ́, Ọlọ́run ti ṣèlérí pé òun máa ṣe àwọn àyípadà yẹn láìpẹ́, Bíbélì sì ṣàlàyé bó ṣe máa ṣe é.

Bíbélì tún sọ jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó sọ ohun tó yẹ ká mọ̀ ká lè ní ayọ̀ tòótọ́, ká sì lè gbádùn ayé wa ní báyìí. Tiẹ̀ ronú nípa àwọn nǹkan tó máa ń mú kó o ní ìdààmú ọkàn. Ó lè jẹ́ ọ̀rọ̀ owó, ìṣòro ìdílé, àìlera tàbí ikú ẹni tó o fẹ́ràn. Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fara da àwọn ìṣòro yìí, á sì tù ẹ́ nínú tó o bá mọ bí Bíbélì ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè bíi:

  • Kí ló dé tá a fi ń jìyà?

  • Báwo la ṣe lè fara da àwọn ìṣòro wa?

  • Ṣé ìdílé wa lè láyọ̀?

  • Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó ti kú?

  • Ṣé a tún lè rí àwọn èèyàn wa tó ti kú?

  • Kí ló mú kó dá wa lójú pé Ọlọ́run máa ṣe gbogbo ohun tó ṣèlérí?

Bó o ṣe ń ka ìwé yìí fi hàn pé ó wù ẹ́ láti mọ ohun tí Bíbélì kọ́ wa. Ìwé yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ gan-an. Àwọn ìbéèrè tó wà fún àwọn ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ lóye Bíbélì dáadáa. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì gbádùn ẹ̀. A retí pé ìwọ náà máa gbádùn ẹ̀. Àdúrà wa ni pé kí Ọlọ́run bù kún ẹ bó o ṣe ń sapá láti mọ ohun tí Bíbélì kọ́ wa!

MỌ BÍBÉLÌ RẸ

ÌWÉ mẹ́rìndínláàádọ́rin (66) ló wà nínú Bíbélì. A pín ìwé kọ̀ọ̀kan sí orí àti ẹsẹ. Èyí mú kó rọrùn láti rí ẹsẹ kọ̀ọ̀kan. Tá a bá tọ́ka sí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan nínú ìwé yìí, nọ́ńbà àkọ́kọ́ tọ́ka sí orí ìwé Bíbélì, nọ́ńbà tó tẹ̀ lé e sì ń tọ́ka sí ẹsẹ. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá rí “2 Tímótì 3:16,” ó túmọ̀ sí Tímótì kejì orí kẹta ẹsẹ kẹrìndínlógún.

Tó o bá ń wá àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a tọ́ka sí, wàá tètè mọ Bíbélì dáadáa. Ohun míì tí wàá ṣe ni pé kó o bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì lójoojúmọ́. Tó o bá ń ka orí mẹ́ta sí márùn-ún lójúmọ́, o lè parí odindi Bíbélì lọ́dún kan.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́