Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 8
Jèhófà bù kún Sólómọ́nì gan-an, ó fún un lọ́gbọ́n, ó sì jẹ́ kó kọ́ tẹ́ńpìlì fóun. Àmọ́ nígbà tó yá, Sólómọ́nì fi Jèhófà sílẹ̀. Tó o bá jẹ́ òbí, jẹ́ kọ́mọ ẹ mọ bí ìbọ̀rìṣà ṣe mú kí Sólómọ́nì fi Jèhófà sílẹ̀. Ìjọba Ísírẹ́lì pín sí méjì, àwọn ọba búburú tó jẹ sì mú káwọn èèyàn náà máa jọ́sìn òrìṣà. Lákòókò yẹn, ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì Jèhófà ni wọ́n fìyà jẹ tí wọ́n sì pa. Jésíbẹ́lì tó jẹ́ ayaba tún mú káwọn èèyàn túbọ̀ máa jọ́sìn àwọn òrìṣà. Nǹkan burú gan-an fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì lákòókò yìí. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Lára wọn ni Ọba Jèhóṣáfátì àti wòlíì Èlíjà.